settings icon
share icon
Ibeere

Kílódé tí a fí ńgbàdúrà? Kínní kókó tí a fí ńgbàdúrà nígbatí Ọlọ́run ti mọ ọjọ́ iwájú tí ó sì ti wà náà ní ṣíṣe àkoso ohun gbogbo. Bí a kò bá lè yí ọkàn Ọlọ́run padà, kílodé tí àwa fi gbọ́dọ̀ gbàdúrà?

Idahun


Fún Kristiẹni, àdúrà gbígbà yẹ kó jẹ́ bíi mímí, tí ó rọrùn láti ṣe ju láti má ṣe lọ. A má ńgbàdúrà fún oríṣiríṣi àwọn ìdí. Fún ohun kan, àdúrà jẹ́ oríṣí ọ̀nà tí à ńgbà sin Ọlọ́run (Luku 2:36-38) àti gbìgbọ́ràn si Òun. Àwa ńgbàdúrà nítorí wípé Ọlọ́run páa l'áṣẹ láti gbàdúrà (Filippi 4:6-7). Àdúrà ní a ṣe àpèjúwe fún wa nípa Kristi àti ìjọ àkọ́kọ́ náà (Marku 1:35; Iṣe Awọn Apọsteli 1:14; 2:42; 3:1; 4:23-31; 6:4; 13:1-3). Bí Jésù bá lérò wípé ó dára láti gbàdúrà, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bì Òun bá nìlò láti wà nínú ìfẹ́ ti Baba náà, mélòmélò ni àwa náà nílò láti gbàdúrà?

Ìdí míìrán láti gbàdúrà ní wípé Ọlọ́run pinnu àdùrà láti jẹ ọ̀nà láti rí gbà àwọn ọ̀nà-àbáyọ Rẹ̀ nínú àwọn ipò mélò kan. Àwa ńgbàdúrà ní ìpalẹ̀mọ́ fún àwọn ìpinnu tí ó ṣe pàtàkì (Luku 6:12-13); láti borí àwọn ìdènà èṣù (Matteu17:14-21); láti kó àwọn òṣìṣẹ́ jọ pọ̀ fún ìkórè ti ẹ̀mí (Luku 10:2); láti jogún okun fún bíborí ìdánwò (Matteu 26:41; àti láti le rí gbà ọ̀nà sí fífi okun fún ẹlòmíràn nípa t'ẹ̀mí (Efesu 6:18-19).

A wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ìbéèrè kan ní pàtó, a sì tùn ní ìlérí Ọlọ́run wípé àwọn àdúrà wa kò já s'ásán kó dà bí a kò bá rí gbà ohun náà ní pàtó tí a bérè fún (Matteu 6:6; Romu 8:26-27). Òun ti ṣe ìlérí wípé nígbàtí àwa bá béèrè gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Rẹ̀, Òun yóò fún wa ni ohun ti àwa bá béèrè fún (1 Johannu 5:14-15). Nígbà míìrán Òun máa ńdá àwọn ìdáhùn Rẹ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n Rẹ̀ àti fún àǹfàní wa. Nínú àwọn ipò wọ̀nyìí, àwa gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ṣe aápọn àti tí ó tẹramọ́ àdúrà (Matteu 7:7; Luku 18:1-8). A kò gbọ́dọ̀ rí àdúrà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ti wa láti mú Ọlọ́run ṣe ìfẹ́ ti wa lórí ayé, ṣùgbọ́n dípò ọ̀nà mímú ìfẹ́ ti Ọlọ́run di ṣíṣe lóri ayé. Ọgbọ́n Ọlọ́run kọjá ọgbọ́n wa.

Fún àwọn ipò tí a kò mọ ìfẹ́ Ọlọ́run ní pàtó, àdúrà jẹ́ ọ̀nà tí a fí ńdá ìfẹ́ Rẹ̀ mọ̀ yàtọ̀. Bí obìnrin ará Síríà náà pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀ tí à nti ipa ẹ̀mí èṣù dari náà kò bá ti gbàdúrà sí Kristi, ara ọmọbìnrin rẹ̀ kì bá ti dá (Marku 7:26-30). Bí ọkùnrin afọ́jú l'óde Jẹ́ríkò kò bá kígbe jáde sí Kristi, òun kò bá wà ní afọ́jú síbẹ̀ (Luku 18:35-43). Ọlọ́run ti sọ wípe a má ńlọ láìní nítorí a kò béèrè (Jakọbu 4:2). Ní ọ̀rọ̀ kan tí ó mọ́gbọ́n dání, àdúrà dà bi pínpín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ènìyàn. Àwa kò mọ ẹni tí yóò fèsì sí ìfiráńṣẹ́ ti ìhìnrere náà à fì bí àwa bá ṣe àjọpín rẹ̀. Ní ọ̀nà kańnáà, àwa kò ní rí àwọn esì ìdáhùn sí àdúrà àyààfi bí a bá gbàdúrà.

Aìlègbàdúrà ńṣe àfihàn àìgbàgbọ́ àti àìnígbẹ̀kẹ̀lé nínú Ọ̀rọ̀ ti Ọlọ́run. Àwa ǹgbàdúrà láti ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run, wípé Òun yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti láti bùkún wa l'ọ́pọ̀lọpọ̀ ju bí a ti le béèré lọ tàbí ní ìrètì fún (Efesu 3:20). Àdúrà jẹ́ ọ̀nà wa àkọ́kọ́ fún rírí iṣẹ́ Ọlọ́run nínú ayé ẹlòmíràn. Nítorí wípé ó jẹ́ ọ̀nà tí à ǹgbà "ń so pọ̀ wọnú" agbára ti Ọlọ́run, o jẹ́ ọ̀nà fún wa láti borí Sátánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wípé a kò lágbára láti borí nípa tìkalára wa. Nítorínáà, kí Ọlọ́run ṣe àwárí wa lóòrèkóòrè níwájú ìtẹ Rẹ̀, nítorí a ní olórí àlúfà ní ọ̀run tí kò lè ṣai ba wa kẹdun ninu ailera wa (Heberu 4:15-16). Àwa ní ìlérí Rẹ̀ wípé àdúrà olódodo ńṣiṣẹ́ agbára púpọ̀ (Jakọbu 5:16-18). Kí Ọlọ́run gbé ògo fún orúkọ Rẹ̀ nínú ayé wa bí a ṣe ńgbàgbọ́ láti tọ̀ Òun wá lóòrèkóòrè nínú àdúrà.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kílódé tí a fí ńgbàdúrà? Kínní kókó tí a fí ńgbàdúrà nígbatí Ọlọ́run ti mọ ọjọ́ iwájú tí ó sì ti wà náà ní ṣíṣe àkoso ohun gbogbo. Bí a kò bá lè yí ọkàn Ọlọ́run padà, kílodé tí àwa fi gbọ́dọ̀ gbàdúrà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries