settings icon
share icon
Ibeere

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini tako Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu — ìwò wo ni ó tọ̀nà?

Idahun


Ẹ̀kọ́ ti Kalifini àti Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu jẹ́ ètò méjì nípa ẹ̀kọ́ ìwàásù tí ó gbìyànjú láti ṣàlàyé ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin títóbi jùlọ Ọlọ́run àti ojúṣe ènìyàn nínú ọ̀rọ̀ ìgbàlà. A sọ Ẹ̀kọ́ ti Kalifini lẹ́yìn Johannu Kalifini (John Calvin), tíí ṣe olùkọ́ ẹ̀kọ́ ìwàásù tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Farasé, tí ó gbé láti ọdún 1509 di 1564. A sọ Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu lẹ́yìn Jakọbu Aminuisi (Jacobus Arminius), ọmọ orílẹ̀-èdè Nẹdalandi, tí ó gbé láti ọdún 1560 di 1609.

A lè ṣe àkójọ àwọn ètò méjèèjí yìí sí ìpín márùn ún. Ẹ̀kọ́ ti Kalifini gbàgbọ́ wípé ènìyàn díbàjẹ̀ pátápátá nígbàtí Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu gbàgbọ́ wípé ènìyàn díbàjẹ̀ díẹ̀. Ẹ̀kọ́ ti Kalifini sọ wípé gbogbo abala ìgbé-ayé ènìyàn ló díbàjẹ̀ nípaṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀; nítorí náà, ènìyàn kò lè wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ara rẹ̀. Ìdíbàjẹ̀ díẹ̀ sọ wípé gbogbo abala ìgbé-ayé ènìyàn ni ẹ̀ṣẹ̀ bàjẹ̀, ṣùgbọ́n kò dé ibi wípé ènìyàn kò lè fi ìgbagbọ́ sínú Ọlọ́run fún ara wọn. Ṣe àkíyèsí wípé: Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu ti ìgbàlódé kọ "ìdíbàjẹ̀ díẹ̀", ó sì ní ìwò tí ó súnmọ́ "ìdíbàjẹ̀ pátápátá" ti Ẹ̀kọ́ ti Kalifini (àmọ́, ibi tí ìdíbàjẹ̀ dé àti ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ àríyànjiyàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ ti Aminiasimu). Ní àpapọ̀, àwọn elérò Aminiasimu gbà wípé ipò kan wà ní "ààrin" ìdíbàjẹ̀ pátápátá àti ìgbàlà. Ní ipò yìí, tí ó ṣe é ṣe nípa ore-ọ̀fẹ́, a fa ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Kristi, tí òun sì ní agbára láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti yan ìgbàlà.

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini nííṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wípé yíyàn kò ní àmúyẹ, nígbàtí Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu gbàgbọ́ wípé yíyàn ní àmúyẹ. Yíyàn tí kò ní àmúyẹ ni ìwò wípé Ọlọ́run yan oníkálúkùù gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ nìkan, kìí ṣe lórí àbùdá ohunkóhun tí ó dára nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Yíyàn pẹ̀lú àmúyẹ sọ wípé Ọlọ́run yan oníkálúkù sí ìgbàlà nípa ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Rẹ̀ nípa ẹni tí yóo gbàgbọ́ nínú Kristi sí ìgbàlà, nípa àmúyẹ wípé oníkálúkù yan Ọlọ́run.

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini rí ètùtù bí èyí tí ó ní gbèdéke, nígbàtí Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu ríi bí éyí tí kò ní gbèdéke. Èyí ló ńfa àríyànjiyàn jù nínú ìpín márùn ún. Ètùtù tí ó ní gbèdéke ni ìgbagbọ́ wípé àwọn àyànfẹ́ nìkan ni Jésù kú fún. Ètùtù tí kò ní gbèdéke ni ìgbagbọ́ wípé Jésù kú fún gbogbo ènìyàn, ṣúgbọ́n wípé ikú rẹ̀ kò l'agbára, à fi ìgbà ti ènìyàn bá gbà Òun gbọ́ nípa ìgbagbọ́.

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini nííṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wípé ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kò ṣe é takò, nígbàtí Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu sọ wípé ènìyàn lè takò ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí kò ṣeé takò jiyàn wípé tí Ọlọ́run pe ènìyàn sí ìgbàlà, ẹni náà yóo wá sí ìgbàlà bí ó tilẹ̀ wù kórí. Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó ṣeé takò sọ wípé Ọlọ́run pe gbogbo ènìyàn wá sí ìgbàlà, ṣùgbọ́n wípé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóo takò ìpè, tí wọn yóò si kọ ìpè yìí.

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini rọ̀mọ́ ìfaradà àwọn ènìyàn mímọ́ nígbàtí Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu rọ̀mọ́ ìgbàlà tí ó ní àmúyẹ. Ìfaradà àwọn ènìyàn mímọ́ túmọ̀ sí èròǹgbà wípé ènìyàn tí Ọlọ́run bá yàn, yóò fara dàá ni ìgbagbọ́, àti pé kò ní sẹ́ Kristi pátápátá tàbí kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀. Ìgbàlà tó ní àmúyẹ ni ìwò wípé onígbàgbọ́ nínú Kristi lè padà kúrò lẹ́yìn Kríisti, tí ó bá wùú, kí ó sì pàdánù ìgbàlà. Ṣe àkíyèsí wípé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Aminíasi tako "ìgbàlà tí ó ní àmúyẹ", dípò wọ́n rọ̀mọ́ "ìdábòbò ayérayé."

Nítorí náà, èwo ni ó tọ̀nà nínú àríyànjiyàn Ẹ̀kọ́ ti Kalifini tako Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu? Ó ṣe pàtàkì kí á kíyèsi wípé nínú onírúurú ara Kristi, oríṣiiríṣi àdàlu Ẹ̀kọ́ ti Kalifini àti Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu ni ó wà. Ìpín márùn èrò Ẹ̀kọ́ ti Kalifini àti ìpín márùn èrò Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu ni ó wà, nígbà kańnáà aní ìpín mẹ́ta Ẹ̀kọ́ ti Kalifini àti ìpin méjì Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu pẹ̀lú ni ó wà. Àwọn onígbàgbọ́ kan wà láàrin àdàlu ìwò méjèèjì. Ní àkótán, ìwò ti wa ni wípé ètò méjèèjì kùnà nítorí wípé wọ́n gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tí kò ṣe é ṣàlàyé. Ọmọ ènìyàn kò ní agbára láti mọ èròǹgbà bí èyí pátápátá. Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run ló tóbi jùlọ, tí ó sì mọ ohun gbogbo. Bẹ́ẹ̀ni, a pe ènìyàn láti ṣe ìpinnu tòótọ́ láti fi ìgbàgbọ́ sínú Kristi fún ìgbàlà. Eró méjèèjì yìí kọ ẹ̀yìn sí ara wọn, ṣùgbọ́n ní ọkàn Ọlọ́run, wọ́n ní òye tí ó péye.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ẹ̀kọ́ ti Kalifini tako Ẹ̀kọ́ ti Aminiasimu — ìwò wo ni ó tọ̀nà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries