settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé Jésù wà ní tòótọ́? Ṣe èyíkéyi ìtàn tí ó jẹ́rìsí wíwà Jésù Kristi wà?

Idahun


Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nígbàtí a ba bèrè ìbéèrè yìí, ẹni tí ó ńbèrè yóò yán ìbéèrè rẹ̀ pẹ̀lú "yàtọ̀ sí ti inú Bíbélì." Àwa kò gba èrò wípé a kò lè gba Bíbélì bíi orísun ẹ̀rí fún wíwà Jésù gbọ́. Májẹ̀mú Titun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́kàsi Jésù Kristi nínú. Àwọn kan wà tí wọn sọ wípé àkókò ti a kọ Àwọn ìwé ìhìnrere ni ìgba ọgọ́run ọdún kejì A. D., èyí tí o ju ọgọ́run ọdún lẹ́yìn ikú Jésù lọ. Bí èyí bá ti lẹ̀ jẹ́ òtítọ́ (èyí tí àwá takò gidi gan), ní ti àwọn ẹ̀rí ti àtijọ́, àwọn àkọsílẹ̀ ti kò tó igba (200) ọdún lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni a kà sí àwọn ẹ̀rí tí ó ṣée gbáralé. Síwájú síi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ (Kristiéni àti Àwọn tí kìí ṣe kristiẹni) yóò gbà wípé Àwọn lẹ́tà Pọọlu (ó kéré jù lára wọn) ni a kọ nípasẹ̀ Pọọlu ní bíi ìlàjì ọgọ́rùún ọdún A. D., èyí tí o jẹ́ bíi ogójì ọdún lẹ́yìn ikú Jésù. Nípa ti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ẹ̀rí nípa ìwé láéláé, ẹ̀rí tí ó múnádóko wà nípa wíwà ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ ńjẹ́ Jésù ní Israeli ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùún ọdún àkọ́kọ́ A. D.

Ó tún ṣe pàtàkì láti dámọ̀ wípé ní A. D 70, àwọn ará Róòmù wọ ìlu Jerusalẹmu àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Isrẹli ti wọn si bàá jẹ́ tí wọn pa àwọn olùgbé rẹ̀. Gbogbo ìlú ni a sun ní iná. Kò yẹ kó yàwá lẹ́nu nígbà náà, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí nípa wíwà Jésù bá di èyí tí a bàjẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn rí Jésù ni wọn yóò ti pa. Òtítọ́ yìí dín iye àwọn ẹlẹ́rìí nípa Jésù tí yóò yè kù.

Bí a bá wòye wípé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù mọ níwọ̀n sí agbègbè tí kò ṣe pàtàkì ní igun Ìjọba Róòmù kan, yóò ya ni lẹ́nu wípé iye àlàyé nípa Jésù díẹ̀ ni a lè rí láti orísun ìtàn. Lára àwọn ẹ̀rí síwájú si èyítí ó ṣe pàtàkì nípa Jésù ní àwọn wọ̀nyìí:

Takitus ará Róòmù ti ìgbà ọgọ́ọ̀run àkọ́kọ́, tí a kàsí ọ̀kan lára àwọn onítàn tí ìtàn wọn gúnrégé jùlọ ti ayé àtijọ, dárúkọ "Kristiẹni"(Láti ìnú Kristus, èyí tí ó jẹ́ èdè Latin fún Kristi), tí o jìyà lọ́wọ́ Pontius Pọ́ntíọ́s Pílátù ní ìgbà ìjọba Tiberius. Suetonius, akọ̀wé àgbà si Emperor Hadrian, kọ̀wé wípé ọkùnrin kan wà ti a ńpè ni Khrestus (tàbí Kristi) tí ó gbé ní ọgọ́rùún òdún àkọ́kọ́ (Annals 15.44).

Flavius Josephus jẹ́ akọ̀wé ìtàn Júù tí o gbajúmọ̀ jùlọ. Nínú "Antiquities" rẹ̀ òun tọ́kasí Jakọbu, "arákùnrin Jésù, tí a pè ní Kristi. Ẹsẹ (18:3) tí ó ní àríyànjiyàn kan sọ wípé, "Ní àkókò yìí Jésù wà, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan, bí o bá tọ̀nà láti pèé ní ènìyàn. Nítorí òun jẹ́ ẹnìkan tí o ṣe ohun ìyàlẹ́nu... Òun ni Kristi [náà]... Òun tún fi ara hàn wọ́n lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àwọn wòólì láti òkè wá ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn àti ẹgbẹgbẹ̀rún nǹkan iṣẹ́ ìyanu míìrán nípa rẹ̀." Ẹ̀dà kan kà báyìí, "Ní àkókò yìí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan wà tí à ńpè ní Jésù. Ìṣe rẹ̀ dára a sì mọ [òun] bíi ẹni rere. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láàrín àwọn Júù àti àwọn ìlú míìrán si di ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀. Pílátù dáa lẹ́bi kí a kàn-án mọ́ àgbélèbuù kí á sì paá. Ṣùgbọ́n àwọn ti o di ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ kò kọ jíjẹ́ ọmọ-lẹ́hìn rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n jábọ̀ wípé òun ti farahàn wọ́n ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí a ti kàn-án mọ́ àgbélèbùú, àti wípé òun wà láàyè; gẹ́gẹ́ bí èyí bóyá òun ni Messiah, ẹni tí àwọn wòólì ti ṣọ àwọn ìyanu rẹ̀."

Julius Africanus sọ nípa àkọsílẹ̀ olùkọ̀tàn Thallus nínú ìjíròrò kan nípa okùnkùn náà tí ó tẹ̀lé kíkan Kristi náà mọ́ àgbélèbùú (Extant Writings, 18).

Pliny Younger náà, nínú Letters 10:96, ṣe àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìjọ́sìn àwọn Kristiẹni àkọ́kọ́ pẹ̀lú òtítọ́ tí ó ní nínú wípé àwọn Kristiẹni ńjọ́sìn Jésù bíi Ọlọ́run ti wọn sì ní ìwà gan, tí ó si tọ́kasí àsè ìfẹ́ àti Oúnjẹ alẹ́ Olúwa.

Babylonian Talmud (Sanhedrin 43a) náà jẹ̀rìsí kíkàn Jésù mọ́ àgbélèbú ní ọjọ́ tí ó ṣaájú Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ẹ̀sùn lòdì sí Kristi pé ó ńse osó, ó sì ńgbà ni níyànjú láti pẹ̀yìndà lọ́dọ̀ àwọn Júù.

Lucian ti Samosata jẹ́ olùkọ̀ Giriki ní igba ọdún tí ó gbà wípé àwọn Kristiẹni ńjọ́sìn Jésù, fi ẹ̀kọ́ titun kọ́ ni, tí a sì kàn mọ́ àgbélèbú. Ó sọ wípé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ní nínú jíjẹ́ ẹbí kannaa àwọn onígbàgbọ́, ṣíṣe pàtàkì ìyípadà àti ṣíṣe pàtàkì sísẹ́ àwọn ọlọ́run kékékèké míìrán. Àwọn kristiéni ńgbé gẹ́gẹ́ bíi àwọn òfin Jésù, gbàgbọ́ wípé àwọn yóò wà títí láéláé, tí wọn si ní àbùdá kíkẹ́gàn ikú, jíjọ̀wọ́ ara ẹni fún ìjọ́sìn, àti ṣíṣẹ́ ohun-ìní ayé.

Mara Bar-Serapion jẹ́rìsí wípé a mọ Jésù bíi ọkùnrin ọlọ́gbọ́n àti ẹni rere kan, ọpolọpọ kàá sí ọba ní Isrẹli, a páá nípasẹ àwọn Júù, ti òun si ńtẹsiwájú láti máa gbé nínú àwọn ẹ̀kọ́ àwọn olùtẹ̀lé rẹ̀.

Lẹ́yìn náà a ní gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ Gnostic (The Gospel of Truth, The Apocryphon of John, The Gospel of Thomas, The Treatise on Resurrection, etc.) tí gbogbo wọn dárúkọ Jésù.

Ní òtítọ́, a fẹ́ẹ̀ le tún ṣe àwọn ìtàn inú ìwé ìhìnrere láti awọn orísun ti kìí ṣe ti àwọn Kristiẹni: A pe Jésù ní Kristi (Josephus), "pidán", darí Isrẹli ní àwọn ẹ̀kọ̀ titun, tí a sì fikọ́ sórí igi ní àkókò Ìrékojá fún wọn (Babylonian Talmud) ní Judea (Tacitus), ṣùgbọ́n ti òun jẹ́wọ́ wípé òun jẹ́ Ọlọ́run ti òun yóò si padà (Eliezar), èyí tí àwọn olùtẹ̀lé rẹ̀ gbàgbọ́, tí wọn ńsìn gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run (Pliny the Younger).

Ẹ̀rí tí ó kaniláyà wà fún wíwà Jésù Kristi, ní ìtan tí kìí ṣe ti bíbélì àti ti bíbélì. Bóyá ẹ̀rí tí ó tóbi jùlọ wípé Jésù wà ni wípé ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn Kristiẹni ní ìgbà ìgọ́ọ̀rún àkọ́kọ́ A.D., àti pẹ̀lú àwọn àpọ́stẹ́lì méjìlá, ṣetán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún ikú fún Jésù Kristi. Àwọn ènìyàn lè kú fún ohun ti wọ́n gbàgbọ́ pé o jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹni kan tí yóò kú fún ohun ti wọ́n mọ́ tí ó jẹ́ irọ́.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé Jésù wà ní tòótọ́? Ṣe èyíkéyi ìtàn tí ó jẹ́rìsí wíwà Jésù Kristi wà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries