settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìjọ?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lónìí mọ̀ ìjọ gẹ́gẹ́ bí ilé tí a kọ́ kan. Èyí kìí ṣe ìmọ̀ Bíbélì nípa ìjọ. Ọ̀rọ̀ náà "ìjọ" wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríkì ekklesia èyítí ó túmọ̀ sìí "àpéjọpọ̀" tàbí àwọn tí a pè." Gbòǹgbò ìtumọ̀ "ìjọ" kìí ṣe ti ilé tí a kọ́, ṣùgbọ́n ti ènìyàn. Kàyéfì ló jẹ́ bí o bá bi àwọn ènìyàn léérè ìjọ tí wọ́n ńlọ, wọ́n má ńsábà dárúkọ ilé tí a kọ́ kan. Romu 16:5 sọ wípé "Ẹ sì kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn." Pọ́ọlù tọ́ka sí ìjọ ní ilé wọn–kìí ṣe ilé tí a kọ́, ṣùgbọ́n ara àwọn onígbàgbọ́.

Ìjọ jẹ́ ara Kristi, èyítí Òun jẹ́ Orí fún. Efesu 1:22-23 sọ wípé, "Ó sì fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ti fi i se orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyítí íse ara rẹ̀, ẹ̀kún ẹnití ó kún ohun gbogbo nínú ohun gbogbo." Gbogbo onígbàgbọ́ jùmọ̀ jẹ́ ara Krístì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Pẹ́ntikọ́siti (Iṣe àwọn Apọsteli 2) títí di ìpadàbọ̀ Kristi. Ara Kristi pín sí apá méjì:

1) Ìjọ àgbáyé ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristi. "Nítorípé nínú Ẹ̀mí kan li a ti baptisi gbogbo wa sínú ara kan, iba ṣe Ju, tàbí Hellene, iba ṣe ẹrú, tàbí ominira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹ̀mí kan" (1 Kọrinti 12:13). Ẹsẹ̀ yí sọ wípé ẹnití ó bá gbàgbọ́ jẹ́ ara Kristi tí òun sí ti gba Ẹ̀mí ti Kristi bíi ẹ̀rí. Ìjọ àgbáyé tí Ọlọ́run ni gbogbo àwọn tó gba ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.

2) Àpèjúwe ìjọ agbègbè wà nínú Galatia 1:1-2: "Pọ́ọ̀lù, àpọ́stélì" àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ Galatia." Ní ibì yìí a rí wípé ní agbègbè Galatia ọ̀pọ̀ ìjọ ló wà níbẹ̀–èyítí a le pè ní àwọn ìjọ agbègbè. Ìjọ Onítẹ̀bọmi, Ìjọ Lútérànù, Ìjọ Àgùdà, abbl., kòní ìjọ, gẹ́gẹ́ bi ìjọ àgbáyé–bíkòṣe ìjọ agbègbè, ara àwọn onígbàgbọ́ tí agbègbè. Ìjọ àgbáyé jẹ́ ti àwọn tó jẹ́ ti Kristi àti àwọn tí ó gbà Òun gbọ́ fún ìgbàlà. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìjọ àgbáyé wọ̀nyìí gbọ́dọ̀ wá ìdàpọ̀ àti ìmúdúró nínú ìjọ agbègbè kan.

Ní àkótán, ìjọ kìí ṣe ilé kan tí a kọ́ tàbí ẹ̀yà ijọ kan. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, ìjọ jẹ́ ara Kristi—gbogbo àwọn tó gbé ìgbágbọ́ wọn lé Jésù Kristi fún ìgbàlà. (Johannu 3:16, 1 Kọrinti 12:13). Ìjọ agbègbè jẹ́ àpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn tó ńpe orúkọ Kristi. Àwọn ọmọ ìjọ agbègbè le jẹ́ tàbí má jẹ́ ọmọ ìjọ àgbáyé, èyí dálé ojúlówó ìgbàgbọ́ wọn. Ìjọ agbègbè ni ibití onígbàgbọ́ tí le lo àwọn ìlànà "ara" ti Kọrinti kínní 12: ìgbani n'íyànjú, ìkọ́ni, àti gbígbé ara ẹni sókè nínú ìmọ̀ àti ore-òfẹ́ Jésù Kristi Olúwa.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìjọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries