settings icon
share icon
Ibeere

Ki ni o de ti emi o se le pa ara mi?

Idahun


Anu mi si se gbogbo awon ti won ti ro lati pa ara won. Ti iwo ba ro be, orisirisi ni iwo yi o ma ro, bi aini ireti ati ibanuje. Iwo yio si ro wipe, iwo wa ninu iho ti o jin, iwo o si ro wipe ko si atunes fun ile aye re. Ko si eni ti o mo tabi ti o fe ran e lowo. Ile aye yi ko wulo fun o mon…. Nje be ni?

Iru emi kemi yi ma n wa si okan wa ni igbaki gba. Iru ibere ti o ma n wa si okan mi, ti emi ba wa ninu ironu, “nje ise ti Olorun ni eyi, tani o da mi?” “nje Olorun yi kere lati ran mi lowo?” Nje iponju ti mo wa yi tobi ju fun?”

Inu mi dun lati so fun o wipe, nje ti iwo ba fun Olorun ni aye lati wa si inu okan rre nisisiyi, yio si fi han o bi ose tobi to! “ ko si ohun kan ti Olorun ko le se” (Luku 1;37). Tabi ohun ti o ti sele si o tele si ti wa ni okan re ti o si ro wipe ko si atunes. O si je ohun ibaunje ti o si je ki awon enia sa fun o. Gege be naa, eyi yi o mu ibanuje ati irora ayeraye ba awon ti o feran re ti iwo ba pa ara re.

Kini ode ti iwo yio fi pa ara re? Ore, ko si bi o ti le ni iponju to ninu aye re, Olorun kan wa ti o ni ife re, ti o si n duro de o lati mu o si ona, ati jade kuro si inu ina iyanu re. Ohun ni ireti re, oruko re ni Jesu.

Jesu yi, alaidese omo Olorun, yi o wa pelu re ninu iponju. Woli Isaiah ko nipa re, “Nitori yio dagba re bi ojele ohun ogbin, ati bi gbongbo lati inu ile gbigbe; irisi re ko dara, beni ko li ewa, nigbati a ba si ri i, ko li ewati a ba fi fe e. a kegan re a si ko o lodo awon enia, eni-ikanu, ti o si mo ibanuje: o si dabi enipe o mu ki a pa oju w amo kuro lara re; a kegan re, awa ko si ka a si. Loto o ti ru ibanuje wa, o si gbe ikanu wa lo; sugbon waw ka a si bi eniti a na, ti a lu lati odo Olorun, ti a si pon Loja. Sugbon a sal i orbe nitori irekoja wa, a pa a li ara nitori aisedede wa; ina alafia wa wa lara re, ati nipa ina re li a fi mu wa lara da. Gbogbo wa ti sina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tele ona ara re; Oluwa si ti mu aisedede wa gbogbo pade lara re” (Isaiah 53: 2-6).

Ore, gbogbo iya yi ni Jesu Kristi je ki gbogbo ese re le je idariji! Ohun ese ti iwo baru, mo wipe yio dari ese re ji o ti iwo ba bere fun idariji ese (yi pada kuro ninu ese re, ki o wa si odo Olorun). Pe mi nigba iponju, emi yio si gba o la, iwo yi o gbe mi ga (Orin Dafidi 50:15). Ko si ohun ti o ti se ti o soro fun Oluwa tali dariji. Awon omo leyin re ninu Bibeli da ese orisirisi, bi pipa enia (Mose), agbere (Dafidi), ati iya emi ati ara (Aposteli Paulu). Be naa, won ri idariji ese pelu igbesi aye titán ninu Oluwa. We mi li awemo kuro ninu aisedede mi, ki o si we mi un kuro ninu ese mi” (Orin Dafidi 51:2). Nitorina, bi enikeni wa ba ninu Kristi, o di eda titán: ohun atijo ti koja lo: kiyesi i, nwon si di titán” (2 Korinti 5:17).

Ki ni o de ti iwo yi o fi pa ara re? Ore, Oluwa n pe lati tun ile aye re se……, bi igbesi aye re ni sin yi, ti o si pa ara re. Iwe woli Isaiah so wipe: “Emi Oluwa Jehofah mbe lara mi: nitori o ti fi ami ororo yan mi lati wasu ihin-rere fun awon otosi; o ti ran mi lati se awotan awon onirobinuje okan, lati kede idasile fun awon igbekun, ati isisile tubu fun awon onde. Lati kede Odón itewogba Olorun, ati ojo esan Olorun wa; lati tu gbogbo awon ti ngbawe ninun. Lati yan fun awon ti nsofo fun Sioni, lati fi oso fun won nipo eru, ororo ayo nipo ofo, aso iyin nipo emi ibanuje, ki ale pe won ni igi ododo, ogbin Oluwa, ki a le yin i logo” (Isaiah 61:1-3).

Wa si odo Jesu, ki o je ki o fun o ni ireti ati ilo re, bi iwo ba se gbagbo ninu re wipe ki o se atunse. “ Mu ayo igbala re pada to mi wa; ki o si fi emi ominira re gbe mi duro. Oluwa, iwo si mi li ete; enu mi yio si ma fi iyin re han: Nitori iwo ko fe ore-ebo sisun. Ebo Olorun ni irobinuje okan: irobinuje ati irota aiya, Olorun, on ni iwo ki yio gan” (Orin Dafidi 51:12, 15-17).

Nje iwo yio gba Olorun olugbala ati olutana re gbo. Yio mu o mona, die die ninu oro re ati Bibeli. “Emi o fi ese re le ona, emi o si ko o li ona ti iwo o rin: emi o ma fi oju mi to o (Orin Dafidi 32:8). “On o si je idurosinsin akoko re, isura igbala, ogbon ati imo; iberu Oluwa ni yio je isura re” (Isaiah 33:6). Ninu Kristi, iwo yi o ni lati según orisirisi, sugbon iwo yi o ni IRETI. “Ore” kan si mbe ti o fi ara moni ju arakonrin lo” (Owe 18:24). Ki ore-ofe Oluwa Jesu ki o wa pelu re bi iwo ba se ni imoran re si.

Ti iwo ba ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala re, so oro won yi ninu okan re si Olorun. “Olorun, mo fe o ninu aye mi. Dariji gbogbo ese mi mi ji mi, mo si ni igbagbo ninu Jesu Kristi, mo si gbagbo wipe ohun ni olugbala mi. Jowo we mi, wo mi san, ki o si fun mi ni ayo mi pada. E se fu nife ti e ni si mi ati fun iku Jesu ti o ku fun mi.”

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ki ni o de ti emi o se le pa ara mi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries