settings icon
share icon
Ibeere

Tani ó ṣẹ̀dá Ọlọ́run? Níbo ni Ọlọ́run ti wá?

Idahun


Àríyànjiyàn tí ó wọ́pọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbágbọ́ nínú Ọlọ́run àti oníyèméjì ni wípé ohun gbogbo ló ní orísun, à ti fún ìdí èyí Ọlọ́run náà gbọ́dọ̀ ní orísun. Ìparí rẹ̀ ni wípé tí Ọlọ́run bá ní orísun, Ọlọ́run kìí ṣe Ọlọ́run nígbànáà (tí Ọlọ́run kìí bá sì ṣe Ọlọ́run, ó tùmọ̀ sí wípé kò sí Ọlọ́run nìyẹn). Èyì jẹ́ ìbéèrè ìpìlẹ̀ tí ó mú fáfá "Tani ó dá Ọlọ́run?" Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ wípé ǹkankan kò wá láti inú òfo. Bí Ọlọ́run bá wá jẹ́ "nǹkan," Ó gbọ́dọ̀ ní orísun nígbànáà, òótọ́ ni bí?

Ìbéèrè náà lọ́jú nítorí wípé ó ńmú kí àròsínú òdì ó yọ jáde wípé Ọlọ́run wá láti ibì kan tí ó sì ńbéèrè wípé níbo ni èyí lè jẹ́. Ìdáhùn ni wípé ibéèrè náà kò ti lẹ̀ mu ọpọlọ dání. Ó dàbí ká máa béèrè wípé, "Báwo ni àwọ̀ búúlù ṣé ńrùn?" Àwọ̀ búúlù kò sí nínú ẹ̀ka àwọn ohun tí a le gbóòórùn, ìbéèrè náà tìkalárarẹ̀ ti gba ìjákulẹ̀. Ní ọ̀nà kannáà, Ọlọ́run kò sí ní ẹ̀ka àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá tàbí ní orísun. Ọlọ́run kò ní orísun a kò sì dáa—Óun ṣà wà láàyè.

Báwo ni a ṣe mọ ẹ̀yí? A mọ̀ wípé láti inú òfo, kò sí ǹkankan. Nítorí náà, bí àkókò kan bá ti wà tí kò sí ǹkankan láyé, kò sí ohun kan tí yóò wà láyé. Ṣùgbọ́n àwọn ǹkankan wà láàyè. Nítorínà, níwọ̀n bí kò le sí òfo pátápátá, ǹkankan gbọ́dọ̀ ti wà láàyè. Ohun kannáà tí ó ti wà ní à ńpè ní Ọlọ́run. Ọlọ́run jẹ́ Ẹni tí kò ní orísun tí ó sì jẹ́ kí ohun gbogbo ó wà láàyè. Ọlọ́run ni Aṣẹ̀dá tí a kò ṣẹ̀dá tí ó dá gbogbo ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Tani ó ṣẹ̀dá Ọlọ́run? Níbo ni Ọlọ́run ti wá?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries