settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni a ti ṣe gba àwọn ènìyàn là ṣáájú ikú Jésù?

Idahun


Láti ìgbà ìṣubú ènìyàn, ìgbàlà ti dá lórí ikú Kristi láti ìgbàgbogbo. Kò sí ẹnìkan, yálà ṣáájú àgbélèbú tàbí láti ìgbà àgbélèbú, tí a ó le gbàlà láì sí ìṣẹ̀lẹ̀ gbòógì yẹn nínú ìtàn ayé. Ikú ti Kristi san ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ti àwọn àyànfẹ́ Májẹ̀mú Láíláí àti fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àyànfẹ́ ti Májẹ̀mú Titun.

Àmúyẹ fún ìgbàlà ti jẹ́ ìgbàgbọ́ láti ìgbàgbogbo. Ohun tí ìgbàgbọ́ ẹni ńdojúkọ fún ìgbàlà ti jẹ́ Ọlọ́run láti ìgbàgbogbo. Olórin kọ wípé, Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn ti o gbẹ́kẹ̀ wọn lé e." (Orin Dafidi 2:12). Jẹnẹsisi 15:6 sọ fún wa wípé Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́ àti wípé ìyẹn tó fún Ọlọ́run láti kàá fún-un bíi òdodo (tún wo Romu 4:3-8). Ètò ìrúbọ Májẹ̀mú Láíláí kò mú ẹ̀ṣẹ̀ lọ, bí Heberu 10:1-10 ti kọ́ni kedere. Ṣùgbọ́n, ó ńtọ́kasí ọjọ́ náà nígbàtí Ọmọ Ọlọ́run yóò ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ fún ìran ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ohun tí ó ti yípadà láti ìran dé ìran ni àkóónú ìgbàgbọ́ tí onígbàgbọ́. Ohun ti Ọlọ́run ńbèrè tí a ńní láti gbàgbọ́ dálé lórí iye ìfihàn tí Òun fún ènìyàn títí dé àkókò yẹn. Èyí ni a pè ní ìfihàn tí ó ńtẹ̀síwájú. Adamu gba ìlérí tí Ọlọ́run fún-un ní Jẹnẹsisi 3:15 gbọ́ wípé Irú-ọmọ obìnrin náà yóò ṣẹ́gun sátánì. Adamu gbà Òun gbọ́, èyí tí ó farahàn nípasẹ̀ orúkọ tí ó fun Efa (ẹsẹ̀ 20) tí Olúwa si tọ́kasi ìtẹ́wọ́gbà lọ́gán nípasẹ̀ bíbò wọ́n pẹ̀lú ẹ̀wù awọ (ẹsẹ̀ 21). Ní àkókò yẹn ohun gbogbo tí Adamu mọ̀ nìyẹn, ṣùgbọ́n òun gbàá gbọ́.

Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi àwọn ìlérí àti ìfihàn titun ti Ọlọ́run fún ni Jẹnẹsisi 12 àti 15. Ṣáájú Mose, kò sí Ìwé Mímọ́ kankan tí a kọ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìran ènìyàn ní ojúṣe fún ohun ti Ọlọ́run ti fihàn. Ní gbogbo Májẹ̀mú Láíláí, àwọn onígbàgbọ́ ńwá sí ìgbàlà nítorí wọn gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yóò ṣe ìtọ́jú ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni ọjọ́ kan. Lóòní, àwa wo ẹ̀yìn wò, wípé Òun ti bójútó àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí àgbélèbú (Johannu 3:16; Heberu 9:28).

Àwọn onígbàgbọ́ tí wọn wà ni ìgba ayé ti Kristi, ṣáájù àkókò àgbélébú àti àjíǹde ńkọ́? Kínni wọn gbàgbọ́? Ǹjẹ́ wọn ni òye àwòrán wípé kíkú Kristi lórí àgbélébú wà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn? Ní ìgbà ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ńparí, "Láti igbana lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ si ífihàn àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ bi òun kò ti lè ṣàìlọ si Jerusalemu, láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí alufa, àti àwọn akọ̀wé, kí a si pa òun, àti ni ọjọ́ kẹta, kí òun si jíǹde" (Matteu 16: 21-22). Báwo ni àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ṣe ṣe sí ìwáàsù yìí? "Nígbàná ni Peteru múu, o bẹ̀rẹ̀ si iba a wí wípé 'Kí a ma rii Olúwa, 'Kì yio ri bẹ́ẹ̀ fún ọ!'" Peteru àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn míìrán kò mọ òtítọ́ l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́, síbẹ̀ a ti gbà wọn là nítorí wọn gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yóò yanjú ìṣòro ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn kò mọ̀ ní pàtó bí Òun yóò ṣe ṣe ìyẹn, ju bí Adamu, Abrahamu, Mose tàbí Dafidi ṣe mọ̀, ṣùgbọ́n wọn gba Ọlọ́run gbọ́.

Lóòní, àwá ní ìfihàn ju àwọn tí wọn ńgbé ṣáájú àjíǹde Kristi; àwá ní òye l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́. "Ọlọ́run, ẹni, ni ìgbà púpọ̀ àti li onírúurú ọ̀nà, tí ó ti ipa àwọn wòólìí ba àwọn baba ṣọ̀rọ̀ nígbàání. Ni ìkẹhìn ọjọ́ wọ̀nyìí o ti ipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀, ẹnití o fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹnití o dá àwọn ayé pẹ̀lú" (Heberu 1:1-2). Ìgbàlà wa ṣì dá lórí ikú Kristi, ìgbàgbọ́ wa ṣì ni àmúyẹ fún ìgbàlà, ohun ti ìgbàgbọ́ wa ṣì ńdojúkọ ni Ọlọ́run. Lóòní, fún wa, àkóónú ìgbàgbọ́ wa ni wípé Jésù Kristi kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, A sín-in, àti wípe Òun jí dìde ní ọjọ́ kẹta (1 Kọrinti 15:3-4).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni a ti ṣe gba àwọn ènìyàn là ṣáájú ikú Jésù?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries