settings icon
share icon
Ibeere

Nígbà wo/Báwo ni a ṣe ńgba Ẹ̀mí Mímọ́?

Idahun


Apọsteli Pọ́ọ̀lù kọ́ni kedere wípé àwa ńgba Ẹ̀mí Mímọ́ ní kété ti a gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà wa. Kọrinti kínní 12:13 sọ wípé, "Nítorípé nínú Ẹ̀mí kan li a ti baptisi gbogbo wa sínú ara kan, iba ṣe Ju, tàbí Hellene, iba ṣe ẹrú, tàbí omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹ̀mí kan." Ìwé Romu 8:9 sọ fún wa wípé bí ẹnìkan kò bá ní Ẹ̀mí Mímọ́, òun kìí ṣe ti Kristi: "Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bíkòṣe nínú Ẹ̀mí Ọlọ́run ńgbé inú yin. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀." Ìwé Efesu 1:13-14 kọ́ wa wípé Ẹ̀mí Mímọ́ ni èdìdì fún ìgbàlà fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: "Nínú ẹnití, ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbàtí ẹ̀yin ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ nì, ìhìnrere ìgbàlà yín, nínú ẹnití nígbàtí ẹ̀yin ti gbàgbọ́ pẹ̀lú, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ìlérí nì ṣe èdìdì yin."

Àwọn ẹsẹ̀ mẹta wọ̀nyìí jẹ́ kí o hàn kedere wípé a gba Ẹ̀mí Mímọ́ ní àkókò ìgbàlà. Pọ́ọ̀lù kò le sọ wípé a baptisi gbogbo wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí kan àti wípé gbogbo wa mu nínú Ẹ̀mí kan bíkòṣe wípé gbogbo àwọn onígbàgbọ́ Kọrinti ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ìwé Romu 8:9 èyí tí ó tún nípọn sọ fún wa wípé bí ẹnìkan kò bá ní Ẹ̀mí Mímọ́, òun kìí ṣe ti Kristi: Fún ìdí èyí, níní Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ àmì dídá níní ìgbàlà mọ̀. Síwájú síi, Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè jẹ́ "èdìdì ìgbàlà"(Efesu 1:13-14) bí a kò bá gba Òun ní àkókò ìgbàlà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé mímọ́ jẹ́ kí ó hàn kedere l'ọ́pọ̀lọpọ̀ wípé ìgbàlà wa ní a pamọ́ ní kété tí a gba Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà.

Ìjíròrò yìí jẹ́ àríyànjiyàn nítorí ìpòrurù wa pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Gbígba/kíkún ni pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ ńwáyé ní àkókò ìgbàlà. Kíkún ni pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ èyí tí ó ńtẹ̀síwájú nínú aye Kristiẹni. Nígbàtí a gbà wípé ìrìbọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́ tún ńwáyé ní àkókò ìgbàlà, àwọn Kristiẹni kan kò faramọ. Èyí ní ọ̀pọ̀ ìgbà máa ńmú ìpòrurù wá nípa ìrìbọmi Ẹ̀mí pẹ̀lú "gbígba Ẹ̀mí" gẹ́gẹ́ bíi ìṣẹ̀lẹ̀ tí o tẹ̀lé ìgbàlà.

Ní àkótán, báwo ni a ṣe ńgba Ẹ̀mí Mímọ́? Àwa gba Ẹ̀mí Mímọ́ nípa gbígba Jésù Kristi Olúwa gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà (Johannu 3:5-16). Nígbà wo ni a ńgba Ẹ̀mí Mímọ́? Ẹ̀mí Mímọ́ di ohun-ìní wa láíláí ní kété tí àwa gbàgbọ́.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Nígbà wo/Báwo ni a ṣe ńgba Ẹ̀mí Mímọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries