Ibeere
Ṣé Ọlọ́run ṣẹ̀dá ibi?
Idahun
Ní àkọ́kọ́ yóò dàbi wípé bí Ọlọ́run bá dá ohun gbogbo, nígbà náà ó gbọ́dọ̀ jẹ́ wípé a dá ibi nípasẹ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ibi kìí ṣe "ohun" kan bíi òkúta tàbí iná-mọ̀nàmọ́ná. O kò lè ní ife ibi kan. Ibi kò ní ibùgbé ti ara rẹ̀; ní òtítọ́ ó jẹ́ àìsí rere. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ihò jẹ́ òtítọ́ ṣùgbọ́n wọn wà nínú nǹkan míìrán. A pe àìsí ìdọ̀tí ní ihò, ṣùgbọ́n a kò lè yàá kúrò ní ìdọ̀tí. Nítorí náà nígbàtí Ọlọ́run ṣẹ̀dá, ó jẹ́ òtítọ́ wípé ohun gbogbo ti Òun dá jẹ́ rere. Ọ̀kan lára àwọn ohun rere tí Ọlọ́run dá ni àwọn ẹ̀dá tí wọn ní òmìnira láti yan rere. Láti lè yàn ní tòótọ́, Ọlọ́run ńní láti gbà láàyè nǹkan míìràn yàtọ̀ sí rere láti yàn. Nítorí náà, Ọlọ́run gba àwọn angẹli tí wọn ní òmìnira àti àwọn ènìyàn wọ̀nyìí láàyè láti yan rere tàbi kọ rere (ibi). Nígbàtí àjọsepọ̀ tí kò dára bá wà láàrín nǹkan rere méjì, ṣùgbọ́n kò ní di "nǹkan" tí ó nílò Ọlọ́run láti ṣẹ̀dá rẹ̀.
Bóyá àlàyé síwájú sí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́. Bí a bá bi ẹnìkan wípé, "Ṣe otútù wà?" ìdáhùn yóò fẹ̀ẹ́ jẹ́ "bẹ́ẹ̀ni." Ṣùgbọ́n, èyí kò tọ́. Otútù kò sí. Otútù jẹ́ àìsí ooru. Bákannáà, òkùnkùn kò sí, o jẹ́ àìsí ìmọ́lẹ̀. Ibi jẹ́ àìsí rere, tàbí, ibi jẹ́ àìsí Ọlọ́run. Ọlọ́run kò ní láti ṣẹ̀dá ibi, ṣùgbọ́n Òun kàn gbà àìsí rere láàyè nìkan dípò.
Ọlọ́run kò ṣẹ̀dá ibi, ṣùgbọ́n Òun gba ibi láàyè. Bí Ọlọ́run kò bá gba ṣíṣeéṣe ibi láàyè, ènìyàn àti àwọn angẹli yóò máa sin Ọlọ́run láti nú àìgbọdọ̀ máṣe, tí kìí ṣe ohun tí a yàn. Òun kò fẹ́ "ẹ̀rọ-ṣìgìdì"tí yóò kàn máa ṣe ohun tí Òun fẹ́ kí wọn ṣe nítorí "ètò" inú wọn. Ọlọ́run gba ṣíṣeéṣe ibi láàyè kí a baà lè ní ọkàn láti yàn l'ótìtọ́ọ́ bóyá àwa fẹ́ sìín tàbí a kò fẹ́ sìín.
Gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn tí ó ní òpin, àwa kò lè ní òye Ọlọ́run tí kò ní òpin l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ (Romu 11:33-34). Nígbàmíì àwa lérò wípé àwa ní òye ìdí tí Ọlọ́run fi ńṣe ohun kan, kí a tó wá mọ̀ nígbà ó ṣe wípé ó wà fún ète míìrán ju ohun tí àwa lérò tẹ́lẹ̀. Ọlọ́run má ńwo àwọn nǹkan láti ìwò mímọ́ àti ayérayé. Àwa máa ńwo àwọn nǹkan láti ìwò ẹ̀ṣẹ̀, ti ayé, àti fún ìgbà díẹ̀. Kínni ìdí tí Ọlọ́run fifi ènìyàn sórí ayé nígbàtí Òun mọ̀ wípé Adamu àti Efa yóò d'ẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò si mú ibi, ikú àti ìjìyà bá gbogbo ènìyàn? Kínni ìdí tí Òun kò ṣe ṣẹ̀da gbogbo wa kí ó sì fi wá sílẹ̀ ní ọ̀run níbití àwa yóò ti wà ní pípé láìsí ìjìyà? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyìí ni a kò lè dáhùn dáradára ní ihà ayérayé yìí. Ohun tí a le mọ̀ ni wípé ohunkóhun tí Ọlọ́run bá ṣe jẹ́ mímọ́ àti pípé tí yóò sì fi ògo fún-Un. Ọlọ́run gba ṣíṣeéṣe ibi láàyè kí ó baà lè fún wa ní yíyàn ní tòótọ́ nípa bóyá àwa yóò sìín Òun. Ọlọ́run kò ṣẹ̀dá ibi, ṣùgbọ́n Òun gba a láàyè. Bí Òun kò bá gba ibi láàyè, àwa yóò máa sìín gẹ́gẹ́ bíi àigbọ̀dọ̀ máṣe, tí kìí ṣe ohun kan tí ènìyàn lè yàn fúnra rẹ̀.
English
Ṣé Ọlọ́run ṣẹ̀dá ibi?