settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ọjọ́ orí ayé? Báwo ni ayé ṣe dàgbà tó?

Idahun


Bíbélì ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn orí ọ̀rọ̀ kan. Fún àpẹẹrẹ, aṣe àlàyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ lórí ojúṣe wa nípa ohun rere sí Ọlọ́run àti ọ̀nà ìgbàlà. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kò pèsè àlàyè tí ó tó bẹ́ẹ̀ fún wa lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ míìrán. Bí a bá farabalẹ̀ ka Ìwé Mímọ́, a ó ri wípé bí orí ọ̀rọ̀ bá ṣe le koko tó, bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì yóò ṣe ṣe àlàyè tàrà nípa rẹ̀. Ní ọ̀rọ̀ míìrán, " àwọn nǹkan tí ó ṣe kókó ni ó jẹ́ kedere." Ọ̀kan lára àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tí kò sí àlàyé púpọ̀ lórí wọn nínú Ìwé Mímọ́ ni ọjọ́ orí ayé.

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni à fi ńgbìyànjú láti fi lè mọ ọjọ́ orí ayé. Gbogbo ọ̀nà náà gbáralé àwon èròǹgbà kan tí ó lè tọ́ tàbí kí ó má tọ́. Gbogbo wọn wà láàrin títúmọ̀ Bíbélì lóréfèé tàbi títúmọ̀ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì lóréfèé.

Ọ̀nà kan láti fi lè mọ ọjọ́ orí ayé gbà wípé ọjọ́ mẹ́fà ìṣẹ̀dá tí ó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì òrí kínní jẹ́ àwọn àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) gẹ́lẹ́, àti wípé kò sí àlàfo nínú sísẹ̀ntẹ̀lé tàbí ìtàn ìrandíran tí ó wà nínú ìwe Jẹ́nẹ́sísì. Wọ́n ṣe ìṣirò àwọn ọdún tí ó wà nínú ìran ti inú Jẹ́nẹ́sísì papọ̀ láti lè mọ ìgbà tí ó lè jẹ́ láti ìgbà ìṣẹ̀dá tí ó fi di àwọn àkókò àkọsílẹ̀ kan nínú Májẹ̀mú Láíláí. Nípa lílo ọ̀nà yìí, wọ́n dé ìkoríta tí wọ́n pinnu pé ọjọ́ orí ayé jẹ́ bíi ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà (6,000). Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ wípé kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ kedere ohun tí ọjọ́ orí ayé jẹ́—èyí jẹ́ nọnba tí a ṣirò.

Ọ̀nà míìrán láti mọ ọjọ́ orí ayé ni láti lo àwọn ohun-èló bíi mímọ ọjọ́ orí ti rediomẹ́tíríkìì (kábọ̀nù), onílọpo ti jiolójìkì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn onímọ̀ ìjìǹlẹ̀ sáyẹ́ńsì gbìyànjú láti mọ ọjọ́ orí ayé nípa fífi oríṣiríṣi ọ̀nà wé ara wọn, àti wí wòó bóyá wọ́n bára wọn mu. Èyí ni ọ̀nà tí wọ́n gbà pinnu wípé ọjọ́ orí ayé jẹ́ bíi bílíọ́nù ọdún mẹ́rin (4) tàbí márùn-ún (5). Ó ṣe pàtàkì láti ríi wípé kò sí ọ̀nà kankan tàrà láti wọn ọjọ́ orí ayé—èyí jẹ́ nọnba tí a ṣirò.

Ọ̀nà méjèèjì tí a fi ńmọ ọjọ́ orí ayé ṣeé ṣe láti ní kùdìẹ̀ kùdìẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kan wà tí wọn kò gbà wípé ẹsẹ Bíbélì nílò wípé ọjọ́ ìṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) gẹ́lẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni, àwọn ìdí wà láti gbàgbọ́ wípé àlàfo tí a mọ̀ọ́mọ̀ fi sílẹ̀ wà láàrin ìtàn ìrandíran tí ó wà nínú ìwe Jẹ́nẹ́sísì, ní wípé wọ́n dárúkọ àwọn ènìyàn kan nìkan nínú ìran náà. Òṣùwọ̀n tí kò ní ojúṣàájú nínú, nípa ọjọ́ orí ayé kò jọ wípé ó fara mọ́ wípé ó kéré tó ọdún ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6), àti wípé kíkọ irú ẹ̀rí báyìí nílò àbá wípé Ọlọ́run jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ abala ayé "rí" bíi wípé wọ́n ti gbó, fún àwọn ìdí kan. Dípò ẹ̀rí fún àtakò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni tí wọ́n ní àfojúsùn ògbólóògbó ayé gbà wípé Bíbélì ṣeé tẹ̀lé, ṣùgbọ́n wọ́n dá yàtọ̀ nípa ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ̀ kan díẹ̀ ni.

Ní ọ̀nà míìrán mímọ ọjọ́ orí ti rediomẹ́tíríkìì wúlò tàbí gúnrégé dé ìkòritá kan ni, tí ó kéré sí òṣùwọ̀n tí wọ́n ńlò pẹ̀lú mímọ ọjọ́ orí ayé. Òṣùwọ̀n àkókò ti Jìọ́lọ́jì, àkọsílẹ̀ nǹkan tí ó ṣẹ́kù lẹ́hìn ikú, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ gbẹ́kẹ̀lé àfojúsùn àtí àṣìṣe àwòkọ́ṣe púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ó rí fún àfojúsùn lórí àgbáyé tí ó tóbi, a lè rí ipa kíún nínú ohun gbogbo tí ó wà láàyè, àti wípé ọ̀pọ̀ ohun tí a "mọ̀" jẹ́ àlàyé tí a kò tíì fìdí rẹ kalẹ̀. Ní kúkúrú, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà láti gbàgbọ́ wípé ìṣirò tí ó gbajúgbajà fún ọjọ́ orí ayé kò yẹ pẹ̀lú. Gbígbẹ̀kẹ̀lé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì láti dáhùn ìbéèrè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì dára, ṣùgbọ̀n a kò gbọdọ̀ ṣe bí ẹni wípé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì kò lè jáni kulẹ̀.

Ní ìgbẹ̀hìn, a kò lè fi ìdí sísẹ̀ntẹ̀lé ọjọ́ orí ayé múlẹ̀. Ó ṣeni láàánú wípé, àwọn kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì gbà wípé tí àwọn ni ìtúmọ̀ tí ó ṣeé ṣẹ—ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tàbí ìmọ̀-ìjìǹlẹ̀ sáyẹ́ńsì. Ní ti òtítọ́, kò sí àtakò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tí a kò lé bá làjà láàrin ẹ̀sìn Kristiẹni àti ayé ògbólògbó. Bẹ̀ẹ̀ sì ni, kò sí àtakò ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì tòótọ́ nínú ayé tí ó jẹ́ ọ̀dọ́. Àwọn tí ó ṣe àtakò ńdá ìyapa sílẹ̀ nígbà tí kò sí. Ìpo yóòwù tí ènìyàn lè gbà, ohun tí ó ṣe kókó ni bóyá irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ gbà wípé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ àti wípé ó ní àṣẹ.

Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Got Questions faramọ́ àfojúsùn ayé tí ó jẹ́ ọ̀dọ́. A gbàgbọ́ wípé ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1-2 rí bí a ti kọọ́ gẹ́lẹ́, àti wípé ẹ̀kọ́ ìṣẹ̀dá nípa ayé tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ jẹ́ ohun tí kíka àwọn orí yìí túmọ̀ sí. Nígbà kannáà, a kò rò wípé ẹ̀kọ́ lóri ayé ògbólògbó jẹ́ ẹ̀kọ́ òdì. A kò níló láti tako ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtí arábìnrin wa nínú Kristi tí kò gbàgbọ́ pẹ̀lú wa nípa ọjọ́ orí ayé. A gbàgbọ́ wípé ènìyàn lè rọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ ìṣẹ̀dá nípa ayé ògbólògbó kí ó sì gbọ́ràn sí àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ṣe kókó nípá ìgbàgbọ́ Kristiẹni.

Àwọn orí ọ̀rọ̀ bíi ọjọ́ orí ayé ni ìdí tí Pọ́ọ̀lù ṣe rọ àwọn onígbàgbọ́ látí maṣe jà lórí àwọn nǹkan tí a kò ṣàlàyé l'ẹ́kúnrẹ̀rẹ̀ nínú Bíbélì (Romu 14:1-10; Titu 3:9). Ọjọ́ orí ayé kò hàn "kedere" nínú Ìwé Mímọ́. Kò sì tún ṣe "kókó" nítorí àfojúsùn ẹnìkan nípa ọjọ́ orí ayé kò ní àyọrísí tí ó ṣe kókó nípa ìhà tí ènìyàn bá kọ sí ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàlà, ìhùwà, ọ̀run, tàbí ọrun-àpáàdì. A lè mọ ohun púpọ̀ nípa ẹni tí ó ṣẹ̀dá, ìdí tí Òun fi ṣẹ̀dá, àti bí ó ṣe yẹ kí á bá Á ṣe pọ̀, ṣùgbọ́n Bíbélì kò sọ fún wa ní ọ̀nà tí ó hàn kedere Ìgbà tí Òun ṣẹ̀dá ní pàtó.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ọjọ́ orí ayé? Báwo ni ayé ṣe dàgbà tó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries