settings icon
share icon
Ibeere

Kínni yíyàntẹ́lẹ̀? Ṣé yíyàntẹ́lẹ̀ bá Bíbélì mu?

Idahun


Ìwé Romu 8:29-30 sọ fún wa pé,"Nítorí àwọn ẹnití ó ti mọ̀ tẹ́lẹ́, ni ó sì ti yàn tẹ́lẹ̀, láti rí bí àwòrán Ọmọ rẹ̀, kí ò un lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀. Àwọn tí ó sì ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ló sì ti pè:àwọn ẹnití ó sì ti pè, àwọn ló sì ti dáláre: àwọn ẹnití ó sì ti dáláre, àwọn ni ó sì ti ṣe lógo." Ìwé Efesu 1:5 àti 11 sọ pé, "Ẹnití ó ti yàn wá tẹ́lẹ́ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Kristi fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀…..Nínú ẹnití a fi wá ṣe ìní rẹ̀ pẹ̀lú , àwa tí a ti yàn tẹ́lẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹnití ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú ìmọ̀ rẹ̀." Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìkórirá tí ó ga sí ẹ̀kọ́ yíyàntẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, yíyàntẹ́lẹ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ tí ó bá Bíbélì mu. Ohun tí ó ṣe kókó ni kí á mọ ìtumọ̀ yíyàntẹ́lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú bíbélì.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí "yíyàntẹ́lẹ̀" nínu àwọn ẹsẹ ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí lókè wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríkì proorizo, tí o túmọ̀ sí "tí a ti yàn tẹ́lẹ̀", "yàn", "láti pinnu nípa nǹkan kí àkókò tó dé." Nítorí náà, yíyàntẹ́lẹ̀ ni ìpinnu Ọlọ́run láti mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ ṣíwájú àkókò. Kínni Ọlọ́run pinnu ṣíwájú àkókò? Gẹ́gẹ́ bíi Ìwé Romu 8:29-30, Ọlọ́run yan àwọn ènìyàn kan tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán Ọmọ rẹ̀, láti pè, dáláre àtí ṣe lógo. Ní pàtàkì, Ọlọ́run yàn tẹ́lẹ̀ wípé a ó gba àwọn ènìyàn kan là. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí wípé a yan àwọn onígbàgbọ́ nínú Kristi (Matteu 24:22, 31; Marku 13:20, 27; Romu 8:33, 9:11, 11:5-7, 28; Efesu 1:11; Kolosse 3:12; 1 Tẹssalonika 1:4; 1 Timoteu 5:21; 2 Timoteu 2:10; Titu 1:1; 1 Peteru 1:1-2, 2:9; 2 Peteru 1:10). Yíyàntẹ́lẹ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì wípé Ọlọ́run nínú títóbi jùlọ Rẹ̀ yàn láti gba àwọn ènìyàn kan là.

Àtakò tí ó gbajúgbajà jù sí ẹ̀kọ́ yíyàntẹ́lẹ̀ ní wípe ó ní ojúṣááju nínú. Kílódé ti Ọlọ́run yóò ṣe yan àwọn kan tí kò sì yan àwọn ẹlòmíràn. Ohun tí ó ṣe kókó láti rántí ni wípé kò sí ẹni tí ó yẹ fún ìgbàlà. Gbogbo wa la ṣá ti ṣẹ̀ (Romu 3:23), tí a sì yẹ fún ìjìyà ayérayé (Romu 6:23). Fún ìdí èyí, Ọlọ́run yóò pé nínú òdodo bí ó bá jẹ́ kí gbogbo wa lo ayérayé wa nínú ọ̀run-àpáàdí. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run yàn láti gba àwa ènìyàn kan là. Kò ṣe ojúṣáájú sí àwọn tí a kò yàn, nítorí ohun tó tọ́ sí wọn ni wọ́n gba. Ìpinnu Ọlọ́run láti ṣe àwọn kan lóore kò túmọ̀ sí ojúṣáájú sí àwọn ẹlòmíràn. Kò sí ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; nítorínà, kò sí ẹni tí ó le ṣe àtakò tí kò bá rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni ọkùnrin kan tí ó ńpín owó fún ènìyàn máàrún láàrin èrò ogún láìṣojúṣáájú. Ṣé inú yóo bí àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún tí kò rí owó gbà ni? Bóyà bẹ́ẹ̀ni. Ṣé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti bínú? Rára, wọn kò ní. Kílódé? Nítorí ọkùnrin náà kò jẹ ẹnikẹ́ni lówó. Ó kàn pinnu láti ṣe ore fún àwọn kan ni.

Bí Ọlọ́run bá yan ẹni tí yóò gbàlà, ṣé èyí kò tẹ́mbẹ́lú àǹfàní láti yàn àti láti gbàgbọ́ nínú Kristi? Bíbélì sọ wípé a ní agbára láti yàn—gbogbo ẹni tí ó bá gba Jésù Kristi gbọ́ yóo yè (Johannu 3:16; Romu 10:9-10. Bíbélì kò ṣàlàyé wípé Ọlọ́run kọ ẹnikẹ́ni tí ó gbàgbọ́ nínú Òun tàbí wípé ó ta ẹnikẹ́ni tí ó wá Òun dànù (Deutarọnọmi 4:29). Ní bákannáà, nínú àdìtú Ọlọ́run, yíyàntẹ́lẹ̀ ṣiṣẹ́ wọnú ara wọn pẹ̀lú ẹni tí Ọlọ́run fà (Johannu 6:44) àti tí ó gbàgbọ́ nínú ìgbàlà (Romu 1:16). Ọlọ́run ńyan àwọn ti yóò di ẹni ìgbàlà, àwa si gbọ́dọ̀ yan Kristi láti lè ni ìgbàlà. Ọ̀rọ̀ méjèjì yí jẹ́ òtítọ́. Ìwé Romu 11:33 polongo wípé, "Ah! ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run! Àwámáridìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì ju àwárí lọ!"

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni yíyàntẹ́lẹ̀? Ṣé yíyàntẹ́lẹ̀ bá Bíbélì mu?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries