settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni èmi ṣe lè di ọmọ Ọlọ̀run?

Idahun


Dídi ọmọ Ọlọ̀run nílò ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. "Sùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àwọn ni ó fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ̀run, àní àwọn náà tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́" (Johannu 1:12).

"Ìwọ́ gbọ́dọ̀ di àtúnbí"
Nígbàtí olórí ẹ̀sìn, Nikodemu bẹ̀ Ẹ́ wò, Jésù kò fún-un ní ìdánilójú ọ̀run ní kíákíá. Dípò bẹ́ẹ̀, Kristi sọ fún-un wípé ó nílò láti di ọmọ Ọlọ̀run, wípé, "lóòtọ́, lóòtọ́ ni mo wí fún ọ, bíkòsepé a tún ènìyàn bí, òun kò le rí ìjọba Ọlọ́run" (Johannu 3:3).

Ìgbà tí ènìyàn bá kọ́kọ́ di àtúnbí, ó jogún àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó gbilẹ̀ láti ibi àìgbọràn ti Adamu nínú Ọgbà Edẹni. Ẹnìkan kò nílò láti kọ́ ọmọdé bí yóò ṣe d'ẹ́ṣẹ̀. Òun ńtẹ̀lé ìwà àìtọ́ ara rẹ̀, tí ńjásí ẹ̀ṣẹ̀ irọ́, olè jíjà, àti ìkórìíra. Dípò jíjẹ́ ọmọ Ọlọ́run, òun jẹ́ ọmọ aláìgbọràn àti ìbínú. (Efesu 2:1-3).

Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbínú, a l'ẹ̀tọ̀ọ́ sí ìyapa kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú ọ̀run-àpáàdì. A dúpẹ́ wípé, Efesu 2:4-5 wípé, "Sùgbọ́n Ọlọ́run, ẹnití íṣe ọlọ́rọ̀ ní àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, nígbàtí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékojá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi—ore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là." Báwo ni a ṣe sọ wá di ààyè pẹ̀lú Krístì/àtúnbí/di ọmọ Ọlọ́run? A gbọ́dọ̀ gba Jésù nípa ìgbàgbọ́!

Gba Jésù
"Sí gbogbo àwọn tí ó gbà á—àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú orúkọ Rẹ̀—Ó ti fi ẹ̀tọ̀ fún láti di ọmọ Ọlọ́run" (John 1:12, NET). Ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ṣe àlàyé kedere bí a ti le jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ gba Jésù nípa gígbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Kínni a gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nípa Jésù?

Àkọ́kọ́, ọmọ Ọlọ́run mọ̀ rí wípé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run ayérayé ẹnití ó di ènìyàn. A bíi nípasẹ̀ wúndía nípa agbára Èmí Mímọ́, Jésù kò jogún àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ Adamu. Nítorínàá, Jésù ni Adamu kejì (1 Kọrinti 15:22). Nígbàtí àìgbọràn Adamu mú egun ẹ̀ṣẹ̀ wa sínú ayé, ìgbọràn Jésù tí ó péye ńmú ìbùkún wa. Ìdáhùn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti ronúpìwàdà (yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀) kí á sì wá ìdáríjìn nínú Kristi.

Èkejì, ọmọ Ọlọ̀run ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà. Ètò Ọlọ́run ni láti fi Ọmọ pípé Rẹ̀ rúbọ lórí igi àgbélèbú láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa: ikú. Ikú Jésù dá àwọn tí ó gbà Á sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjìyà àti agbára ẹ̀ṣẹ̀. Àjínde Rẹ̀ dá wa l'áre (Romu 4:25).

Lákòótán, ọmọ Ọlọ́run ńtẹ̀lé Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa. Lẹ́yìn tí Òun jí Kristi dìde gẹ́gẹ́ bíi Aṣẹ́gun lórí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, Ọlọ́run fún-Un ní gbogbo àṣẹ (Efesu 1:20-23). Jésù ńdaríji gbogbo àwọn tí ó gbà Á; Òun yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n kọ̀ọ́ sílẹ̀ (Iṣe àwọn Apọsteli 10:42). Nípa ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a ti di àtúnbí sí ayé titun gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run. Àwọn tí ó gba Jésù nìkan—tí wọn kò mọ̀ nípa rẹ̀ lasan ṣùgbọ́n tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé E fún ìgbàlà, bíbọ̀wọ̀ fún-Un gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá, tí a sì ńfẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìṣura ńlá—ló di ọmọ Olọ́run.

Di ọmọ Ọlọ́run
Gẹ́gẹ́ bí a kò ti ní ipa nínú ìbí wa, a kò lè mú kí á bí ara wa sínú ìdílé Ọlọ́run nípa ṣíṣe rere tàbí kí á ma a ṣe ìgbàgbọ́ ara wa. Ọlọ́run ni ẹnití Ó "fún ni ní ẹ̀tọ̀" láti di ọmọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi ìṣe ògo Rẹ̀. "Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Bàbá fi fẹ́ wa, tí à fí ńpè wá ní ọmọ Ọlọ́run!" (1 Johannu 3:1). Nípasẹ̀ èyí, ọmọ Ọlọ́run kò ní nǹkankan láti sògo; ìsògo rẹ̀ wà nínú Ọlọ́run nìkan (Efesu 2:8-9).

Ọmọ ńdàgbà láti jọ àwọn òbí rẹ̀. Bákannáà, Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ dàbi Jésù Kristi síi àti síwájú sí. Bí o tìlẹ jẹ́ wípé ní ọ̀run níkan ni a ó ti di pípé, ọmọ Ọlọ́run kò ní máa hùwà àìdẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀. "Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ki o tàn yín. Ẹnití ó bá ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí Òun ti íṣe Olódodo. Ẹnití o bá ńdẹ́ṣẹ̀ ti èṣù ni, nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù tí ńdẹ́ṣẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó le pa iṣẹ́ èsù run. Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kìí dẹ́ṣẹ̀; nítorítí irú rẹ̀ ń gbe inú Rẹ̀: kò sí le dẹ́ṣẹ̀ nítorípé a ti ti ipa Ọlọ́run bíi. Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èsù: Ẹnikẹ́ni tí kò bá ń ṣe òdodo kì íṣe ti Ọlọ́run, àti ẹnití kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀" (1 Johannu 3:7-10).

Má ṣe àṣìṣe kankan—a kò le kọ ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀ nípa dídẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe déédé nínú, tí ó sì ńgbádùn, ẹ̀ṣẹ̀ láì ṣe ti Kristi àti wípé ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fihàn wípé kò tíì di àtúnbí. Jésù sọ fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, "Ti èsù bàbá ni ẹ̀yin íṣe, ìfẹ́kùfẹ́ bàbá yín ni ẹ sì ńfẹ́ se" (Johannu 8:44). Ọmọ Ọlọ́run, ní ọ̀nà míìrán, kò fẹ́ láti d'ẹ́ṣẹ̀ mọ́ sùgbọ́n ó fẹ́ mọ̀, fẹ́, àti fi ògo fún Bàbá rẹ̀.

Àwọn èrè jíjẹ́ ọmọ Ọlọ́run kò níye. Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run, a jẹ́ ara ìdílé Rẹ̀ (ìjọ), tí Ó ṣe ìlérí ilé l'ọ́run, tí ó sì fun ní ẹ̀tọ́ láti tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà (Efesu 2:19; 1 Peteru 1:3-6; Romu 8:15). Ìdáhùn sí ìpè Ọlọ́run láti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ àti gbàgbọ́ nínú Kristi. Di ọmọ Ọlọ́run l'ónìí!

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni èmi ṣe lè di ọmọ Ọlọ̀run?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries