settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́?

Idahun


Kókó ọ̀rọ̀ ti "sí sọ̀rọ̀ l'òdì sí Ẹ̀mí" ni a mu ẹ́nu bà nínú Marku 3:22-30 àti Matteu 12:22-32. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu tán ni. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a gbé tọ Jésù wá, Olúwa sì lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, Òun sì wo ọkùnrin náà sàn kúrò nínú ojú fífọ́ àti yíya òdi rẹ̀. Àwọn tí ọ̀rọ̀ lílé ẹ̀mí èṣù náà jáde ṣ'ojú wọn sí bẹ̀rẹ̀ sì ní wòó Jésù pẹ̀lú ìyanu bóyá Òun ni Mesiah tí wọ̀n ti ńretí nítòótọ́. Ẹgbẹ́ àwọn Farisí kan, ńgbọ́ ọ̀rọ̀ ti Mesiah, lójúkannáà wọ́n gbọ̀n èyíkéyì ìgbàgbọ́ tí o súyọ l'áàrin ogunlọ́gọ̀ náà danù: "Ọkùnrin yìí kò lé ẹ̀mí èṣù jáde, bíkòṣe nípa Beelsebubu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù," ni wọ́n wí (Matteu 12:24).

Jésù kọ oun ti àwọn Farisí sọ pẹ̀lú àwọn àlàyé tí ó ní ìtumọ̀ èrè ìdí fún àìlé ẹ̀mì èṣù jáde pẹ̀lú agbára sátánì (Matteu 12:25-29). Lẹ́yìn náà Òun sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mì Mímọ́: "Nítorí náà ni mó wí fún yín, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ̀-kẹ́ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì li a o dáríji ènìà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, oun li a ki yíò dáríji ènìà. Ẹnikẹ̀ni tí ó bá ńsọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ-ènìà, a o dárí rẹ̀ jìí, ṣugbọ́n ẹnikẹ́ni tí o bá ńsọ̀rọ̀-òdì si Ẹ̀mí Mímọ́, a kì yíò dárí rẹ̀ jìí li ayé yí, li aye tí ḿbọ̀"(ẹsẹ 31-32).

Kókó ọ̀rọ̀ náà ọ̀rọ̀-òdì ni a lè túmọ̀ l'ápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí "aìní-ibọ̀wọ̀ lọ́nà tí ó lòdì." Kókó ọ̀rọ̀ náà ni a lè lò sí ẹ̀ṣẹ̀ bíi bíbú Ọlọ́run tàbì mìmọ̀ọ́mọ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ohun tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ òdì tún jẹ́ pípe àwọn ibi mọ́ Ọlọ́run tàbí kíkọ̀ àwọn ohun rere tí ó yẹ kí a fi fùn un. Irú ọ̀rọ̀-òdì ní pàtó báyìí, ni a ǹpé ní, "ọ̀rọ̀-òdì tako Ẹ̀mí Mímọ́" nínú Matteu 12:31. Àwọn Farisí, lẹ́hìn èyí tí wọn ti rí ẹ̀rí tí kò ṣeé kọ̀ wípé Jésù ńṣe iṣẹ́ ìyanu pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́, jẹ́rìí wípé ẹ̀mi èṣù gbé Olúwa wọ̀ (Matteu 12:24). Ṣe àkíyèsi, ní Marku 3:30 wípé Jésù sọ̀rọ̀ ní pàtó nípa ohun tí àwọn Farisí ṣe láti dẹ́ṣẹ̀ ìsọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́: "Ó sọ èyí nítorípé wọ́n wí pé 'Ó ní ẹ̀mí àìmọ́.'"

Ọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ níí fi ṣe pẹ̀lú fífi ẹ̀sùn kan Jésù Kristi wípé ẹ̀mí èṣù gbée wọ̀ dípò kíkún fún Ẹ̀mí-Mímọ́. A kò lè ṣe ẹ̀dà irúfẹ́ ìsọ̀rọ̀-òdì báyìí lóde òní. Àwọn Farisí wà ní ìgbà tí ó dá yàtọ̀ nínú ìtàn: wọ́n ní àwọn Òfin àti àwọn Wòólì, wọ́n ní Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ńru wọ́n lọ́kàn sókè, wọ́n ní Ọmọ Ọlọ́run tìkalárarẹ̀ tí ó dúró níwájú wọn gan-an àti pẹ̀lú wọ́n fi ojú wọn ri àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ó ṣe. Kò sí ṣáájú rí nínú ìtàn l'áyé (kò sí tún sí láti igba náà mọ́) kí imọ́lẹ̀ láti òkè wá tí ó pọ̀ báyìí tí a jọ̀wọ́ fún ènìyàn; bí ẹnikẹ́ni báyẹ láti dá Jésù mọ̀ fún ẹni tí Ó jẹ́, àwọn Farisí ni. Síbẹ̀ wọ́n yan ìpín tí ó lòdì. Wọ́n mọ̀ọ́mọ́ọ̀ fi iṣẹ́ ti Ẹ̀mí pe ti èṣù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n mọ ọ́títọ́ àti wípé wọ́n ní ẹ̀rí. Jésù kéde mímọ̀ọ́mọ̀ ní ìfọ́jú gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀ṣẹ̀ èyì tí kò ní ìdáríjí. Ọ̀rọ̀ òdì wọn sí Ẹ̀mí Mímọ́ náà ni ó jẹ́ ìkọ̀sílẹ̀ ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti la ipa ọ̀nà tí wọn yóò tọ̀, tí Ọlọ́run yóò si jọ̀wọ́ wọn láti tọ ọ̀nà sí ìparun láìní ìdíwọ́.

Jésù wí fún àwọn àpéjọpọ̀ náà wípé àwọn ọ̀rọ̀-òdì àwọn Farisí lòdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ "a ki yíò dárí rẹ̀ jì li ayé yìí àti li èyí tí mbọ̀" (Matteu 12:32). Ọ̀nà míìrán láti sọ wípé ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò ní ní ìdáríjì mọ́ láí. Nísìsiyí kọ́, ní ayérayé kọ́. Gẹ́gẹ́ bí Marku 3:29 ṣe gbékalẹ̀, "Wọ́n jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ti ayérayé."

Èsì lọ́gán sí ìkọ̀sílẹ̀ ìta gbangba ti Kristi àwọn Farisí (àti ikọ̀sílẹ̀ ti Ọlọ́run sí wọn) ni a rí ni orí tí ó tẹ̀le. Jésù, fún ìgbà àkọ́kọ́,"fi òwe bá wọn sọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkàn"(Matteu 13:3: cf. Marku 4:2). Àyípada ìlànà ìkọ́ni tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn ya àwọn ọmọ-ẹ̀hìn lẹ́nu, tí Jésù ṣe àlàyé àmúlò àwọn òwe Rẹ̀: "Ẹ̀yin li a fifún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn li a kò fifún. . . . Nítorí ní rírí, wọn kò rí; àti ní gbígbọ́, wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ni kò yé wọn" (Matteu 13:11,13). Jésù bẹ̀rẹ̀ sìí ní bo òtítọ́ pẹ̀lú ọ́we àti ọ̀rọ̀ àfiwé gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ̀ tí ó láṣẹ tààrà nínú àwọn aládarí Júù.

Lẹ́kànsii, ìsọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ ni à kò le ṣe àtúnṣe rẹ̀ lódè òní, bí o tìlẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ènìyàn kan ńgbìyànjú. Jésù Kristi kò sí ní ayé—Òun ti jókòó ní apá ọ̀tún Ọlọ́run. Kò sí ẹníkẹ́ni tí ò lè dá ṣe ẹlẹ́rí Jésù tí ó ńṣe iṣẹ́ ìyanu kí ó sì wá fi agbára náà pe ti sátánì dípò ti Ẹ̀mí.

Ẹ̀ṣẹ̀ tì kò ní ìdáríjì l'ónìí ni wíwà ní ipò àìgbágbọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́ Ẹ̀mí ńdá ayé ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí kò ní ìgbàlà lẹbi ẹ̀ṣẹ̀, ìṣòdodo, àti ìdájọ́ (Johannu 16:8). Láti tako ìdánilójù nàà kí á sì mọ̀ọ́mọ̀ọ́ wà ní àìní ìrónúpìwàdà jẹ́ "ìwà ọ̀rọ̀-òdì" sí Ẹ̀mí. Kò sí ìdáríjì, yálà ní ayé yìí tàbí ayé èyí tí ó ńbọ̀ wá, fún ènìyàn tí ó kọ ìdarí T'ẹ̀mí láti gbẹ́kẹ̀lé inú Jésù Kristi tí ó sì wá kú sínú àìgbágbọ́. Ìfẹ́ ti Ọlọ́run hàn gbangba: "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kansọsọ fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má ba ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun." (Johannu 3:16). Ìpín yíyàn náà hàn kedere: "Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹkun, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ Ọmọ náà kì yí ò rí ìyè, nítorí ìbínú Ọlọ́run ḿbẹ lórí ẹni bẹ́ẹ̀" (Johannu 3:36).

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries