settings icon
share icon
Ibeere

Lílọ sí ọ̀run — báwo ni mo ṣe le ṣe ìmúdánilójú ilé ayérayé mi?

Idahun


Kọjú mọ́-ọn. Ọjọ́ tí a o wọ ayérayé le dé láìpẹ́ ju bí a ṣe lérò lọ. Ní ìmúrasílẹ̀ fún ìgbà náà, a gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́—kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni o ńlọ sí ọ̀run. Báwo ni a ṣe le mọ̀ dájú wípé a ńlọ sí ọ̀run? Ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, àpọ́stélì Peteru àti Johannu ńwàásù ìhìnrere Jésù Kristi fún ọ̀pọ̀ èrò ní Jerusalẹmu. Peteru sọ gbólóhùn ńlá kan tí ó rinlẹ̀ kódà nínú ayé òde òní tiwa: "Ìgbàlà ni a kò lè rí nínú elòmíràn, nítorí kò sí orúkọ kan lábẹ ọrun tí a fi fún àwọn èniyàn nípa èyí tí a lè fi ní ìgbalà." (Ìṣe àwọn Apọsteli 4:12).

Nísisìnyí bíi ìgbà náà, Iṣẹ àwọn Apọsteli 4:12 kò tọ̀nà ní ìwòye òṣèlú. Lóníì ó gbajúgbajà láti sọ wípé, "Gbogbo ènìyàn ló ńlọ sí ọ̀run" tàbí '"Gbogbo ọ̀nà lọ sí ọ̀run." Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni o rò wípé àwọn lè dé ọ̀run láì ní Jésù. Wọ́n fẹ́ ògo náà, ṣùgbọ́n wọ́n kò fẹ́ mọ̀ nípa àgbélèbú, kí á tó wá sọ nípa Ẹni tí ó kú níbẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò fẹ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà kan soso láti lọ sí ọ̀run wọ́n sì gbìyànjú láti wá ọ̀nà míìrán. Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wa wípé kò sí ọ̀nà míìrán àti wípé ìjìyà kíkọ́ òtítọ́ yìí jẹ́ ayérayé nínú ọ̀run-àpáàdì. Ó sọ fún wa wípé "Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹkun, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ Ọmọ náà kì yíì ò rí ìyè, nítorí ìbínú Ọlọ́run ńbẹ lórí ẹni bẹ́ẹ̀" (Johannu 3:36). Ìgbàgbọ́ nínú Kristi ni kọ́kọ́rọ́ sí lílọ sí ọ̀run.

Àwọn kan yóò jiyàn wípé èrò Ọlọ́run kúrú láti pèṣè ọ̀nà kan soso sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n, lóòtọ́, nínú ìṣọ́tẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn sí Ọlọ́run, èrò Rẹ̀ gbòòrò láti pèsè ọ̀nàkọnà sí ọ̀run fún wa. Àwa yẹ fún ìdájọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún wa ní ọ̀nà àbáyọ nípa ríran Ọmọ Rẹ̀ kan soso láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Bóyá ẹnìkan rí èyí gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà tóóró tàbí gbòòrò, ó jẹ́ òtítọ́. Ìhìnrere náà ni wípé Jésù kú ó sì jí dìde; àwọn tí ńlọ sí ọ̀run ti gba ìhìnrere yìí nípa ìgbàgbọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló di ìhìnrere tí a ti bu omi là mú èyítí kò sí nání ìdí fún ìronúpìwàdà. Wọ́n fẹ́ gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run "ìfẹ́" (tí kìí dáni lẹ́jọ́) tí kìí mẹnubà ẹ̀ṣẹ̀ tí kìí sì bèèrè ìyípadà nínú ìgbé-ayé wọn. Wọ́n le sọ nǹkan bíi, "Ọlọ́run mi kò ní rán ènìyàn lọ sí ọ̀run-àpáàdì." Ṣùgbọ́n Jésù sọ púpọ̀ nípa ọ̀run-àpáàdì ju bí o ti sọ nípa ọ̀run, o sì fi ara Rẹ hàn bíi Olùgbàlà ẹnití ó pèsè ọ̀nà kan soso sí ọ̀run: "Èmi ni ọnà òtítọ àti ìyè náà. Kò sí ẹni tí ó lè wá sọdọ Baba bíkòṣe nípasẹ mi." (Johannu 14:6).

Tani yóò wọ ìjọba Ọlọ́run gan an? Báwo ni mo ṣe le ní ìdánilójú wípé mò'ún lọ sí ọ̀run? Bíbélì ṣe àfihàn ìyàtọ̀ kedere láàrin àwọn tí ó ní ìyè ayérayé àti àwọn tí kò ní: "Ẹnití ó bá ni Ọmọ, ó ní ìyè; ẹnití kò bá sì ní Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè" (1 Johannu 5:12). Gbogbo rẹ̀ padà sí ìgbàgbọ́. Àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Kristi àwọn ni a sọ di ọmọ Ọlọ́run (Johannu 1:12). Àwọn tí ó gba ìrúbọ Jésù gẹ́gẹ́ bí ìsan gbèsè ẹ̀sẹ̀ wọn àti àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú àjíǹde Rẹ̀ ńlọ sí ọ̀run. Àwọn tó kọ Jésù kò lọ. "Ẹnití ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹnití kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ náà, nítorítí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí kan soso ti Ọlọ́run gbọ́" (Johannu 3:18).

Bí ọ̀run yóò ti dùn tó fún àwọn tí ó gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi olùgbàlà, ọ̀run-àpáàdì yóò gbòrò gan fún àwọn tí ó kọ̀ Ọ́. Ènìyàn kò lè ka Bíbélì dáadáa láì rii lemọ́lemọ́—a ti fa ìlà. Bíbélì sọ wípé ọ̀nà kan soso ló wà sí ọ̀run—Jésù Kristi. Tẹ̀lé àṣẹ Jésù: "Ẹ bá ẹnu-ọ̀nà híhá wọlé. Gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbú ní ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹnití ń bá ibẹ̀ wọlé. Nítorí pé híhá ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti tóóró ní ojú-ọ̀nà náà, tí ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹnití ó ń rìn-in" (Matteu 7:13 àti 14).

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni ọ̀nà kan soso sí lílọ sí ọ̀run. Àwọn tí ó nìgbàgbọ́ ní ìdánilójú láti dé ibẹ̀. Ṣé ìwọ́ ni ìgbẹkẹ̀lé nínú Jésù?

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Lílọ sí ọ̀run — báwo ni mo ṣe le ṣe ìmúdánilójú ilé ayérayé mi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries