settings icon
share icon
Ibeere

Ìtumọ́ àlá Kristiẹni? Ṣé àwọn àlá wa ti ọwọ́ Ọlọ́run wá?

Idahun


Àjọ GotQuestions.org kìí ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ àlá Kristiẹni. Àwa kìí ìtumọ̀ àwọn àlá. Àwa gbàgbọ́ wípé àwọn àlá ẹnìkan jẹ́ tirẹ̀ ti ìtumọ̀ àwọn àlá wọ̀nyẹn wà láàrin ẹni náà àti Ọlọ́run nìkan. Ní àtijọ́, Ọlọ́run máa ńbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú àwọn àlá. Àwọn àpẹẹrẹ ni Jósẹ́fù, ọmọ Jakọbu (Jẹnẹsisi 37:5-10); Jósẹ́fù, ọkọ Maria ( Matteu 2:12-22); Sọlomọni (1 Àwọn Ọba 3:5-15); àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míìrán (Daniẹli 2:1; 7:1; Matteu 27:19). Àsọtẹ́lẹ̀ wòólì Joẹli kan tún wà (Joẹli 2:28), èyí tí àpọ́stélì Peteru tún sọ ní Ìṣe àwọn Apọsteli 2:17, tí ó mẹ́nuba Ọlọ́run tí Ó lo àlá. Nítorí náà, Ọlọ́run lè sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn àla bí Òun bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣùgbọ̀n àwa gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn wípé Bíbélì pé, ní wípé o ti fi ohun gbogbo tí a ní láti mọ̀ láti ìsínsìnyí dé ayérayé hàn. Èyí kò túmọ̀ sí wípé Ọlọ́run kìí ṣe iṣẹ́ ìyanu tàbí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn àlá lónìí pàápàá, ṣùgbọ́n ohunkóhùn tí Ọlọ́run bá sọ, bóyá nípasẹ̀ àlá, ìran, gbígbìn nǹkan síni lọ́kàn, tàbí "ohùn kẹ́lẹ́ kékeré," yóò bá ohun tí Òun ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mu pátápátá. Àwọn àlá kò lè gba ipò iṣẹ́ ti Ìwé Mimọ́.

Bí o bá lá àlá kan tí o lérò wípé Ọlọ́run fi fún ọ, gbée yẹ̀wò pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa àdúrà kí o sì ríi dájú wípé àlá rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Bí o bá rí bẹ́ẹ̀, wo ohun tí Ọlọ́run yóò fẹ́ kí o ṣe sí àlá rẹ nípa àdúrà (Jakọbu 1:5). Nínú Ìwé Mímọ́, nígbàkuugbà tí ẹnikẹ́ni bá ti ní ìrírí àlá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run máa ńjẹ́ kí àlá náà hàn kedere nígbàgbogbo, bóyá ní tààrà sí ẹni náà, nípasẹ̀ ańgẹ́lì, tàbí nípasẹ̀ òjíṣẹ́ míìrán (Jẹnẹsisi 40:5-11; Daniẹli 2:45; 4:19). Nígbàtí Ọlọ́run bá ńbá wa sọ̀rọ̀, Òun yóò ríi dájú wípé ìfiráńṣẹ́ Rẹ̀ yéni kedere.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ìtumọ́ àlá Kristiẹni? Ṣé àwọn àlá wa ti ọwọ́ Ọlọ́run wá?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries