settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa kí Kristiẹni máa jẹ gbèsè? Ṣé ó yẹ kí Kristiẹni yá tàbí jẹ owó?

Idahun


Ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù sí wa nínú ìwé Rómù 13:8 ni láti máṣe jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohun kan, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní ìrántí tí ó lágbára nípa bí Ọlọ́run ṣe kóríra gbogbo irú gbèsè tí ó jẹ́ wípé wọn kò san ní àsìkò tí ó yẹ (tún wo Orin Dafidi 37:21). Bákannáà, Bíbélì kò pàṣẹ kedere fún wa lòdì sí onírúurú gbèsè jíjẹ. Bíbélì lódì sí gbèsè, ó sì gbé ìwà àìwọ inú gbèsè lárugẹ, ṣùgbọ́n kò tako gbèsè. Bíbélì ní ọ̀rọ̀ ẹ̀bi líle fún àwọn ayánilówó tí wọ́n ṣe àṣìlò àwọn tí ó jẹ wọ́n ní gbèsè, ṣùgbọ́n kò dá àwọn ajigbèsè lẹ́bi.

Àwọn ènìyàn kan tako gbígba èlé lórí owó tí a yá, ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì a rí wípé èlé kékeré ni ó yẹ láti gbà lórí owó tí a yá (Òwe 28:8; Matteu 25:27). Ní Isrẹli àtijọ́ Òfin kò faramọ́ gbígba èlé lórí ìṣọ̀rí owó tí a yá kan—èyí tí a ṣe fún àwọn aláìní (Lẹfitiku 25:35-38). Òfin yìí ní ọ̀pọ̀ àyọrísí l'áwùjọ, l'étò ìṣúná àti l'ẹ́mìí, ṣùgbọ́n méjì ṣe pàtàkì láti mẹ́nubà. Àkọ́kọ́, òfin náà ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ní tòótọ́ nípa wípé kí ìṣòrò wọn má baà burú si. O tí burú tó láti bọ́ sínú àìní àtí wípé ó tini lójú láti wá ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí, ní àfikún pẹ̀lú sísan owó yíyá padà, aláìní bá ní láti san èlé tí ó ga, ojúṣe yí yóò ṣe àkóbá fun ju ìrànlọ́wọ́ lọ.

Ẹ̀kejì, òfin yìí ńkọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀mí pàtàkì. Fún ayánilówó láti fojú fo èlé lórí owó tí a yá aláìní yóò jẹ́ ìṣe àánú. Òun yóò pàdánù lílo owó náà nígbà tí ó yáa síta. Síbẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀nà gidi láti fi ìmore hàn sí Ọlọ́run fún àánú Rẹ̀ bí kò ṣe gba "èlé" lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ fún ore-ọ̀fẹ́ tí Òun fi hàn sí wọn. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti fi àánú mú àwọn ọmọ Isrẹli jáde kúrò ní Íjíbítì nígbà tí wọn ò já mọ́ nǹkankan, bíkòṣe òtòṣì ẹrú tí ó sì fún wọn ní ilẹ̀ ti wọn (Lẹfitiku 25:38), nítorí náà ó réti wọn láti ṣe irú ojú rere bẹ́ẹ̀ sí àwọn òtòṣì ọmọ ìlú.

Kristiẹni wà ní irú ipò yìí. Ìgbé-ayé, ikú àti àjíǹde Jésù ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Ọlọ́run. Nísinsìyí, bí a ṣe ní àǹfàní, a le ran àwọn míìrán lọ́wọ́ nínú àìní wọn, ní pàtàkì àwọn onígbàgbọ́ bí tiwa, pẹ̀lú owó yíyá tí kò dákún ìṣòro wọn. Jésù tilẹ̀ pa òwe nípa èrò yìí nípa ayánilówó méjì àti ìhà tí wọ́n kọ sí ìdáríjì (Matteu 18:23-35).

Bíbélì kò takò yíyá owó bẹ́ẹ̀ni kò fàyè gbàá. Ọgbọ́n inú Bíbélì kọ́ wa pé kìí ṣe àbá tí ó dára nígbà gbogbo láti máa jẹ gbèsè. Gbèsè máa ńjẹ́ kí á di ẹrú ẹni tí ó pèsè owó tí a yá. Nígbà kannáà, ní ìgbà míìrán wíwọ inú gbèsè jẹ́ "ibi tí ó wúlò." Níwọ̀n ìgbà tí a bá ná owó pẹ̀lú ọgbọ́n, tí gbèsè sísan náà kò sì kọjá àfaradà, onígbàgbọ́ lè gbé àjàgà gbèsè owó wọ̀ tí ó bá pọn dandan.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa kí Kristiẹni máa jẹ gbèsè? Ṣé ó yẹ kí Kristiẹni yá tàbí jẹ owó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries