settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni mo ṣe lè múrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó?

Idahun


Pípèsè ara ẹni fún ìgbeyàwó ní ìlàna bíbélì jẹ́ nǹkàn kan náà pẹ̀lú mímúrasílẹ fún èyíkéyì ìgbìyànjú ayé. Ìlànà kan wà tí ó yẹ kí ó máa ṣe àkóso gbogbo àwọn ìpele ayé wa gẹ́gẹ́ bí àwọn onígbàgbọ́ tí o tí di àtúnbí: "Kí iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọ́run Oluwa rẹ" (Matteu 22:37). Èyí kìí ṣe àṣẹ gbẹ̀fẹ́. Ó jẹ́ òkúnkúndùn ayé wa gẹ́gẹ́ bíi àwọn onigbàgbọ́. Ó jẹ́ yíyàn láti ni ìfojúsùn sí ọ̀dọ Ọlọ́run àti sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa kí ọkàn àti àwọn èro wa lè kún fún àwọn ohun náà tí yóò fún Ún ní ìdùnnú.

Ìbáṣepọ̀ tí a ní pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ Jésù Kristi Olúwa náà jẹ́ ohun tí o mú gbogbo àwọn ìbáṣepọ̀ yòókù sí ojú ìwòye. Ìbáṣepọ̀ ti ìgbéyàwó dá lórí àwòṣe ti Kristi àti ìjọ Rẹ̀ (Efesu 5:22-33). Gbogbo ìpele ti àwọn ayé wa ní a ńṣe àkóso nìpa ìfarajìn wa gẹ́gẹ́ bí àwọn onígbàgbọ́ láti gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin àti àwọn ìlànà ti Olúwa. Ìgbọ́ràn wa sí Ọlọ́run àti sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ńró wa lágbára láti lè mù àwọn ojúṣe tí Ọlọ́run là kalẹ̀ nínú ìgbeyàwó àti nínù ayé ṣẹ. Àti wípé ojúṣe gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tí o ti di àtúnbí ni láti fi ògo fún Ọlọ́run nínú ohun gbogbo (1 Kọrinti 10:37).

Láti pèsè ara rẹ sílẹ̀ fún ìgbéyàwó, láti rìn ní ọ̀nà tí ó yẹ ti ìpè rẹ nínú Kristi Jésù, àti láti lè wà ní tímọ́tímọ́ pẹ̀lù Ọlọ́run nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (2 Timoteu 3: 16-17), fi ojú sùn lórí ìgbọ́ràn nínú ohun gbogbo. Kò sí ètò tí o rọrùn láti kọ́ láti lè rìn nínú igbọ́ràn sí Ọlọ̀run. Ó jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ yàn lójojúmọ́ láti gbé ojú ìwòye ayé yìí sápá kan kí a sì tẹ̀lé Ọlọ́run dípò rẹ̀. Rínrìn ní ọ̀nà tí ó yẹ Kristi jẹ́ láti jọ̀wọ́ ara wa ní ìrẹ̀lẹ̀ sì Ọ̀nà kan ṣoṣo náà, Òtítọ́ kan ṣoṣo náà àti Ìyè ṣoṣo kan náà ní ìpìlẹ̀ ọjọ́ dé ọjọ́, ìgbà dé ìgbà. Èyí jẹ́ ìmùrasílẹ̀ náà tí gbogbo onígbàgbọ́ nìlò láti mùrasílẹ̀ fún ẹ̀bùn nlá nì tí à ńpè ní ìgbéyàwó.

Ènìyàn kan tí ó ti dàgbà nìpa ti ẹ̀mì tí ó sì ńrìn pẹ̀lú Ọlọ́run wà ní ìmúrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó ju ẹnikẹ́ni lọ. Ìgbéyàwó pè fún ìfarajìn, ìfẹ́ gidigidi, ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́, àti ìbọ̀wọ̀. Àwọn ìwà wọ̀nyìí máa ńfarahàn jùlọ nínú ẹni tí ó ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí o tí ńmúrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó, ní ìfojúsùn ní fífi ààyè gba Ọlọ́run kí ó kọ́ ọ àti mọ ọ́ sí ọkùnrin tàbí obìnrin tí Òun fẹ́ kí ìwọ́ jẹ́ (Romu 12: 1-2). Bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún Un, yóò jẹ́ kí o wà ní ìmúrasílẹ̀ fún ìgbeyàwó nígbà tí ọjọ́ iyánú náà bá dé.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni mo ṣe lè múrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries