settings icon
share icon
Ibeere

Tani Sàtanì?

Idahun


Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn nípa Sàtanì wà jákèjádò—láti ọmọ ọkùnrin kékeré pupa oního tí ó jókóò lórí èjìká ènìyàn láti mú ni dẹ́ṣẹ̀ àti sí àwòrán tí ó ṣàlàyé àfiwé tàrà fún ibi. Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi àwòrán kedere nípa ẹni tí Sàtanì jẹ́ àti ọ̀nà tí ó fi ńṣe àkóbá fún ayé wa hàn. Láì déènà pẹnu, Bíbélì ṣe àgbékalẹ̀ Sàtanì gẹ́gẹ́ bí ańgẹ́lì tó ṣubú kúrò ní ipò rẹ̀ lọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀, tó sì wá dojúkọ Ọlọ́run pátápátá nísìnsinyíí, tí ó ńṣe ohun gbogbo tó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ láti ba ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́.

A ṣẹ̀dá Sàtanì gẹ́gẹ́ bí ańgẹ́lì mímọ́ kan. Ìwé Isaiah 14:12 ṣàlàyé pé Lúsíférì ní orúkọ tí Sàtanì ńjẹ́ kí ó tó di wípé ó ṣubú. Ìwé Esikiẹli 28: 12-14 ṣàlàyé wípé Kérúbù ni a dá Sàtanì tẹ́lẹ̀, ó sì jọ wípé òun ni ańgẹlì tí ó ga jùlọ tí a ṣẹ̀dá. Òun gbérága nínú ẹwà àti ipò rẹ̀, ó sì pinnu láti jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga ju ti Ọlọ́run lọ (Isiah 14:13-14; Esikiẹli 28: 1; 1 Tìmoteu 3:6). Ìgbéraga Sàtanì ló fa ìṣubú rẹ̀. Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ "èmi o" nínú Ìwé Isaiah 14:12-15. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọ́run fi lé Sàtanì kúrò lọ́run.

Sàtanì di aláṣẹ ayé àti aláṣẹ ẹ̀mí tí ó wà nínú òfuurufú (Johannu 12:31, 2 Kọrinti 4:4; Efesu 2:2). Olùfisùn ni (Ifihan 12:10), olùdánniwò ni (Matteu 4:3; 1 Tẹssalonika 3:5), àti atannijẹ sì ni (Jẹnẹsisi 3; 2 Kọrinti 4:4; Ifihan 20:3). Orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí "ọ̀tá" tàbí "èyí tí ó ńtako nńkan". Àkorí rẹ̀ míìrán ni èṣù tí ó túmọ̀ sí "ẹlẹ́gàn."

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a ti le kúrò ní ọ̀run, òun ṣí tún ńwá bí ó ṣe lè gbé ìtẹ́ rẹ̀ gaju ti Ọlọ́run lọ. Ó ńṣe àdàmọ́dì ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá ńṣe, ní ìrètí pé kí àwọn ènìyàn máa sìnín àti mú kí ìṣelòdì sí ìjọba Ọlọ́run tẹ́síwájú. Èṣù ni orísun gbogbo ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti ẹ̀sìn ayé. Sàtanì lè ṣe ohun kóhun àti ohun gbogbo ní ìkáwọ́ rẹ̀ láti kọjú ìjà sí Ọlọ́run àti àwọn tí ó ńtẹ̀le Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, a ti di àyànmọ́ Sàtanì—ayérayé nínú adágún iná (Ifihan 20:10)

English


Pada si oju ewe Yorùbá

Tani Sàtanì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries