settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé àwa yóò lè rí kí á sì dámọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa ní ọ̀run?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sọ wípé ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe nígbàtí wọ́n bá dé ọ̀run ni làti rí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ àti olólùfẹ́ wọn tí wọ́n ti kú ṣáájú wọn. Ní ayérayé, ọ̀pọ̀ ààyè ni yóò wà láti rí, mọ̀, àti lo àkókò pẹ̀lu ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Ṣùgbọ́n, èyí kò ní jẹ́ kókó àfojúsùn wa ní ọ̀run. Àwa yóò ti fi ara wa jìn fún ìsìn Ọlọ́run tí àwa yóò sì máa gbádùn iṣẹ́ ìyanu ti ọ̀run. Àtúnrí pẹ̀lu àwọn olólùfẹ́ wa ṣeé ṣe kí ó kún fún ìrántí ore-ọ̀fẹ́ àti ògo Ọlọ́run nínú ayé wa, ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ agbára Rẹ̀. Àwa yóò yọ̀ dáadáa nítorí wípé a lè yìn àti sin Olúwa ní àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ yòókù, pàápàá jùlọ àwọn olùfẹ́ wa ní ilé-ayé.

Kínni Bíbélì sọ nípa bóyá àwa yóò le dá ènìyàn mọ̀ ní ayé tí ó ńbọ̀? Ọba Sọọlu dá Samuẹli mọ̀ nígbàtí àjẹ́ Ẹnidọri pe Samuẹli jáde láti inú òkú (1 Samueli 28:8-17). Nígbàtí ọmọ Dafidi kú, Dafidi kéde, "Èmi yóò tọ̀ ọ́ lọ , òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá (Samuẹli keji 12:23). Dafidi lérò wípé òun yóò lè dá ọmọ òun mọ̀ l'ọ́ọ̀run, bí ó tilẹ̀ jẹ wípé ó kú ní kékeré. Nínú Luku 16:19-31, Abrahamu, Lasaru, àti ọkùnrin ọlọ́rọ dá ara wọn mọ̀ lẹ́yìn ikú. Ní òkè ìpaláradà, wọ́n dá Mose àti Elija mọ̀ (Matteu 17:3-4). Nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyìí, Bíbélì ṣe àfihàn rẹ̀ wípé àwa yóò dá ara wa mọ̀ lẹ́yìn ikú.

Bíbélì sọ wípé tí a bá dé ọ̀run, a ó "dà bi Rẹ̀ [Jésù]; nítorí àwa ó ri i àní bí ó ti rí" (1 Johannu 3:2). Gẹ́gẹ́ bí ara èrùpẹ̀ wa ti rí bíi tí ọkùnrin ìṣáájú, Adamu, bẹ́ẹ̀ni ara àjíǹde wa yóò ti rí bíi ti Kristi (1 Kọrinti 15:47). "Bí àwa sì ti ru àwòrán ẹni èrùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ni àwa ó sì ru àwòrán ẹni ti ọ̀run. Nítorípé ara ìdibàjẹ́ yìí kò le sàìgbé àìdibàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò le sàìgbé ara àìkú wọ̀" (1 Kọrinti 15:48, 53). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn dá Jésù mọ̀ lẹ́yìn àjíǹde Rẹ̀ (Johannu 20:16, 20; 21:12; 1 Kọrinti 15:4-7). Bí a bá dá Jésù mọ̀ nínú ara ògo Rẹ̀, àwa yóò dá àwa náà mọ̀ pẹ̀lú nínú ara ògo wa. Àti le rí àwọn olólùfẹ́ wa jẹ́ ara ògo ọ̀run, ṣùgbọ́n ọ̀run ńsọ púpọ̀ nípa Ọlọ́run, àti díẹ̀ nípa wa. Ayọ̀ ni yóò jẹ́ láti se àtúnrí pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa àti láti sin Ọlọ́run pẹ̀lú wọn ní ayérayé.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ṣé àwa yóò lè rí kí á sì dámọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa ní ọ̀run?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries