Báwo ní mo ṣè lè polongo ìhìnrere fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹ̀bí míi láì ṣẹ̀ wọ́n tàbí tì wọn danù?


Ibeere: "Báwo ní mo ṣè lè polongo ìhìnrere fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹ̀bí míi láì ṣẹ̀ wọ́n tàbí tì wọn danù?"

Idahun:
Ní àwọn ìgbà kan, gbogbo Kristiẹni ti ní mọ̀lẹ́bí kan, ọ̀rẹ́ kan, olùbáṣiṣẹ́pọ̀ kan, tàbí ojúlùmọ̀ tí kìí ṣe Kristiẹni. Pínpín ìhìnrere pẹ̀lú ẹlòmíràn lè nira ó sì tún wà lè nira gan-an nígbà tí ó bá nííṣe pẹ̀lú ẹni tí o súnmọ̀ ni típẹ́-típẹ́. Bíbélì sọ fún wa wípé àwọn ènìyàn kan yòó kọsẹ̀ sí ìhìnrere (Luku 12: 51-53). Ṣùgbọ́n, a ti pá àṣẹ fún wa láti pín ìhìnrere náà, kò sì sí àwáwí láti ma ṣe bẹ́ẹ̀ (Matteu 28:19–20; Iṣe wọn Apọsteli 1:8; 1 Peteru 3:15).

Nítorí náà, báwo ní a ṣe lè polongo ìhìnrere fún àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, alábàṣìṣẹ́pọ̀ àti ojúlúmọ̀ wa? Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ náà tí a lè ṣe ní láti gbàdúrà fún wọn. Gbàdúrà wípé kí Ọlọ́run yí wọn l'ọ́kàn padà kí Òun sì ṣí ojú wọn sí òtítọ́ tí ńbẹ nínú ìhìnrere náà (2 Kọrinti 4:4). Gbàdúrà wípé Ọlọ́run yóò fi ìdánílójú ìfẹ́ Rẹ̀ fún wọn àti àìní wọn fún ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Kristi hàn wọ́n (Johannu 3:16). Gbàdúrà fún ọgbọ́n nípa ọ̀nà tí ó dárá jùlọ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn (Jakọbu 1:5).

A gbọ́dọ̀ ṣetán láti ṣe àjọpín ìhìnrere náà gan-an kí á sì ní ìgboyà. Kéde ìròyìn igbàlà náà nípasẹ̀ Jésù Kristi fún àwọn ọrẹ́ àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ (Romu 10:9–10). O gbọ́dọ̀ wà ní ìgbaradì nígbàgbogbo láti sọ nípa ìgbàgbọ́ rẹ (1 Peteru 3:15), ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́ àti ọ̀wọ̀. Kò sí pàsíípàrọ̀ fún pínpín ìhìnrere náà ní àwa tìkàlára wa: "Njẹ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti i wa, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run" (Romu 10:17).

Ní àfikún sí gbígba àdúrà atí ṣíṣe àjọpín ìgbàgbọ́ wa, a tún gbọ́dọ̀ gbé ìgbé-ayé Kristiẹni ní ìwà bí Ọlọ́run l'ójú àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wa kí wọ́n ba lè rí àyípadà tí Ọlọ́run ti ṣe nínú wa (1 Peteru 3:1–2). Ní ìkẹhìn, a gbọ́dọ̀ fi ìgbàlà àwọn olólùfẹ́ wa sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Agbára àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni o ńgba ènìyàn là, kìí ṣe ipá wa. Èyí tí ó dára jùlọ tí a lè ṣe ni láti gbàdúrà fún wọn, ṣe ìjẹ́ri sí wọn, kí á sì gbé ìgbé-ayé Kristiẹni l'ójú wọn. Ọlọ́run ní o ńmú ìbísí wá (1 Kọrinti 3:6).

English


Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ní mo ṣè lè polongo ìhìnrere fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹ̀bí míi láì ṣẹ̀ wọ́n tàbí tì wọn danù?