settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àwọn Òfin Mẹ́wàá?

Idahun


Àwọn Òfin Mẹ́wàá jẹ́ àwọn òfin Mẹ́wàá níínú Bíbélì tí Ọlọ́run fi fún orílẹ̀-èdè Isrẹli ní kété lẹ́hìn ìrìn-àjò láti Íjíbítì. Àwọn Òfin Mẹ́wàá jẹ́ pàtàkì ìsọníṣókí òfin ẹ̀gbẹ̀talénímẹ́tàlá (613) tí ó ńbẹ nínú Òfin ti Májẹ̀mú Láìláí. Àwọn òfin mẹ́rin àkọ́kọ́ ńkojú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn òfin mẹ́fà tí ó kẹ́hìn ńkojú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ara wa . Àwọn Òfin Mẹ́wàá ní a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì ní Ẹksodu 20:1-17 àti Deutarọnọmi 5: 6-21 báyìí sì ni bí o ṣe lọ:

1) "Ìwọ kò gbọdọ ní Ọlọrun míìrán pẹ̀lú mi." Àṣẹ yìí lòdì sí jíjọsìn sí èyíkéyì ọlọrún míìrán dípò Ọlọrun òtítọ kan ṣoṣo. Gbogbo ọlọrun míìrán jẹ àwọn ọlọrun èké.

2) "Ìwọ kò gbọdọ yá ère fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ l'ókè ọrun tàbí ti ohun kan tí n bẹ ní ìsàlẹ ilẹ tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ ilẹ. Ìwọ kò gbọdọ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹnìi ìwọ kò gbọdọ sìn wọn nítorí Èmi ni, OLÚWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mí tí ń bẹ ẹṣẹ àwọn Baba wò l'ára àwọn ọmọ láti ìran kẹta dé ẹkẹrin àwọn tí ó kórìra mi, èmí a sì máa fi ànú han fún ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ mi, tí wọn sì ń pa òfin mi mọ. Òfin yìí lòdì sí ṣíṣe òrìṣà kan, àpẹẹrẹ tí Ọlọrun tí a lè fi ojú rí. Kò sí àwòrán tí a lè ṣẹdá tí ó lè ṣe ẹkúnrẹrẹ bí Ọlọrun ṣe jẹ́. Láti ṣẹ̀dá orìṣà kan tí ó ńṣojú Ọlọrun ni láti jọsìn ọlọ́run èké.

3) "Ìwọ kò gbọdọ pe orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ lásán, nítorí tí OLÚWA kìí yòó mú àwọn tí ó pe orúkọ rẹ lásán ní aláílẹṣẹ ní ọrùn." Èyí jẹ òfin tí ó lòdì sí lílo orúkọ Olúwa lásán. A kò gbọ́dọ̀ ṣe orúkọ Olúwa ní yẹ́pẹrẹ. A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Ọlọ̀run nípa dídárúkọ Rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà ìbọ̀wọ̀ àti ìtẹríba.

4) "Rántí ọjọ́ Ìsinmi láti yàá sí mímọ́. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ ó ṣiṣẹ́, tí ìwọ ó ṣiṣẹ́ rẹ gbogbo, ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje ni ọjọ́ ìsinmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kíṣẹ́ kan, ìwọ àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, àti ohun ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tí n bẹ nínú ibodè rẹ, Nítorí ọjọ́ mẹ́fà ni OLÚWA dá ọ̀run òun ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ kéje, Nítorínà ní OLÚWA ṣe bùsí ọjọ́ kéje, ó sì yà á sí mimọ́." Èyí jẹ́ òfin látí yà sọ́tọ̀ Sábatì (Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ tí ó kẹ́hìn nínú ọ̀sẹ̀) gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi tí a fi jìn fún Olúwa.

5) "Bọ̀wọ̀ fún Baba òn ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ." Èyí jẹ́ òfin láti máa ṣe ìtọ́jú òbí ẹni pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ àti ìtẹ́ríba.

6) "Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn." Èyí jẹ́ òfin lòdì sí mímọ̀ tẹ́lẹ̀ láti pà ènìyàn míìrán.

7) "Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà." Èyí jẹ́ àṣẹ lòdì sí ní ní àwọn ìbáṣepọ̀ ti ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí alábaṣepọ̀ t'ẹni.

8) "Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè." Èyí jẹ́ òfin lòdì sí mímú ohunkóhun tí kìí ṣe ti ara ẹni, láì gbà ìyọnda lọ́wọ́ ẹni tí ó ní.

9) "Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ." Èyí jẹ́ òfin kan tí ó tàbùkù sí jíjẹ́wọ́ èké sí ẹlòmíràn. Ó jẹ́ òfin pàtakì lòdì sí irọ́ pípa.

10) "Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ilé aládùúgbò rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò aya aládùúgbò rẹ, tàbí ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ-ọdọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọmààlúù tàbí ìbakasiẹ́ rẹ̀, tàbí ohunkóhun tí í ṣe ti aládùúgbọ́ rẹ." Èyí jẹ́ òfin tí ó lòdì sí fífẹ́ ohunkóhun tí kìí ṣe ti ẹni. Ṣíṣe ojúkòkòrò lè yọrísí rírú ọ̀kan nínú àwọn òfin tí a kà sókè: ìpànìyàn, panṣágà àti olè jíjà. Bí ó bá burú láti fẹ́ ohun kàn, ó burú láti ṣe ohun kan náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa ńṣe àṣìṣe nípa wíwo àwọn Òfin Mẹ́wàá náà gẹ́gẹ́ bíi àwọn àkójọpọ̀ àṣẹ wípé, bí a bá tẹ̀lée, yóò fún wa nì ìdánílojú àbáwọlé sí ọ̀run lẹ́hìn ikú. Ní ìdàkejì, èrèdí ti àwọn Òfin Mẹ́wàá ni láti kàn ní ipá fún àwọn ènìyàn láti ṣe àwárí wípé wọn kò lè ṣe ìgbọràn sí Òfin ní pípé (Romu 7:7-11), àti síwájú nílò àánú Ọlọ́run àti ore-ọ̀fẹ. Láìkàsìí ìjẹ́wọ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ ní Matteu 19:16, kò sí ẹni tí ó lè ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn Òfin Mẹ́wàá náà (Oniwasu 7:20). Àwọn Òfin Mẹ́wàá ṣe àpejúwe wípé gbogbo wa ni o ti ṣẹ̀ (Romu 3:23) tí a si nílò àánù Ọlọ́run àti ore-ọ̀fẹ́, tí ó wà nìkanṣoṣo nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni àwọn Òfin Mẹ́wàá?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries