settings icon
share icon
Ibeere

Níbo ni ìwọ yóò lọ nígbàtí o bá kú?

Idahun


Bíbélì fihàn kedere wípé, lẹ́yìn ohun gbogbo, àwọn ìpín méjì nìkan l'ówà níbití ìwọ lè lọ bí o bá kú: ọ̀run rere tàbí ọ̀run-àpáàdì. Bíbélì tún fihàn kedere wípé ìwọ lè pinnu ibi tí ìwọ ńlọ bí o bá kú. Bawo? Kàá síwájú.

Àkọ́kọ́, ìṣòro náà. Gbogbo wa ti ṣẹ̀ (Romu 3:23). Gbogbo wa ti ṣe ohun tí ó lòdì, ibi, tàbí àìmọ́ (Oniwaasu 7:20). Ẹ̀ṣẹ̀ wa yà wá nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti, bí a bá fi sílẹ̀ láì yanjú, ẹ̀ṣẹ̀ wa yóò yọrí sí ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run (Matteu 25:46; Romu 6:23a). Ìyapa ayérayé yìí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀run-àpáàdì, tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bíi adágún iná ayérayé (Ifihan 20:14-15).

Níbàyí, ọ̀nà àbáyọ. Ọlọ́run wá di Ènìyàn tíí ṣe Jésù Kristi (Johanu 1:1, 14; 8:58; 10:30). Òun gbé ìgbe-ayé àílẹ́ṣẹ̀ (1 Peteru 3:22; 1 Johannu 3:5) tí ó sì fi ara rẹ̀ rúbọ tọkàntọkàn ní ipò wa (1 Kọrinti 15:3; 1 Peteru 1:18-19). Ikú Rẹ̀ san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa (2 Kọrinti 5:21). Ọlọ́run wá pèsè ìgbàlà àti ìdáríjì gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀bùn (Romu 6:23b) wípé a gbọ́dọ̀ gbàá nípa ìgbàgbọ́ (Johannu 3:16; Efesu 2:8-9). "Gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là" (Iṣe àwọn Apọsteli 16:31). Gbàgbọ́ nínú Jésù nìkan gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ, gbígbẹ́kẹ̀lé ètùtù Rẹ̀ nìkan gẹ́gẹ́ bíi ìsan gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, àti, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ti ṣe ìlérí ìyè ayérayé fún ọ ní ọ̀run.

Níbo ni ìwọ yóò lọ nígbàtí o bá kú? Ó kù sí ọ lọ́wọ́. Ọlọ́run fún ọ láàyè láti yàn. Ọlọ́run ńpè ọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ òun. Ìpè rẹ ni.

Bí o bá rò wípé Ọlọ́run ńfà ọ́ sí ìgbàgbọ́ nínú Kristi (Johannu 6:44), wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà náà. Bí Ọlọ́run bá ńyọ ìbòjú àti ìfọ́jú ẹ̀mí kúrò (2 Kọrinti 4:4), wo ọ̀dọ̀ Olùgbàlà náà. Bí ò bá ńní ìrírí ìtají ẹ̀mí nínú ohun tí ó ti fi ìgbàgbogbo kú (Efesu 2:1), wá sí ibi ìyè nípaṣẹ̀ Olùgbàlà.

Níbo ni ìwọ yóò lọ nígbàtí o bá kú? Ọ̀run rere tàbí ọ̀run-àpáàdì. Nípaṣẹ̀ Jésù Kristi, a lè yàgò fún ọ̀run-àpáàdì. Gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ, ọ̀run rere yóò sì jẹ́ ilé ayérayé rẹ. Ṣe ìpinnu míìrán, ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú ọ̀run-àpáàdì ni àyọrísí rẹ̀ (Johannu 14:6, Ìṣe àwọn Apọsteli 4:12).

Bí o bá ti wa ní òye ìtumọ̀ ibi méjèjì tí ó ṣeé ṣe kí o lọ bí o ba ku bá ti yé ọ báyìí, tí o sì fẹ́ gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà rẹ, ríi wípé o ní òye àti gbàgbọ́ nǹkan wọ̀nyìí, àti gẹ́gẹ́ bíi ìṣe ìgbàgbọ́, sọ àwọn nǹkan wọ̀nyìí sí Ọlọ́run. "Ọlọ́run, mo mọ̀ wípé ẹlẹ́ṣẹ́ ni mí, mo sì mọ̀ wípé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi mo l'ẹ́tọ̀ọ́ sí ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Rẹ. Kódà tí nkò bá l'ẹ́tọ̀ọ́ síi, O ṣeun tí o fẹ́ràn mi àti ìpèsè ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi nípa ikú àti àjíǹde Jésù Kristi. Mo gbàgbọ́ wípé Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi mo sì gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ nìkan láti gbà mí là. Lati ìgbà yìí lọ, ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbe-ayé mi fún Ọ dípò fún ẹ̀ṣẹ̀. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìyóóku ayé mi nínú ọpẹ́ fún ìyanu ìgbàlà tí Ìwọ ti pèsè. O ṣeun, Jésù, fún gbígbà mí là!"

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Níbo ni ìwọ yóò lọ nígbàtí o bá kú?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries