settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn bàbá Kristiẹni?

Idahun


Òfin tí ó ga jùlọ nínú Ìwé Mímọ́ ni èyí: "Kí iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ OLUWA Ọlọ́run rẹ" (Deutarọnọmi 6:5). Bí a bá padà sí ẹsẹ kejì (2), a ó kà wípé,"kí ìwọ ó lè ma bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti pa gbogbo ìlànà rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, tí èmi fi fún ọ, ìwọ àti ọmọ rẹ , àti ọmọ ọmọ rẹ, ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo; kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́". Ní títẹ̀lé Deutarọnọmi 6:5, a kà wípé," Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo palaṣẹ fún ọ ní òní, kí ó ma wà kí àyà rẹ: kí ìwọ ó sì fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ ó sì ma fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ ìsọ nígbàtí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbàtí ìwọ bá ńrìn ní ọ̀nà, àti nígbàtí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbàtí ìwọ bá dìde" (ẹsẹ 6 sí 7).

Ìtàn Isrẹli fihàn wípé bàbá gbọdọ̀ fi àìṣèmẹ́lẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ní ọ̀nà àti ọ̀rọ̀ Olúwa fún ìdàgbà nínú ẹ̀mí àti ìlera ara wọn. Bàbá náà tí ó gbọràn sí àṣẹ inú Ìwé Mímọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Èyí mú wa lọ sí ìwé Òwe 22:6, " Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yíó tọ̀, nígbàtì ó sì dàgbà tán , kì yó ò kúrò nínú rẹ̀". Láti "tọ́" tọ́kasí òfin àkọ́kọ́ tí bàbá àti ìyá fún ọmọ, tí í ṣe, ẹ̀kọ́ òwúrọ̀. A gbé ìkọ́ni náà kalẹ̀ láti lè fihàn àwọn ọmọ kedere irú ayé tí á dá wọn fún. Láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ òwúrọ̀ ọmọdé ní ọ̀nà yìí ṣe pàtàkì.

Efesu 6:4 jẹ́ àkójọ òfin fún bàbá, tí a sọ ní ọ̀nà tí ó léwu àti dára dára. "Àti ẹ̀yin Bàbá, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú: ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa." Ipa tí ó léwu nínú ẹsẹ yìí tọ́kasí wípé bàbá kò gbọ́dọ̀ fi ohun búburú tọ́ ọmọ nípa líle, àìṣododo, ojúṣáájú, tàbi lílo àṣẹ láì ní ìdí. Ọ̀nà líle, ìwà tí kò tọ́ sí ọmọ yóò gbin ibi sí ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ yìí, "bínú" túmọ̀ sí "ni lára, fi sú, fi kọ́ ní ọ̀nà tí ó burú tàbí ru inú." Èyí jẹ́ nípa ẹ̀mí búburú àti ọ̀nà búburú—líle, àìlọ́pọlọ, àìletẹ̀, àìláàánú, ìbéèrè ohun tí ó le, ìhámọ́ gágá tí kò wúlò àti ìtẹnumọ́ ìmọtaraẹni nìkan lórí àṣẹ. Irú ìbínú yìí yóò bí ìhùwàsí búburú, yóò pa ìfẹ́ nínú àwọn ọmọ, yóò dín ìpòǹgbẹ wọn fún ìwà mímọ́ kù, àti wípé yóò mú wọn lérò wípé wọn kò lè tẹ́ àwọn òbí wọn lọ́rùn. Ọlọgbọ́n òbí yóò wá láti mú kí ìgbọràn wuni, kí ó sì ṣeé ṣe nípa ìfẹ́ àti ìwà pẹ̀lẹ́.

Ipa tí ó dára nípa Efesu 6:4 ni ó jẹ yọ ní ọ̀nà tí ó yé ni yékéyéké—kọ́ wọn, mú wọn dàgbà, jẹ́ kí wọn dàgbà ní gbogbo abala ayé nípa àmọ̀ràn àti ìgbani ní ìyànjú nínú Olúwa. Èyí jẹ́ ìlànà tí ó pé láti kọ́ àti bániwí. Ọ̀rọ̀ yìí, "ìgbani ní ìyànjú" gbé èrò rírán ọmọ létí nípa àṣìṣe (ní ọ̀nà tí ó ńgbéniró) àti ojúṣe (àwọn iṣẹ́).

Bàbá Kristiẹni jẹ́ ohun-èlò tòótọ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Gbogbo ọ̀nà àmọ̀ràn àti ìbániwí gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí Ọlọ́run pàṣẹ, tí ó sì ṣe ìṣàkósó lé lórí, kí àṣẹ Rẹ̀ lè wà nígbà gbogbo àti lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ìbárakínra pẹ̀lú àyà,ọkàn, àti ẹ̀rí ọkàn àwọn ọmọ. Bàbá nípa ara kò gbọ́dọ̀ gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ bíi olórí aláṣẹ tí ó ńpinnu òtítọ́ àti ojúṣe. Ó jẹ́ nípa jíjẹ́ kí Ọlọ́run nìkan tíí ṣe olùkọ́ àti olùdarí, lábẹ́ àṣẹ ẹnití a ńṣe ohun gbogbo tí èrèdí ẹ̀kọ́ sì fi lè wá sí ìmúṣe.

Martin Luther sọ wípé, "Pa èso àpù mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹgba láti fun-un nígbà tí ó bá ṣe dáradára." A gbọ́dọ̀ ṣe ìbániwí pẹ̀lú ìtọ́jú tí ó ní ìṣọ́ra àti ìtọ́ni lemọ́lemọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àdúrà. Ìbániwí, ìtọ́nisọ́nà àti àmọ̀ràn nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fífún ni ní ìbáwí àti ìmísí jẹ́ ààrin gbùngbùn "ìgbaniníyànjú." Ìtọ́ni náà wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì lé kọ ní ilé-ẹ̀kọ́ ìrírí ti Kristiẹni, èyítí àwọn òbí ńṣe ìṣàkóso—ní pàtàkì bàbá, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìyá, lábẹ́ ìdarí bàbá. A nílò ìbániwí Kristiẹni láti lè jẹ́ kí àwọn ọmọ dàgbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìbọ̀wọ̀ fún àṣẹ òbi, ìmọ̀ òṣùwọ̀n Kristiẹni, àti ìwà ìkóra-ẹniníìjánu.

"Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbáni-wí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo"(2 Timoteu 3:16-17). Ojúṣe àkọ́kọ́ bàbá ni láti mú kí àwọn ọmọ faramọ́ Ìwé Mímọ́. Ọ̀nà àtí ohun-èlò tí àwọn bàbá lè lò láti kọ́ òtítọ́ Ọlọ́run lè yàtọ̀ sí arawọn. Bí bàbá ṣe jẹ́ olótítọ́ sí ní àwòkọ́ṣe, ohun tí àwọn ọmọ bá kọ́ nípa Ọlọ́run, yóò fi wọn sí ipò tí ó dára títí gbogbo ọjọ́ ayé wọn, ohunkóhun tíwọn ì báà ṣe tàbí ibikíbi/ibi yòówù tí wọn ìbáà lọ.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn bàbá Kristiẹni?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries