settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni títóbí jùlọ Ọlọ́run àti àǹfàní ènìyàn láti dá yàn ṣe ṣiṣẹ́ nínú ìgbàlà?

Idahun


Kò ṣée ṣe fún wa láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbáṣepọ̀ tí ò wà láàrín títóbí jùlọ Ọlọ́run àti àǹfàní ènìyàn láti dá yàn àti gbígba ojúṣe. Ọlọ́run nìkan ni o mọ ní òtítọ́ bí wọn ṣe ńṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ètò ìgbàlà Rẹ̀. Bóyá síwájú si ju èyíkéyi ẹ̀kọ́ míìràn lọ, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣe pàtàkì láti gba àìlágbara wa láti ní òye ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àbùdá Ọlọ́run àti ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀. Lílọ síwájú jù ní ọ̀nà méjèjì yó ò yọrí sí dída òye ìgbàlà rú.

Ìwé Mímọ́ hàn kedere wípé Ọlọ́run mọ ẹni tí yóò ní ìgbàlà (Romu 8:29; 1 Peteru 1:2). Ìwé Efesu 1:4 sọ fún wa wípé Ọlọ́run ti yàn wá "ṣaju ìpilẹ̀sẹ̀ aiye." Bíbélì ṣe àpèjúwe àwọn onígbàgbọ́ léraléra bíi "tí a yàn" (Romu 8:33; 11:5; Efesu 1:11; Kolosse 3:12; 1 Tessalonika 1:4; 1 Peteru1:2; 2:9) àti "àyànfẹ́" (Matteu 24:22, 31; Marku 13:20, 27; Romu 11:7; 1 Timoteu 5:21; 2 Timoteu 2:10; Titu 1:1; 1 Peteru 1:1). Òtítọ́ wípé a ti yan àwọn onígbàgbọ́ tẹ́lẹ̀ fún ìgbàla hàn gbangba kedere (Romu 8:29-30; Efesu 1:5, 11), àti wípé wọn jẹ́ àyànfẹ́ (Romu 9:11; 11:28; 2 Peteru 1:10).

Bíbélì tún sọ wípé àwa ní ojúṣe láti gba Jésù bíi Olùgbàlà – ohun gbogbo tí a ní láti ṣe ni láti gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi a ó si gbà wá là (Johannu 3:16, Romu 10:9-10). Ọlọ́run mọ àwọn ti yóò di ẹni ìgbàlà, Ọlọ́run ńyan àwọn ti yóò di ẹni ìgbàlà, àwa si gbọ́dọ̀ yan Kristi láti lè ni ìgbàlà. Bí àwọn òtítọ́ mẹta wọ̀nyìí ṣe ńṣiṣẹ́ papọ̀ kọjá òye ọkàn tí ó ni gbèdéké (Romu 11:33-36). Ojúṣe wa ni láti mú ìhìnrere lọ sí gbogbo ayé. (Matteu 28: 18-20; Iṣe àwọn Apọsteli 1:8). Kí àwa kí ó fi ìpin mímọ̀ tẹ́lẹ̀, ìdìbò yàn, àti tí asọtẹ́lẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ̀run kí a gbọ́ràn nípa ṣíṣe àjọpín Ìhìnrere.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni títóbí jùlọ Ọlọ́run àti àǹfàní ènìyàn láti dá yàn ṣe ṣiṣẹ́ nínú ìgbàlà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries