settings icon
share icon
Ibeere

Ààwẹ̀ Kristiẹni — kínni Bíbélì sọ?

Idahun


Ìwé Mímọ́ kò pàṣẹ wípé kí Kristiẹni gbààwẹ̀. Ọlọ́run kò nílò tàbí bèére rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Kristiẹni. Ní ìgbà kańnáà, Bíbélì fi ààwẹ̀ gbígbà hàn bíi nǹkan tí ó dára, níye lórí, tí ó sì ṣe ni ní ànfààní. Ìwé Iṣẹ awọn Apọsteli ṣe àkọsílẹ̀ àwọn onígbàgbọ̀ tí wọn ńgbààwẹ̀ kí wọn tó ṣe ìpinnu tí ó ṣe pàtàkì (Iṣẹ awọn Apọsteli 13:2, 14:23). Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àsopọ̀ wa láàrin ààwẹ̀ àti àdúrà (Luku 2:37; 5:33). Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ààwẹ̀ gbígbà ńtẹjúmọ́ àísí oúnjẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ète ààwẹ̀ gbígbà gbọ́dọ̀ jẹ́ láti mú ojú rẹ kúrò ni àwọn nǹkan ayé láti tẹjúmọ́ Ọlọ́run pátápátá. Ààwẹ̀ gbígbá jẹ́ ọ̀nà láti fihan Ọlọ́run, àti àwa, wípé a mú àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run ní òkúnkúndùn. Ààwẹ̀ gbígbá ńràn wá lọ́wọ́ láti ní ìwò titun àti ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ ọ̀tun lóri Ọlọ́run.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé ààwẹ̀ gbígbá nínú Ìwé Mímọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà jẹ́ ààwẹ̀ gbígbà oúnjẹ, àwọn ọ̀nà míìrán wà láti gba ààwẹ̀. Ohunkóhun tí a fi sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti darí gbogbo ìwò wa sórí Ọlọ́run ni a le pè ní ààwẹ̀ (1 Kọrinti 7:1-5). Ààwẹ̀ gbígbà gbọ́dọ̀ wa fún àkókò kan, pàápàá nígbàtí a bá ńgba ààwẹ̀ oúnjẹ. Àkókò tí ó gùn láì jẹun lè fa ìjàǹbá fún ara. Ààwẹ̀ gbígbá kò sí fún láti jẹ ara ni ìyà, ṣùgbọ́n láti tún ni darí sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ààwẹ̀ gbígbá ni a kò gbọdọ̀ rí bíi "ọ̀nà dídín oúnjẹ jíjẹ kù" Ète ààwẹ̀ gbígbá tí ó bá bíbélì mu kìí ṣe láti dín ìwọ̀n kù, ṣùgbọ́n láti ní ìdàpọ̀ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹnikẹ́ni ni o le gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn míìrán le ma lè gbààwẹ̀ oúnjẹ (fún àpẹẹrẹ, àwọn tí wọn ni ìtọ̀ ṣúgà). Gbogbo ènìyèn lè fi ohun kan sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti lè súnmọ́ Ọlọ́run.

Nípa gbígbé ojú wa kúrò lára àwọn nǹkan ayé yìí, àwa lè ní àṣeyọrí síwájú síi láti darí ìwò wa sí Kristi. Ààwẹ̀ gbígbá kìí ṣe ọ̀nà láti mú kí Ọlọ́run ṣe oun ti àwa bá fẹ́. Ààwẹ̀ gbígbá ńyí wa padà, kìí ṣe Ọlọ́run. Ààwẹ̀ gbígbá kìí ṣe ọ̀nà láti dàá wípé a jẹ́ ẹni ẹ̀mí ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Ààwẹ̀ gbígbá ni a ńní láti ṣe pẹ̀lú ẹmí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà àyọ̀. Matteu 6:16-18 sọ wípé, "Ati pẹlu nigbati ẹyin ba ngbaàwẹ, ẹ maṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; wọn a ba oju jẹ, nitori ki wọn ki o ba le farahan fun eniyan pe wọn ńgbaàwẹ. Lootọ ni mo wi fun yin, wọn ti gba èrè wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ńgbaàwẹ, fi ororo kun ori rẹ, ki o si bọju rẹ ki iwọ ki o maṣe farahan fun enia pe iwọ ńgbaàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o nbẹ ni ìkọ̀kọ̀; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọ̀kọ̀ yóò san a fun ọ ni gbangban."

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ààwẹ̀ Kristiẹni — kínni Bíbélì sọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries