settings icon
share icon
Ibeere

Ṣe ó yẹ kí Kristiẹni lọ sí ọ̀dọ̀ oníṣègùn òyìnbó?

Idahun


Àwọn Kristiẹni kan gbàgbọ́ wípé wíwá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn òyìnbó ńfi àìní ìgbàgbọ́ hàn nínú Ọlọ́run. Nínú ètò Ọ̀rọ̀-Ìgbàgbọ́, a máa ńsábà rò wípé lílọ sí ọ̀dọ̀ oníṣègùn òyìnbó jẹ́ àìní ìgbàgbọ́ tí kò ní jẹ́ kí Ọlọ́run wò ọ́ sàn. Nínú àwọn ìṣọ̀rí bíi sáyẹ́nsì Kristiẹni, a máa ńwo wíwá ìrànlọ́wọ́ oníṣègùn òyìnbó bíi ìdíwọ́ sí lílo agbára ẹ̀mí tí Ọlọ́run fi fún wa láti wo ara wa sàn. Èró àfojúsùn yìí kù díẹ̀ káàtó. Bí ọkọ̀ rẹ bá bàjẹ́, ṣé o máa gbe lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn atúnkọ̀ ṣe ni tàbí ìwọ yóò dúró de Ọlọ́run láti ṣe ìyanu nípa wíwo ọkọ̀ rẹ sàn? Bí ẹ̀rọ-omi ní ilé rẹ bá bẹ́, ṣé ìwọ yóò dúró de Ọlọ́run láti díi pa, tàbí ìwọ yóò pe ẹni tí ó ńtún ẹ̀rọ-omi ṣe? Ọlọ́run ní agbára láti tún ọkọ̀ ṣe tàbí láti tún ẹ̀rọ-omi ṣe. Òtítọ́ wípé Ọlọ́run lè ṣe, àti wípé Òun sì ńṣe ìyanu ìwòsàn kò túmọ̀ sí wípé a gbọ́dọ̀ máa retí ìyanu dípò kí á máa wá ìrànlọ́wọ́ ẹni tí ó ní ìmọ̀ àti òye láti ràn wá lọ́wọ́.

A tọ́kasí àwọn oníṣègùn òyìnbó ní ìgbà méjìlá nínú Bíbélì. Ẹsẹ̀ kan ṣoṣo tí a lè yọ kúrò nínú àyálò láti kọ́ wípé ènìyàn kò lè lọ sí ọ̀dọ̀ oníṣègùn òyìnbó ni ìwé Króníkà kejì 16:12. "Àti lí ọdún kọkàndílógójì ìjọba rẹ̀, Ásà ṣe àìsàn lí ẹsẹ̀ rẹ̀, títí àrùn rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: Síbẹ̀ nínú àìsàn rẹ̀ òun kò wá Olúwa, bíkòṣe àwọn oníṣègùn." Ọ̀ràn náà kìí ṣe nítorí wípé Ásà wá oníṣègùn, ṣùgbọ́n wípé "òun kò wá Olúwa" Kódà nígbà tí a bá bẹ oníṣègùn òyìnbó wò, ìgbàgbọ́ wa tí ó jàjú gbọ́dọ̀ wà nínú Ọlọ́run, kìí ṣe ninú oníṣègùn òyìnbó náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹsẹ̀ sọ nípa lílo "ìtọ́jú ìṣègùn" bíi lílo báńdèjì (Isaiah 1:6), òróró (Jakọbu 5:14), òróró àti ọtí-wáínì (Luku 10:34), ewé (Ẹsekiẹli 47:12), ọtí-wáínì (2 Timoteu 5:23), àti ọṣẹ, ní pàtàkì "òróró Gílíàdì" (Jẹrimiah 8:22). Pẹ̀lú, Pọ́ọ̀lù pe Lúkù, ẹni tí ó kọ ìwé Ìṣe àwọn Àpọ́stélì àti ìhìnrere ti Lúkù ní "oníṣègùn olùfẹ́"(Kolosse 4:14).

Marku 5:25-30 sọ nípa obìnrin tí ó ní ìṣòro ìsun ẹ̀jẹ̀ tí kò dá, ìṣòro tí àwọn oníṣègùn òyìnbó kò le wòsàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ti tọ ọ́pọ́lọpọ̀ lọ, tí ó sì ti ná gbogbo owó rẹ̀. Wíwá sọ́dọ̀ Jésù, ó rò wípé bí òun bá fi ọwọ́ kan ìsẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara òun yó yá gágá: o fí ọwọ́ kàn án, ara rẹ̀ sì yá gágá. Jésù, nígbàtí ó ńdá àwọn Farisì lóhùn nípa ìdí tí ó fi ńlo àkókò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sọ fún wọn wípé "Àwọn tí ara wọn le kò fẹ́ oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá" (Matteu 9:12). Nínú àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyìí a lè fa àwọn ìlànà wọ̀nyìí yọ:

1) Àwọn oníṣègùn òyìnbó kìí ṣe Ọlọ́run, a kò sì gbọ́dọ̀ rí wọn bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè ran ni lọ́wọ́ nígbà míìrán, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n lè ṣe ní àkókò míìrán ni láti yọ owó kúrò.

2) A kò dá wíwá oníṣègùn òyìnbó àti lílo àtúnṣe "ti ayé" lẹ́bi nínú Ìwé Mímọ́. Kódà, a rií wípé ìtọ́jú ara ti ìṣègùn òyìnbó dára.

3) A gbọ́dọ̀ wá kí Ọlọ́run dásí wa nínú ìṣòro ayé (Jakọbu 4:2; 5:13). Òun kò ṣe ìlérí wípé Òun yóò dá wa lóhùn bí a bá ṣe fẹ́ nígbà gbogbo (Isaiah 55:8-9), ṣùgbọ́n a ní ìdánilójú wípé gbogbo ohun tí ó bá ṣe yóò jẹ́ nínú ìfẹ́, tí yóò sì jẹ́ fún rere wa (Orin Dafidi 145:8-9).

Nítorí náà, ṣe ó yẹ kí Kristiẹni lọ sí ọ̀dọ̀ oníṣègùn òyìnbó? Ọlọ́run dá wa ní ẹ̀dá tí ó ni ọpọlọ, ó sì fún wa ní agbára láti ṣe oògùn àtí láti kọ́ bí a ti lè tún ara wa ṣe. Kò sí ohun tí ó burú nínú lílo ìmọ̀ àti agbára wa fún ìwòsàn ara wa. A gbọ́dọ̀ rí àwọn oníṣègùn òyìnbó gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀bùn Ọlọ́run sí wa, ọ̀nà tí ó gbà láti mú ìwósàn àti ìmúláradá wá. Nígbàkan náà, gbogbo ìgbàgbọ́ wa àti ìgbẹ́kẹ̀le wa gbọ́dọ̀ wà nínú Ọlọ́run kìí ṣe nínú oníṣègùn òyìnbó tàbí oògùn. Nínú gbogbo ìpinnu líle, a gbọ́dọ̀ wá Ọlọ́run tí ó ṣe ìlérí láti fún wa ni ọgbọ́n nígbà tí a bá bèrè fún un (Jakọbu 1:5).

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ṣe ó yẹ kí Kristiẹni lọ sí ọ̀dọ̀ oníṣègùn òyìnbó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries