settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ píparun bá Bíbélì mu?

Idahun


Píparun jẹ́ ìgbàgbọ́ wípé àwọn aílàgbàgbọ̀ kò ní ní ìrìrí ti ayérayé nípa ìjìyà nínú ọ̀run-àpáàdì, ṣùgbọ́n wípé wọn yóò "ti parun" lẹ́hín ikú. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, píparun jẹ́ ìgbàgbọ́ tí o wu ni nitorí bí èrò wípé àwọn ènìyàn yóò lo ayérayé ní ọ̀run-àpáàdì ṣe burú. Níwọn ìgbàtí àwọn ẹsẹ díẹ̀ kan wà tí wọn jọ wípé wọn fẹ́ faramọ ìjiyàn lóri píparun, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwòye sí ohun tí Bíbélì ńwí nípa àyànmọ́ ṣe àfihàn òtítọ́ wípé ẹni búburú yóò jìyà ní ọ̀run-àpáàdì fún ayérayé. Ìgbàgbọ́ nínú píparun yóò wáyé látàrí àìní òye kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyìí : 1) àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀, 2) ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, 3) àbùdá ọ̀run-àpáàdì.

Ní ìbámu pẹ̀lú àbùdá ọ̀run-àpáàdì, àwọn tí ó di ẹ̀kọ́ píparun mú kò ní òye ìtúmọ̀ adágún iná. Ó hàn gbangba wípé, bí a bá ju ènìyàn kan sí inú adágún iná olókùúta tí ńjó náà, ẹni náà l'ọ́kùnrin/l'òbìnrin yóò jóná lójúkannáà. Síbẹ̀síbẹ̀, adágún iná náà jẹ́ tí ara tí a lè f'ojú rí àti ipele ti ẹ̀mí. Kìí kàn ṣe sísọ àgọ́ ara ènìyàn sí inú adágún iná; ó jẹ́ àgọ́ ara ènìyàn, ọkàn, àti ẹ̀mí. Àbùdá ti ẹ̀mí kò lè jẹ́ píparun nípa iná tí a lè f'ojú rí. Ó jọ wípé ẹni tí a kò gbàlà yóò jí dìde pẹ̀lú àgọ́ ara tí a palẹ̀mọ́ fún ayérayé gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a ti gbàlà (Ifihan 20:13; Iṣe awọn apọsteli 24:15). Àwọn àgọ̀ ara yìí ní a ti palẹ̀mọ́ fún ipò ti ayérayé.

Ayérayé tún jẹ́ ìṣọ̀rí mìírán tí àwọn oní ẹ̀kọ́ píparun kùnà láti ní òye rẹ̀ ní kíkún. Àwọn oní ẹ̀kọ́ píparun, sọ òtìtọ́ wípé ọ̀rọ̀ Gíríkì náà aionion èyí tí a máa ńsábà túmọ̀ sí "ayérayé", nípa ìtumọ̀ kò túmọ̀ sí "ayérayé. Ní pàtó ó túmọ sí "àkókò kan" tàbí "agbára àtòkèwá tí o gùn ní àkókò", àkókò ìgbà kan ní pàtó. Síbẹ̀síbẹ̀, ó hàn kedere nínú Májẹ̀mú Titun wípé aionion ni a máa nsábà lò ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti tọ́kasi àkókò ìgbà kan fún ayérayé. Ifihan 20:10 ńsọ nípa Satani, ẹranko náà, àti àwọn wòólì èké ti a jù sínú adágún iná tí a sì ńdálóró "ní ọ̀sán àti òru láí àti láíláí. Ó sì hàn kedere wípé àwọn mẹ́ta wọ̀nyìí kò "parun" nípa jíjù wọn sínú adágún iná. Kílódé ti ìpín àwọn tí a kò gbàlà yóò ṣe yàtọ̀ (Ifihan 20:14-15)? Ẹ̀rí tí ó dánilójù jùlọ fún ayérayé ọ̀run-àpáàdì ni Matteu 25:46, "Lẹ́hìn náà àwọn [ẹni tí kò di ẹni ìgbàlà wọn ó lọ sí ìjìyà ayérayé, ṣùgbọ́n olódodo sí ìyè ayérayé." Nínú ẹ́sẹ̀ yìí, ọrọ̀ Gíríkì kan náà ní a lò látí tọ́kasí àyànmọ́ ti ẹni búburú àti olódodo. Bí a bá pọ́n àwọn ẹni búburú lójú fún "ìgbà kan," lẹ́hìn náà olódodo yóò kàn ní ìrírí ìyè ayérayé ní ọ̀run fún "ìgbà kan" nìkan ni. Bí àwọn onígbàgbọ́ bá máa wà ní ọ̀run títí láíláí, àwọn aláìgbàgbọ́ yóò wà ní ọ̀run-àpáàdì títí láíláí.

Àtakò míìrán lóòrèkórè sì ayérayé ti ọ̀run-àpáàdì nípa àwọn oní ẹ̀kọ́ píparun ni wípé yóò jẹ́ àìṣòdodo fún Ọlọ́rún láti jẹ aláìgbàgbọ́ ní ìyà ní ọ̀run-àpáàdì fún ayérayé fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ní òdiwọ̀n. Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe ṣe òdodo láti mu ẹnìkan tí ó gbé ìgbé-ayé ẹ̀ṣẹ̀, fún àádọ́rin (70) ọdún, àti ìjìya rẹ̀ l'ọ́kùnrin/l'óbìnrin fún gbogbo ayérayé? Ìdáhùn náà ni wípé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ńbí àtubọ̀tán ayérayé nítorí a dáa lòdì sí Ọlọ́run ayérayé. Nígbàtì Ọba Dafídí dá ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè àti ìpànìyàn ó wípé, "Ìwọ, ìwọ nìkanṣoṣo ní mo ṣẹ̀ sí, tí mo ṣe búburú yìì níwájú rẹ̀..."(Orin Dafidi 51:4). Dáfídì ti dá ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí Bátṣébà àti Ùriah; báwo ní Dáfídì ṣe lè jẹ́wọ́ wípé sí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni òun dá ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí? Dáfídì lóye wípé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ní ìkẹhìn lòdì sí Ọlọ́run. Ọlọ́run jẹ́ ayérayé àtí ẹ̀dá tí kò l'ópin. Látàri eléyìí, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí Í, tọ́sí ìjìyà ayérayé. Kìí ṣe ìwọn akókò tí ó gùn tí a fi dá ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ̀n ìṣesí Ọlọ́run náà tí a dá ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí.

Ìpín ti ara-ẹni ti ẹ̀kọ́ píparun ni òye wípé inú wa lè má dùn ní ọ̀run bí a bá mọ̀ wípé lára àwọn olólùfẹ̀ẹ́ wa ńjìyà ayérayé kan pẹ̀lú ìpọ́njú ní ọ̀run-àpáàdì. Síbẹ̀sìbẹ̀ nígbà tí a bá ti gúnlẹ̀ ní ọ̀run, a kò ní lè ní nǹkan kan láti ṣe àwáwí nípa tàbí ní ìbànújẹ́ nípa rẹ̀. Ifihan 21:4 sọ fún wa wípé "Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn. Kì yóò sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ni kì yóò sí ìròra mọ́: nítorípé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ." Bí díẹ̀ nínú àwọn olólùfẹ wa kò bà sí ní ọ̀run a ó wà ní gbígbà ni ìdá ọgọ́rùn (100) pípé wípé wọn kò sí ní ibẹ̀ àti wípé wọn jẹ́ ẹni idalẹ̀bí nípa kíkọ láti gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà (Johannu 3:16; 14:6). Ó le láti lóye nǹkan wọ̀nyìí, ṣùgbọ́n a kò gbọ̀dọ̀ nì ìbánújẹ́ nípa àìsí níbẹ wọn. Ìfojúsùn wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ lórì bí a ṣe ńgbádùn ní ọ̀run láìsí gbogbo àwọn olólùfẹ̀ẹ́ wa níbẹ̀, ṣùgbọ́n bí a ṣè lè tọ́ka àwọn olólùfẹ̀ẹ́ wa sí ìgbàgbọ́ nínú Kristi kí wọ́n baà lè wà níbẹ̀.

Ọ̀run-apáàdì tilẹ̀ lè jẹ́ ìdí àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run fi rán Jésù Kristi wá láti san ìtanràn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ní "píparun" lẹ́hìn ikú kìí se àyànmọ lati bẹrù, ṣùgbọ́n ayérayé nínù àpáàdì ní dájúdájú jùlọ. Ikú ti Jésù jẹ́ ikú àìlópin, sìsan igbèsè ẹ̀ṣẹ̀ àìlópin, kí a má bàa san án ni ọ̀run-àpáàdì fún ayérayé (2 Kọrinti 5:21). Nígbà ti a bá gbé ìgbàgbọ́ wa sí inú Rẹ̀, a ti gbà wá là, dárìjì wàá, wẹ̀ wá mọ́ àti ìlérí ti ilé ayérayé ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n bí a bá kọ ẹ̀bun t'Ọlọ́run ti ìyè ayérayé, a má a dojúkọ àtúbọ̀tán ayérayé ti ìpinnu náà.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ píparun bá Bíbélì mu?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries