settings icon
share icon
Ibeere

Ọjọ́ wo ni Ọjọ́ Ìsinmi, Ọjọ́ Àbámẹ́ta tàbí Ọjọ́ Àìkú?" Sé àwọn Kristiẹni ní láti kíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi?

Idahun


À máa ńsábà gbà wípé "Ọlọ́run dá Ọjọ́ Ìsinmi nínú Ídẹ́nì" nítorí àsopọ̀ láàrin Ọjọ́ Ìsinmi àti ìṣẹ̀dá nínú Ẹksodu 20:11. Bíotìlẹ́jẹ́ wípé Ìsinmi Ọlọ́run l'ọ́jọ́ keje (Jẹnẹsisi 2:3) ṣe àwòjíji fún òfin Ọjọ́ Ìsinmi, kò sí àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣáájú ìgbà tí àwọn ọmọ Israeli kúrò ní ilẹ̀ Egipiti. Kò sí ibìkan nínú Ìwé-Mímọ́ tí ó sọ wípé pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́ ti wáyé láti ìgbà Adamu sí Mose.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó hàn kedere pé àkíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ààmìn pàtàkì láàrin Ọlọ́run àti Isrẹli: "Nítorínà ni àwọn ọmọ Isrẹli yóò ṣe má a pa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́, láti má a kíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi láti ìrandíran wọn, fún májẹ̀mú títíláí. Ààmìn ni íṣe láàrin Ẹ̀mi àti láàrin àwọn ọmọ Israẹli títíláí: nítorí ní ijọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, ní ijọ́ kèje ó sì sinmi, ó sì se ìtura" (Ẹksodu 31:16-17).

Nínú Deutarọnọmi 5, Mose ṣe àtúnsọ àwọn Òfin Mẹ́wàá sí ìran Isrẹli míìrán. Ní ibí yìí, lẹ́yìn àṣẹ àkíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi nínú ẹsẹ̀ 12-14, Mose sọ ìdí tí a fi fi Ọjọ́ Ìsinmi fún orílẹ̀-èdè Isrẹli: "Sì ráńtí pé ìwọ ti ṣe ìráńsẹ́ ní ilẹ̀ Egipiti, àti pé Olúwa Ọlọ́run rẹ mú ọ láti ibẹ̀ jáde wá nípa ọwọ́ agbára, àti nípa nína apá. Nítorínà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe pàṣẹ fún ọ láti pa ọjọ́-ìsinmi mọ́" (Deutarọnọmi 5:15).

Ète Ọlọ́run láti fún Isrẹli ní Ọjọ́ Ìsinmi kìí ṣe wípé wọn ó ráńtí ìṣẹ̀dá, ṣùgbọ́n pé wọn ó ráńtí oko-ẹrú ilẹ̀ Egipiti àti ìtúsílẹ̀ Olúwa. Kíyèsi àwọn àmúyẹ pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́: Ẹ̀níyán tí ó wà lábẹ́ òfin Ọjọ́ Ìsinmi kò lè fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ l'ọ́jọ́ Ìsinmi (Ẹksodu 16:29), kò le dá iná (Ẹksodu 35:3), kò sì le jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣiṣẹ́ (Deutarọnọmi 5:14). Ẹni tí ó bá rú òfin Ọjọ́ Ìsinmi ni a ó pa (Ẹksodu 31:15; Numeri 15:32-35).

Àyẹ̀wò àwọn ẹsẹ̀ Májẹ̀mú Titun fi kókó ọ̀rọ̀ mẹ́rin hàn: 1) Ìgbákùùgbà tí Jésù bá yọ ní ara àjíǹde Rẹ̀ àti ní ọjọ́ tí Òun sọ, ó jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀ (Matteu 28:1, 9, 10; Marku 16:9; Luku 24:1, 13, 15; Johannu 20:19, 26). 2) Ìgbà kan soso tí a mẹ́nuba Ọjọ́ Ìsinmi láti Ìṣe àwọn Àpọ́stélì títí dé Ífihàn, ìgbà náà ni ìtànkálẹ̀ ìhìnrere, àti wípé ìṣètò rẹ̀ má ńsabà jẹ́ sínágọ́gù (Iṣe àwọn Apọsteli ori 13 -18). Pọ́ọ̀lù kọọ́, "Fún àwọn Ju mo dàbi Ju, kí èmi kí ó le jèrè àwọn Ju" (Kọrinti Kinni 9:20). Pọ́ọ̀lù kò lọ sí sínágọ́gù láti jọ́sìn pẹ̀lú àti láti kọ àwọn ẹni mímọ́, ṣùgbọ́n láti dá ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi kí ó sì gba àwọn tó sọnù là. 3) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti wípé, "Láti ìsisìnyí lọ èmi ó tọ àwon kèfèrí lọ" (Iṣe àwọn Apọsteli 18:6), a kò sì mẹ́nu ba Ọjọ́ Ìsinmi mọ́. Àti 4) dípò àbá láti dìrọ̀mọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, ìráńtí Májẹ̀mú Titun túmọ̀ sí ìdàkejì (àyààfi èyí tí ó pẹ̀lú kókó 3, l'ókè, tí ó wà nínú Kolosse 2:16).

Wíwo kókó 4 lókè dáradára ó fihàn wípé kìí ṣe ọ̀rànọyàn fún àwọn ọmọ Isreli láti pa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́, èyí yóò sì fihàn wípé èrò ọjọ́ Àìkú " Ọjọ́ Ìsinmi Kristiẹni" kò bà Ìwé Mímọ́ mu. Gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò lókè, ìgbàkan wà tí a mẹ́nubà Ọjọ́ Ìsinmi lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí dojúkọ àwọn Kèfèrí, "Nítorínà máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa ṣe ìdájọ́ yín níti jíjẹ, tàbí níti mímu, tàbí níti ọjọ́ àsè, tàbí osù titun, tàbí Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn wọ̀nyìí ni òjìji ohun tí ńbọ̀; ṣùgbọ́n tí Kristi ni ara." (Kolosse 2:16-17). Òpin dé bá Ọjọ́ Ìsinmi ti Júù lórí igi àgbélèbú níbití Jésù ti "pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, pẹ̀lú àwọn ìlàna rẹ̀" (Kolose 2:14).

Èrò yìí ni a túnsọ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ nínú Májẹ̀mú Titun: "Ẹlòmíì ńbuyìn fún ọjọ́ kan ju òmíràn lọ: ẹlòmíì ńbuyìn fún ọjọ́ gbogbo bákanáà. Kí olúkùlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. Ẹnití ó bá ńkíyèsí ọjọ́, ó ńkíyèsí i fún Olúwa" (Romu 14:5-6a). "Ṣùgbọ́n nísisìnyí, nígbàtí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tán, tàbí kí á sà kúkú wípé, ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti ri tí ẹ fi tún yípadà sí aláìlera àti àlàgbé ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀dá? Ṣé ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá sìnrú? Ẹ̀yin ńkìyèsí ọjọ́, àti osù, àti àkókò, àti ọdún" (Galatia 4:9-10).

Ṣùgbọ́n àwọn kan gbà wípé àṣẹ láti ọ̀dọ Constantine ni A.D. 321 ló "yí" Ọjọ́ Ìsinmi kúrò ní "Ọjọ́ Àbámẹ̀ta sí Ọjọ́ Àìkú. Ọjọ́ wo ni àwọn ìjọ àkọ́kọ̀ ńpàdé fún ìjọsìn? Ìwé Mímọ́ kò dárúkọ́ àpéjọpọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi (Ọjọ́ Àbámẹ̀ta) tí àwọn onígbàgbọ́ fún ìdàpọ̀ tàbí ìjọ́sìn. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀sẹ̀ tí ó mẹ́nuba ọjọ́ àkọ́kọ̀ nínú ọ̀sẹ̀ wà kedere. Fún àpẹẹrẹ, Iṣe àwọn Apọsteli 20:7 sọ wípé "Àti ní ọjọ́ kìnní ọ̀sẹ̀ a péjọ láti bu àkàrà." Ní Kọrinti kínní 16:2 Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ Kọrinti níyànjú "Ní ọjọ́ ìkínní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣura lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní apákan." Nígbàtí Pọ́ọ̀lù ti yan ọ̀rẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí "Ìsìn" nínú Kọrinti kejì 9:12, àkójọpọ̀ yìí gbọdọ̀ ti sopọ̀ mọ́ ètò ìsìn Ọjọ́ Àìku àwọn àpèjọ Kristiẹni. Nínú ìtàn Ọjọ́ Àìku, kìí ṣe Ọjọ́ Àbámẹ́ta, jẹ́ ọjọ́ ìpàdé fún àwọn onígbàgbọ́ nínú ìjọ, a sì ti ńṣètò yìí láti ọgọ́ọ̀rún ọdún àkọ́kọ́ sẹ́yìn.

Isrẹli ni a fún ní Ọjọ́ Ìsinmi, kìí ṣe ìjọ. Ọjọ́ Ìsinmi sì ni Ọjọ Àbámẹ́ta, kìí ṣe Ọjọ́ Àìku, kò sì tíì yípadà. Ṣùgbọ́n Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ara Òfin Májẹ̀mú Láíláí, àwọn onígbàgbọ́ sì bọ́ lọ́wọ́ ìdè òfin (Galatia 4:1-26; Romu 6:14). A kò bèèrè kí Kristiẹni pa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́ "bóyá Ọjọ́ Àbámẹ́ta tàbí Ọjọ́ Àìku. Ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, Ọjọ́ Àìku, ọjọ́ Olúwa (Ifihan 1:10) ńṣe àjọyọ̀ Ìṣẹ̀dá Titun, pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí olórí àjíǹde wa. A kò fi ipá mú wa láti tẹ̀lé ìsinmi Ọjọ́ Ìsinmi ti Mose, a sì ti di òmìnira báyìí láti tẹ̀lé Iṣẹ́ Kristi tí ó jíǹde. Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù sọ wípé Kristiẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pinnu láti kíyèsí Ìsinmi , "Ẹlòmíì ńbuyìn fún ọjọ́ kan ju òmíràn lọ: ẹlòmíì ńbuyìn fún ọjọ́ gbogbo bákanáà. Kí olúkùlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀" (Romu 14:5) A ní láti sin Ọlọ́run l'ójojúmọ́, kìí ṣe ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta tàbí Ọjọ́ Àìkú nìkan.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ọjọ́ wo ni Ọjọ́ Ìsinmi, Ọjọ́ Àbámẹ́ta tàbí Ọjọ́ Àìkú?" Sé àwọn Kristiẹni ní láti kíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries