Ibeere
Báwo ni nkò ṣe ní lọ sí ọ̀run-àpáàdì?
Idahun
Láti má lọ sí ọ̀run-àpáàdì rọrùn ju bí o ṣe rò lọ. Àwọn ènìyàn kan gbàgbọ́ wípé àwọn nílò láti gbọ́ràn sí àwọn Òfin Mẹ́ẹ̀wá fún gbogbo ọjọ́ ayé wọn kí wọ́n má bàa lọ sí ọ̀run-àpáàdì. Àwọn ènìyàn kan gbàgbọ́ wípé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìrúbọ kan kí wọ́n má bàa lọ sí ọ̀run-àpáàdì. Àwọn ènìyàn kan gbàgbọ́ wípé kò sí ọ̀nà tí a fi le mọ̀ dájú wípé bóyá àwa yóò lọ sí ọ̀run-àpáàdì tàbí a kò ní lọ. Kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ìwòye wọ̀nyìí tí ó tọ̀nà. Bíbélì hàn kedere lórí bí ẹnìkan ṣe le yàgò fún lílọ sí ọ̀run-àpáàdì lẹ́yìn ikú.
Bíbélì ṣe àpèjúwe ọ̀run-àpáàdì gẹ́gẹ́ bíi ibi ìbẹ̀ẹ̀rù àti oró. A ṣe àpèjúwe ọ̀run-àpáàdì gẹ́gẹ́ bíi "iná ayérayé" (Matteu 25:41), "iná àjóòkú" (Matteu 3:12), "ìtìjú àti ẹ̀gàn ayérayé" (Daniẹli 12:2), ibi tí "iná kìí kú" (Marku 9:44-49), àti "ìparun ayérayé" (2 Tẹsalonika 1:9). Ifihan 20:10 ṣe àpèjúwe ọ̀run-àpáàdì gẹ́gẹ́ bíi "adágún iná tí ń fi súfúrù jó" níbití àwọn ìkà tí ń "jẹ oró t'ọ̀sán-t'ọ̀ru láí àti láíláí" (Ifihan 20:10). Ó hàn gbangba wípé, ọ̀run-àpáàdì jẹ́ ibi tí a gbọ́dọ̀ yàgò fún.
Kílódé tí ọ̀run-àpáàdì ṣe wà àti kílódé tí Ọlọ́run ṣe rán àwọn ènìyàn kan síbẹ̀? Bíbélì sọ fún wa wípé Ọlọ́run ti "pèsè" ọ̀run-àpáàdì sílẹ̀ fún èṣù àti àwọn ańgẹ́lì tí ó subú lẹ́yìn tí wọn ṣọ̀tẹ̀ sí I (Matteu 25:41). Àwọn tí ó kọ ìpèsè ìdáríjìn Ọlọ́run yóò jìyà àyànmọ́ ayérayé kannáà pẹ̀lu èṣù àti àwọn ańgẹ́lì tí ó ti subú. Kínni ìdí tí ọ̀run-àpáàdì fi ṣe pàtàkì? Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ lòdì gidigidi sí Ọlọ́run (Orin Dafidi 51:4), ati nítorí Ọlọ́run jẹ́ ẹni àìlópin àti ayérayé, ìjìyà àìlópin àti ayérayé nìkan ti tó. Ọ̀run-àpáàdì jẹ́ ibi tí ìdájọ́ òdodo ti Ọlọ́run mímọ́ àti òdodo ti ńṣẹlẹ̀. Ọ̀run-àpáàdì ni ibi tí Ọlọ́run ti ṣe ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ àti gbogbo àwọn tí ó kọ̀ọ́ sílẹ̀. Bíbélì fihàn kedere wípé gbogbo wa lati ṣẹ̀ (Oniwaasu 7:20; Romu 3:10-23), Ní báyi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo wa l'ẹ́tọ̀ọ́ láti lọ si ọ̀run-àpáàdì.
Nítorínáà, báwo ni nkò ṣe ní lọ sí ọ̀run-àpáàdì? Bí ó ṣe jẹ́ wípé ìjìyà àìlópin àti ayérayé nìkan ti tó, gbèse àìlópin àti ayérayé gbọ́dọ̀ jẹ́ sísan. Ọlọ́run wá di Ènìyàn ẹni tíí ṣe Jésù Kristi. Nínú Jésù Kristi, Ọlọ́run gbé láàrin wa, Òun kọ́ wa, ó sì mú wa lára dá—ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wọ̀n yẹn kìí ṣe iṣẹ́ pàtàkì Rẹ̀. Ọlọ́run di ènìyàn (Johannu 1:1, 14) nítorí wípé kí Òun lè kú fún wa. Jésù, Ọlọ́run ní àwòrán ènìyàn, kú lórí igi àgbélèbú. Gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run, ikú Rẹ̀ jẹ́ iye àìlópin àti ayérayé, tí ńsan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ (1 Johannu 2:2). Ọlọ́run ńpè wá láti gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà, gbigba ikú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìsanwó fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ wa l'ótìtọ́ọ́ àti ní yíye. Ọlọ́run ṣe ìlérí wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Jésù (Johannu 3:16), tí ó gba òun nìkan gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà (Johannu 14:6), yóò là, à ní, kì yóò lọ sí ọ̀run-àpáàdì.
Ọlọ́run kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí o lọ sí ọ̀run-àpáàdì (2 Peteru 3:9). Ìdí nìyí tí Ọlọ́run fi ṣètò ìrúbọ ńlá, pípé, àti tító nípò wa. Bí o kò bá fẹ́ lọ sí ọ̀run-àpáàdì, gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ. Kò rọrùn jù báyẹn lọ. Sọ fún Ọlọ́run wípé o mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ́ àti wípé o yẹ kí o lọ sí ọ̀run-àpáàdì. Sọ fún Ọlọ́run wípé ìwọ ńgbẹ́kẹ̀lé Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè ìgbàlà àti ìdáǹdè rẹ lọ́wọ́ ọ̀run-àpáàdì. Ìgbàgbọ́ tí ó rọrùn, gbígbẹ́kẹ̀lé Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà, ni bí ìwọ yóò ṣe le yàgò fún lílọ sí ọ̀run-àpáàdì!
Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!
Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.
English
Báwo ni nkò ṣe ní lọ sí ọ̀run-àpáàdì?