settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni mo ṣe lè yípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni?

Idahun


Ọkùnrin kan ní ìlú Gíríkì tí Fílíppì bèèrè ìbéèrè kannáà lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà. A mọ nǹkan mẹ́ẹ̀ta, ó kééré jù, nípa ọkùnrin yìí: ẹlẹ́wọ̀n ni, kèfèrí ni, ó sì wà láìnírètí. Ó wà ní bèbè ìpokùnso nígbàtí Pọ́ọ̀lù dáa lẹ́ẹ̀kun. Nígbànáà wá ni ọkùnrin náà bèèrè, "Kínni kí èmi kí ó ṣe kí ń le là?" (Iṣe àwọn Apọsteli 16:30).

Wípé ọkùnrin náà bèèrè ìbéèrè yìí fihàn wípé ó mọ ìnílò ìgbàlà rẹ̀—ó rí ikú nìkan fúnra rẹ̀, ó sì mọ̀ wípé òun nílò ìrànlọ́wọ́. Òtítọ́ wípé ó bi Pọ́ọ̀lù àti Sílà léèrè fihàn wípé ó gbàgbọ́ wípé wọ́n ní dáhùn.

Ìdáhùn náà wá ní kánkán òun ìrọ̀rùn: "Gba Jésù Krístì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là" (ẹ̀ṣẹ̀ 31). Àyọkà náà tẹ̀sìwájú láti fihàn bí ọkùnrin náà ṣe gbàgbọ́ tí ó sì yípadà. Ayé rẹ̀ sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sìí ní ṣe ọ̀tun láti ọjọ́ yẹn lọ síwájú.

Kíyèsi wípé ìyípadà ọkùnrin náà dá lórí ìgbàgbọ́ ("Gbàgbọ́"). Òun nílò láti gbẹ́kẹ̀lé Jésù kò sì sí nǹkan míìrán. Ọkùnrin náà gbàgbọ wípé Jésù ni ọmọ Ọlọ́run ("Olúwa") àti Mesiah ẹnití ó mú ìwé mímọ́ ṣẹ ("Kristi"). Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wípé Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tí ó sì jí dìde padà, nítorí wípé ìròyín tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ńwàásù rẹ̀ nìyẹn (wo Romu 10:9-10 àti 1 Kọrinti 15:1-4).

Láti "yípadà" jẹ́ "láti yípo." Nígbàtí a bá yípadà sí nǹkankan, a ní láti yípadà kúrò nínú àwọn nǹkan míìrán. Nígbàtí a yípadà sí Jésù, a gbọ́dọ̀ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Bíbélì pe ìyípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ní "ìrònúpìwàdà" àti ìyípadà sí Jésù ni "ìgbàgbọ́." Nítorínàá, ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ bá ara wọn mu. Àfihàn ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ wà nínú Tẹsalonika Kínní 1:9—"Ẹ̀yín ti yípadà sí Ọlọ́run kúrò nínú ère." Onígbàgbọ́ yóò gbé ìgbe-ayé àtijọ́ sẹ́yìn àti ohunkóhun tí ó jọ mọ́ ẹ̀sìn èké gẹ́gẹ́ bíi àyọrísí ìyípadà tòótọ́ sí ìgbàgbọ́.

Láti jẹ́ kí ó rọrùn, láti yípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni, o gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ wípé Jésù ni ọmọ Ọlọrun tí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí ó sì jí dìde padà. O gbọ́dọ̀ gbà fún Ọlọ́run wípé ìwọ́ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó nílò ìgbàlà, kí o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù nìkan láti gbà ọ́ là. Nígbàtí o bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sí Kristi, Ọlọ́run ṣe àwọn ìlérí láti gbà ọ́ là àti láti fún ọ ní Ẹ̀mí Mímọ́, Ẹni tí yóò fún ọ ní ìgbé-ayé titun.

Ìgbàgbọ́, ní ipò òtítọ́ rẹ, kìí ṣe ẹ̀sìn. Ẹ̀sìn Kristiẹni gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì, jẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristi. Ẹ̀sìn Kristiẹni ni ọrẹ ìgbàlà Ọlọ́run sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ àti gbẹ́kẹ̀lé ìrúbọ Jésù lórí igi àgbélèbú. Ẹnití ó bá yípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni kò fi ẹ̀sìn kan sílẹ̀ fún ẹ̀sín míìrán. Ìyípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni ni gígba ẹ̀bùn tí Ọlọ́run pèsè àti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìbásepọ̀ ara ẹni pẹ̀lú Jésù Kristi tí ó yọrí sí ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun ní Ọ̀run lẹ́yìn ikú.

Ṣé o fẹ́ láti yípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni nítorí ohun tí o ti kà nínú àròkọ yìí. Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, èyí ni àdúrà ìrọ̀rùn tí o lè gbà sí Ọlọ́run. Gbígba àdúrà yìí, tàbí àdúrà míìrán, kò ní gbà ọ́. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Kristi nìkan ló le gbà ọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Àdúrà yìí jẹ́ ọ̀nà láti fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn sí Ọlọ́run àti láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ìpèsè fún ìgbàlà rẹ. "Ọlọ́run, mo mọ̀ pé mo ti d'ẹ́ṣẹ̀ sí Ọ mo sì l'ẹ́tọ̀ọ́ sí ìjìyà. Ṣùgbọ́n Jésù Kristi mú ìjìyà tí mo l'ẹ́tọ̀ọ́ sí kí ó le jẹ́ wípé mo le gba ìdáríjìn nípa ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Mo fi ìgbàgbọ́ mi sínú Rẹ fún Ìgbàlà. O seun fún ore-ọ̀fẹ́ ìyanu àti ìdáríjìn — ẹ̀bùn ìyè ayérayé!" Àmín

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni mo ṣe lè yípadà sí ẹ̀sìn Kristiẹni?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries