settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni èmi ṣe lè dá ohùn ti Ọlọ́run mọ̀?

Idahun


Ìbéèrè yìí ni àìmọye ènìyàn láti ìgbà pípẹ́ ti béèrè. Sámúẹ̀lì gbọ́ ohùn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò dáamọ̀ títí di ìgbà tì Élì fún ní ìtọ́ni (1 Samuẹli 3:1-10). Gídíónì ní ìfihàn olójukojú láti ọ̀dọ Ọlọ́run, síbẹ̀ òun sì tún ṣiyèméjì ohun tí o ti gbọ́ títí dé ojú bíbèrè fún àmì kan, láì kìí ṣe ẹ̀kanṣoṣo, ṣùgbọ́n ìgbá mẹ́ta (Awọn Onidajọ 6:17–22,36–40). Nígbàtí a bá ńtẹ́tí sílẹ̀ fún ohùn ti Ọlọ́run, báwo ni a ṣè lè mọ̀ wípé Òun ní ó ńsọ̀rọ̀? Ní àkọ́kọ́ ná, àwa ní nǹkan tí Gídíónì àti Sámúẹ́lì kò ní. A ní Bíbélì pípé, Ọ̀rọ̀ ti Ọlọ́run tí ó ní ìmísí, láti kà, wádìí, àti ṣàṣàrò lé lórí. "Gbogbo Ìwé-Mímọ́ tí ó ní ìmísí Ọlọ́run ni ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbáni-wí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo: kí ènìyàn Ọlọ́run kí ó le pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo" (2 Timoteu 3:16). Nígbàtí a bá ní ìbéèrè nípa kókó ọ̀rọ̀ kan tàbí ìpinnu kan nínú ayé wa, àwa gbọ́dọ̀ wo nkàn tí bíbélì sọ nípa rẹ̀. Ọlọ́run kò ní ṣì wa darí lòdí sí ohun tí Òun tí kọ́ wa nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (Titu 1:2).

Láti gbọ́ ohùn ti Ọlọ́run àwa gbọ̀dọ̀ jẹ́ ti Ọlọ́run. Jésù wípé, "Àwọn aguntan mi ngbọ́ ohùn mi, emi si mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mi lẹ́hin" (Johannu 10:27). Àwọn tí ó ńgbọ́ ohùn ti Ọlọ́run jẹ́ ti Rẹ̀ – àwọn tí o ti di ẹni ìgbàlà nípa ore-ọ̀fẹ́ sí ìgbàgbọ́ nínú Jésù Olúwa. Àwọn wọ̀nyìí jẹ́ àgùntàn tí ó ńgbọ́ ti ó sì dá ohùn Rẹ̀ mọ̀, nítorí wípé wọ́n mọ Òun gẹ́gẹ́ bì Olùṣọ́-àgùntàn wọn. Bí àwa bá máa dá ohùn ti Ọlọ́run mọ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ti Rẹ̀.

Àwa ńgbọ́ ohùn Rẹ̀ nígbàtí a ba lo àkókò láti kẹ́ẹ̀kọ́ Bíbélì àti ṣíṣàsàrò ní ìdàkẹ́jẹ́ lórí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Bí iye àkókò tí a ńlò nì tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe rọrùn tó láti dá ohùn Rẹ̀ àti ìdarí Rẹ̀ nínú ayé wa mọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìfowopamọ́ kan ni a fún ní ìdanílẹ̀kọ́ láti dá àwọn ayédèrú mọ̀ nípa kíkẹ́ẹ̀kọ́ nípa owó tí ó jẹ́ ojúlówó pẹ́kípẹ́kì kí o lè rọrùn láti dá òtúbántẹ́ mọ̀. Àwa gbọ́dọ̀ súnmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ ti ó fi jẹ́ wípé nígbàtí ẹnìkan bá ńsọ irọ́ fún wa, yóò hàn kedere sí wa wípé kìí ṣe ti Ọlọ́run.

Nígbàtí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ketekete fùn àwọn ènìyàn lóde òní, Òun a kọ́kọ́ máa sọ̀rọ̀ nípasẹ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí a ti kọsílẹ̀ . Nígbà míìrán ìdarí ti Ọlọ́run lè wá nípasẹ Ẹ̀mí Mímọ́, nípasẹ àwọn ẹ̀rí ọkàn wa, nípasẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, àti nípasẹ àwọn ìgbani níyànjú àwọn ẹlòmíràn. Nípa ṣiṣe àfiwé ohun tì a gbọ̀ sì òtítọ́ tì Ìwé Mímọ́, a lè kọ́ láti dá ohùn ti Ọlọ́run mọ̀.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni èmi ṣe lè dá ohùn ti Ọlọ́run mọ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries