settings icon
share icon
Ibeere

Ṣe àwọn Kristiẹni nńí láti gbọ́ràn sí àwọn òfin ilẹ̀?

Idahun


Romu 13:1-7 sọ wípé, "Ki olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti ó wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti ó si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá. Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn. Nitori awọn ijoye kì iṣe ẹ̀rù si iṣẹ rere, bikoṣe si iṣẹ buburu. Njẹ iwọ ha fẹ ṣaibẹru aṣẹ wọn? Ṣe eyi ti o dara, iwọ ó si gbà iyìn lati ọdọ rẹ̀: Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe si ọ fun rere. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe buburu, bẹru; nitori kò gbé idà na lasan: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe, olugbẹsan lati ṣiṣẹ ibinu lara ẹniti nṣe buburu. Nitorina ẹnyin kò gbọdọ ṣaima tẹriba, kì iṣe nitoriti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkàn pẹlu. Nitori idi eyi na li ẹ ṣe san owo-ode pẹlu: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni wọn eyi yi na ni wọn nbojuto nigbagbogbo. Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀rù fun ẹniti ẹ̀rù iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀."

Àyọkà yìí fihàn kedere l'ọ́pọ̀lọpọ̀ wípé a gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí ìjọba tí Ọlọ́run fi lé wa lórí. Ọlọ́run ṣẹ̀dá ìjọba láti fi ètò, ìjìyà ibi, àti ìgbé lárugẹ òdodo kalẹ̀ (Jẹnẹsisi 9:6; 1Kọrinti 14:33; Romu 12:8). Àwa ńni láti gbọ́ràn sí ìjọba nínú ohun gbogbo, sísan owó-orí, gbígbọ́ràn sí àwọn òfin àti àṣẹ, àti bíbọ̀wọ̀. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ní ìkẹhìn àwa kò bu ọlá fún Ọlọ́run, nítorí Òun ni Ẹni náà tí ó gbé ìjọba yẹn lórí wa. Nígbàtí àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ara Romu, òun wà lábẹ́ ìjọba Romu nígbà ìjọba Nérò, èyí tí ó jẹ́ ìjọba Romu tí ó fẹ́ẹ̀ burú jùlọ. Pọ́ọ̀lù ṣì tún rí àkóso ìjọba Romu lórí rẹ̀. Báwo ni àwa yóò ṣe sẹ ohun tí ó kéré sí èyí?

Ìbéèrè tí yóò tẹ̀le ni "Ṣé ìgbà kan wà nígbàtí àwa gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ọ́ ṣe àìgbọràn sí àwọn òfin ilẹ̀?" Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn ni a lè rí ní Ìṣe àwọn Apọsteli 5:27-29 "Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn léèrè, Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹyin ti fi ẹ̀kọ́ yin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa. Ṣugbọn Peteru ati awọn apọsteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ." láti ibíyìí, ó hàn kedere wípé níwọ̀n ìgbà tí òfin ilẹ̀ wa kò bá tako òfin Ọlọ́run, àwa wà lábẹ́ kí a gbọ́ràn sí òfin ilẹ̀ wa. Ní kété tí òfin ilẹ̀ wa bá ti tako àṣẹ Ọlọ́run, àwa ńní láti ṣe àìgbọràn sí òfin ilẹ̀ wa náà kí a sì gbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwa gbọ́dọ̀ gba àṣẹ ìjọba lórí wa. Èyí ni a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nípa òtítọ́ wípé Peteru àti Johannu kò tako nínà, ṣùgbọ́n dípò wọ́n yọ̀ wípé wọ́n jìyà fún gbígbọ́ràn sí Ọlọ́run (Iṣe àwọn Apọsteli 5:40-42).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣe àwọn Kristiẹni nńí láti gbọ́ràn sí àwọn òfin ilẹ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries