Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa kí Kristiẹni ṣiṣẹ́ ológun?
Idahun
Bíbélì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ nípa ṣíṣe íṣẹ́ ológun. Nígbà tí ọ̀pọ̀ atọ́ka Bíbélì jẹ́ àfiwé lásán, onírúurú ẹsẹ̀ ló sọ tàrà nípa ìbéèrè yìí. Bíbélì kò sọ ní pàtó wípé kí ènìyàn ṣe iṣẹ́ ológun tàbí kí ó má ṣeé. Nígbà kannáà, Kristiẹni lè ní ìdánilójú wípé jíjẹ́ ológun ní ọ̀wọ̀ púpọ̀ nínú gbogbo ìwé mímọ́, àti wípé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wà ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé pẹ̀lú àfojúsùn Bíbélì.
Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ ti iṣẹ́ ológun ni a lè rí nínú Májẹ̀mú Láíláí (Jẹnẹsisi 14), nígbàtí Kedorláómérì Ọba Élámù àti àwọn ìjòyè rẹ̀ jí Lọ́tì arákùnrin Ábráhámù gbé. Ábráhámù ṣe ìgbọ̀wọ́ fún Lọ́tì nípa kíkó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọ̀rìndínírinwó (318) ènìyàn ó dín méjì tí a ti kọ́, tí ó sì ṣẹ́gun àwọn ará Élámù. Níbí a rí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ṣiṣẹ́ tí ó lọ́wọ̀—gbígbà àti dídáàbòbò àwọn aláìṣẹ̀.
Ní òpin ìtàn rẹ̀, orílẹ̀-èdè Isrẹli ní ọmọ ogun tí ó dúró. Ìdí ni wípé Ọlọ́run ni Olórí ogun ọ̀run tí ó sì dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀, láì fi ti agbára ogun wọn ṣe lè jẹ́ ìdí tí Isrẹli fi pẹ́ kí wọ́n tó yan ọmọ ogun. Níní ọmọ ogun tí ó dúró ní Isrẹli wá lẹ́yìn ìgbà tí Sọ́ọ́lù, Dáfídì, àti Sólómọ́nì gbé ètó òṣèlú gbogbogbò kalẹ̀. Sọ́ọ́lù ló kọ́kọ́ ṣe àgbékalẹ̀ ọmọ ogun tí ó dúró (1 Samuẹli 13:2; 24:2; 26:2).
Ohun tí Sọ́ọ́lù bẹ̀rẹ̀, Dáfídì tẹ̀síwájú. Ó fikún àwọn ọmọ ogun náà, ó mú àwọn ikọ̀ tí a yá láti ìpínlẹ̀ míìrán tí ó ṣe olótítọ́ sí òhun nìkan (2 Samuẹli 15:19-22), tí ó sì darí ìjọba tàra sí Jóábù, olórí ogun. Lábẹ́ Dáfídì, Isrẹli di ògbóǹtarìgì nínú àwọn ọ̀nà àtakò tí àwọn ọmọ ológun máa ńlò, tí ó sì fi gba àwọn ìpínlẹ̀ tí ó súnmọ́ wọn bíi Ámónì (2 Samuẹli 11:1; 1 Kronika 20:1-3). Dáfídì gbé ètò yíyípo àwọn ọmo ogun ní ìṣọ̀rí méjìlá ti ènìyàn ẹgbàá mẹ́rìnlélógún yóó máa jagun fún oṣù kan nínú ọdún kalẹ̀ (1 Kronika 27). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, ìṣàkóso Sólómọ́nì ní àlàáfíà, ó tẹ àwọn ọmọ ogun síwájú nípa fífi kún àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin (1 Àwọn Ọba 10:26). Àwọn ọmọ ogun tí ó dúró tẹ̀síwájú (bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n pínyà pẹ̀lú ìjọba lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì) títí ó fi di ọdún 586 B.C., nígbà tí Ísrẹli (Júdà) kọ̀ láti máa jẹ́ orílẹ̀-èdè olóṣèlú.
Nínú Májẹ̀mú Titun, ó ya Jésù lẹ́nu nígbàtí Balógun ọrún (òṣìṣẹ́ tí ó wà fún àkóso ọgọ́rún ọmọ ogun) tọ̀ Ọ́ wá. Ìdáhùn Balógun náà túmọ̀ sí òye kedere rẹ̀ nípa àṣẹ, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù (Matteu 8:5-13). Jésù kò ta iṣẹ́ rẹ̀ dànù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn Balógun tí a sọ nípa wọn nínú Májẹ̀mú Titun ni a rí gẹ́gẹ́ bíi Kristiẹni, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àti ènìyàn tí ó ní ìwà rere ((Matteu 8:5; 27:54; Marku 15:39-45; Luku 7:2; 23:47; Ìṣe àwọn Apọsteli10:1; 21:32; 28:16).
Agbègbè àti àkọ́rí lè ti yípadà, ṣùgbọ́n ikọ̀ ogun wa sì gbọ́dọ̀ níyì bí ti àwọn Balógun nínú Bíbélì. Iṣẹ́ jagunjagun ní iyì púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù ṣe àpèjúwe Ẹpafródítù arákùnrin Kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí "ẹgbẹ́ ọmọ ogun" (Filppi 2:25). Bíbélì tún lo àwọn èdè ọmọ ogun láti ṣe àpèjúwe jíjẹ́ alágbára nínú Olúwa nípa gbígbé ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀ (Efesu 6:10-20), pẹ̀lú irinṣẹ́ ọmọ ogun—àṣíborí, apata, àti idà.
Bẹ́ẹ̀ni, Bíbélì náà sọ nípa sísìn nínú iṣẹ́ ológun ní tàrà àti ẹlẹ́lọ́. Kristiẹni l'ọ́kùnrin àti l'óbìnrin tí wọ́n sin orílẹ̀-èdè wọn pẹ̀lú ìwà, ìbọ̀wọ̀ àti iyìn lè fọkàn balẹ̀ pé iṣẹ́ tí wọ́n ńṣe jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn tó sìn nínú iṣẹ́ ológun tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yẹ fún ìbọ̀wọ̀fún àti ìmoore wa.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa kí Kristiẹni ṣiṣẹ́ ológun?