settings icon
share icon
Ibeere

Kínni pàtàkì Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa/Ìdàpọ̀ Onígbàgbọ́?

Idahun


Ẹ̀kọ́ kan lórí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ ìrírí tó ńru ọkàn sókè nítorí ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó ní. Ní àkókò àjọyọ̀ ògbólógbòó Àjọ Ìrékọjá ní àṣàálẹ́ ikú Rẹ̀ ni Jésù ṣe àgbékalẹ̀ oúnjẹ ìdàpọ̀ titun tó l'àpẹrẹ èyí tí à ńṣe títí di òní. Ó jẹ́ ètò kan lára Ìjọ́sìn Onígbàgbọ́. Ó ńmú kí á rántí ikú àti àjíǹde Olúwa wa kí á sì máa wá ìpadàbọ̀ ológo Rẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.

Àjọ Ìrékọjá jẹ́ àpèjẹ tí ó lọ́wọ̀ jùlọ ní ọdún ẹ̀sìn àwọn Júù. Ó ńṣe ìrántí ìkọlù tó kẹ́hìn lórí ilẹ̀ Íjíipiti nígbàtí àkọ́bí àwọn ará Íjíipiti kú tí a sì dá àwọn ọmọ Isrẹli sí nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùtàn tí wọn wọ́n sílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà wọn. Lẹ́hìn náà wọ́n sun ọ̀dọ́ àgùtàn náà wọ́n sì jẹẹ́ pẹ̀lú àìwúkàrà. Àṣẹ Ọlọ́run ni wípé gbogbo ìran to ńbọ̀ ni yóò máa ṣe àjọyọ̀ àṣè náà. Àkọsílẹ̀ ìtàn yìí wà nínú Eksodu 12.

Ní àkókò Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—àjọyọ̀ ìrékọjá—Jésù bu àkàrà Ó sì dúpẹ́ fún Ọlọ̀run. Bí ó ti bùú, ó fifún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀, Ó wípé, "'Èyí ni ara mi tí a fifún yín; ẹ má a ṣe èyí ní ìrántí mì i.' Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́hìn óúnjẹ alẹ́, Ó sì mú ago, Ó wípé ago yìí ni májẹ̀mú titun ní ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín'" (Luku 22:19-21). Ó káàdí àṣà náà nípa kíkọ orin kan (Matteu 26:30), wọ́n sì jáde lọ sórí òkè Ólífì. Níbẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Judasi tí fi Jesu hàn. A kan Jesu mọ́ àgbélèbú ní ọjọ́ kejì.

Àkọsílẹ̀ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni a rí nínú àwọn Ìwé Ìhìnrere (Matteu 26:26-29; Marku 14:17-25; Luku 22:7-22; ati Johannu 13:21-30). Pọ́ọ̀lù àpọ́stélì kọ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní Kọrinti kinni 11:23-29. Pọ́ọ̀lù fi gbólóhùn kan kún-un èyìí tí kò sí nínú àwọn Ìwé Ìhìnrere: "Nítorínà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ àkàrà, tí ó sì mu ago Olúwa láìyẹ̀, yóò jẹ̀bi ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. Ṣùgbọ́n kí ènìyàn kí ó wádì i ara rẹ̀ dájú, bẹ́ẹ̀ni kí ó sì jẹ nínú àkàrà náà, kí ó sì mu nínú ago náà. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ńjẹ, tí ó bá sì ńmu láìmọ̀ ara Olúwa yàtọ̀, ó ńmu ẹ̀bi fún ara Rẹ̀" (2 Kọrinti 11:27-29). A le bèèrè kínni ìtumọ̀ ìbápín níní àkàrà àti ago "ní ọ̀nà àìtọ́." Ó lè jẹ́ aikọbiarasi ìtumọ̀ àkàrà àti ago tòótọ́ àti láti gbàgbé ọ̀wọ́n iye tí Olùgbàlà san fún ìgbàlà wa. Tàbí ó le túmọ̀ sí láti gba àjọyọ̀ náà láàyè kí ó di ìrúbọ òkú tábí kí ó wá sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa pẹ̀lú àìjẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀. Ní pípa ìtọ́ni Pọ́ọ̀lù mọ́, a gbọ́dọ̀ yẹ ara wa wò kí á tó jẹ àkàrà àti mu ago náà.

Gbólóhùn míràn tí Pọ́ọ̀lù sọ èyítí kò sí nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìwé ìhìnrere ni "Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ̀yin bá ńjẹ àkàrà yìí, tí ẹ̀yin bá sì ńmu ago yìí, ẹ̀yin ńkéde ikú Olúwa títí yóò fi dé" (2 Kọrinti 11:26). Èyíí gbé gbèdéke lé orí àjọyọ̀ náà—títí ìpadàbọ̀ Olúwa. Láti inú àkọsílẹ̀ ráńpẹ́ yìí a kọ́ bí Jésù ṣe lo ohun aláìlágbára méjì gẹ́gẹ́ bí ààmìn ara àti ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ tí Òun sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bíi ìrántí ikú Rẹ̀. Kìí ṣe ìrántí tí a fi òkúta tàbí idẹ mímọ ṣe, ṣùgbọ́n ti àkàrà àti ọtí wáìnì.

Ó sọ pé àkàrà ńsọ nípa ara Rẹ̀ èyítí yóò wó. Kò sí egungun kankan tó kán, ṣùgbọ́n ìyà jẹẹ́ gidigidi débi wípé ó le láti dáamọ̀ (Orin Dafidi 22:12-17; Isaiah 53;4-7). Ọtí wáìnì sọ nípa ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀, èyítí ó ńsọ nípa ìrírí ikú burúkú tí yóò rí. Òun, ọmọ Ọlọ́run tó péye, di ìmúṣẹ ìsọtẹ́lẹ̀ Májẹ̀mú Láíláí tí kò níye nípa Óluràpadà (Jẹnẹsisi 3:15; Orin Dafidi 22; Isaiah 53). Nígbàtí Òun wípé, "Ẹ ṣe èyí ní ìrántí mi," Ó fihàn pé èyí jẹ́ àjọyọ̀ tó gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú l'ọ́jọ́ iwájú. Ó fihàn pẹ̀lú pé àjọ ìrékọjá náà, èyítí ó nííse pẹ̀lú ikú ọ̀dọ́ àgùtàn tí a sì f'ojú s'ọ́nà sí bíbọ̀ ọ̀dọ́ àgùtàn Ọlọ́run ẹnití yòò mú ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ, ní a músẹ nínú Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Májẹ̀mú Titun ti rọ́pò Májẹ̀mú Láíláí nígbàtí a ti fi Kristì, Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ìrékọjá (1 Kọrinti 5:7), rúbọ (Heberu 8:8-13). A kò nílò ètò ìrúbọ mọ́ (Heberu 9:25-28). Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa/Ìdàpọ̀ Onígbàgbọ́ jẹ́ ìrántí ohun tí Jésù ṣe fún wa àti àjọyọ̀ ohun tí a gbà ní àyọrísí ìrúbọ Rẹ̀.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni pàtàkì Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa/Ìdàpọ̀ Onígbàgbọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries