settings icon
share icon
Ibeere

Jíjẹ́ kí ìgbeyàwó pẹ́ — kínni kókó?

Idahun


Kínni nǹkan tí tọkọtaya lè ṣe láti ríi dájú wípé ìgbéyàwo wọn yóò pẹ́? Ohun àkọ́kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ọ̀kan ìgbọ́ràn sí Ọlọ̀run àti sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Èyí jẹ́ ìlànà kan tí ó gbọ́dọ̀ fìdí múlẹ̀ ṣáájú kí ìgbéyàwó náà ó tó bẹ̀rẹ̀. Ọlọ́run sọ wípé, "Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn?" (Amosi 3:3). Fún onígbàgbọ́ tí ó ti di àtúnbí, èyí túmọ̀ sí wípé kí a má ṣe bẹ̀rẹ̀ ìbáṣepọ̀ tí o ní ìfarakíni pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí kìí ṣe onígbàgbọ́ kan bákanáà. "Ẹ má ṣe fi aidọgba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìdàpọ̀ kili ododo ni pẹ̀lú àwọn alaiṣododo? Ìdàpọ̀ kini ìmọ́lẹ̀ si ni pẹ̀lú òkùnkùn?" (2 Kọrinti 6:14). Bí a bá tẹ̀lé ìlànà yìí, yóò gbà wá kàlẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbànújẹ́ àti ìjiyà lọ́jọ́ iwájú nínú àwọn ìgbéyàwó.

Ìlànà míìrán tí ó lè dáàbòbò ẹ̀mí gígùn ti ìgbéyàwó ni wípé kí ọkọ gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu kí ó sì ní ìfẹ́, kí ó bu ọlá fún ìyàwó rẹ̀ kí ó sì dáàbòbò ní bí òun yóò ṣe ṣe sí ara rẹ̀ (Efesu 5:25–31). Ìlànà míìrán tí ó wà ní ìbámu ni wípé kí ìyàwó kí ó gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu kí ó sì tẹríba fún ọkọ ara rẹ̀ "gẹ́gẹ́ bí fun Olúwa" (Efesu 5:22). Ìgbéyàwó láàrín okùnrin kan àti obìnrin kan jẹ́ àwòrán ìbáṣepọ̀ láàrin Kristi àti ìjọ. Kristi fí ara Rẹ̀ fún ìjọ tí Òun sì fẹ́ẹ, tí Òun sì ńbu ọlá fún-un, ńdáàbòbó ó gẹ́gẹ́ bíi "aya" rẹ̀ (Ifihan 19:7 — 9).

Kíkọ́ ìpìlẹ̀ ìgbeyáwo lóri ìwà bí ọlọ́run, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tọkọtaya rí àwọn ọ̀nà tí ó ṣé mú lọ sí ojúṣé láti ṣe ìrànlọ́wọ́ kí àwọn ìgbéyàwó lè pẹ́: lílo àkókò tí ó jọjú papọ̀; sísọ wípé, "Mo nífẹ̀ rẹ" lóòrékóòrè; níní inú rere; fífi ìfẹ́ hàn; mímọ rirì; jíjáde lọ; ṣiṣe àkọsílẹ̀ nǹkan; fífún ni àwọn ẹ̀bùn; àti gbígbaradì láti dáríjì, fún àpẹẹrẹ. Gbogbo àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí ni àwọn àkójọpọ̀ ìtọ́ni tí Bíbélì ṣe fún àwọn ọkọ àti àwọn aya.

Nígbà tí Ọlọ́run mú Éfà wá sí ọ̀dọ̀ Ádámù nínú ìgbéyàwó àkọ́kọ́, a ṣẹ̀da rẹ̀ láti inú "ẹran ara àti egungun" rẹ̀ (Jẹnẹsisi 2:21) wọ́n sì di "ara kan" (Jẹnẹsisi 2:23-24). Ìtumọ̀ jíjẹ́ ara kan jú wípé ìdàpọ̀ ti ara lọ. Ó túmọ̀ sí pípàdé ti èrò ọkan àti ọkàn láti di igun kan. Ìbáṣepọ̀ yìí kọja jìnà réré tayọ ti ìbálọ́pọ̀ àti ìmọ̀lára, àti wíwọ inú "ìṣọ̀kan" tí ẹ̀mí tí ó lè di rírí nìkan gẹ́gẹ́ bí alábàṣepọ̀ méjèèjì bá ṣe jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún ara wọn. Ìbáṣepọ̀ yìí kò dálé lórí "èmi àti t'èmi" ṣùgbọ́n lórí "àwa àti t'àwa." Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣírí sí ìgbeyàwó tí ó pẹ́.

Jíjẹ́ kí ìgbéyàwó kan pẹ́ fún ìgbà-ayé ẹ̀dá jẹ́ ohun kan tí àwọn alábaṣepọ̀ méjèèjì ní láti fi ṣe pàtàkì jùlọ. Àwọn tọkọtaya tí àwọn igbeyàwó bá pẹ́ máa ńṣe àjọyọ̀ àwọn ìfarajìn wọn sí ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn tọkọtaya fi ṣé ìpinnu kan láti má tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀, kódà nínú ìbínú. Fífi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ìbáṣepọ̀ ẹni èyítí o lọ sóké pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipa tí ó jinlẹ̀ láti ríi dájú wípé ìbáṣepọ̀ láàrín ọkọ àti aya jẹ́ èyítí ó pẹ́, tí ó bu ọlá fún Ọlọ́run.

Tọkọtaya tí ó bá ńfẹ́ kì ìgbéyàwo wọn kí ó pẹ́ gbọdọ̀ kọ́ bí a ṣe ńkojú àwọn ìṣòrò. Àdúrà, kíkọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, àti gbígba ara ẹni niyánjú náà dára. Àti wípé kò sí ohun ti ó búrú pẹ̀lú wíwá ìránlọ̀wọ́ lóde; kódà, ọ̀kan nínú àwọn ìdí ti ìjọ ní láti "ru ara wa si ìfẹ́ àti si iṣẹ́ rere" (Heberu 10:24). Àwọn tọkọtaya tí wọ́n ńtiraka gbọ́dọ̀ wá ìmọ̀ràn láti ọwọ́ àwọn tọkọtaya Kristiẹni tí o ti dàgbà, olùṣọ́ àgùntàn, tàbí agbanilámọràn nípa ìgbéyàwó tí o bá bíbélì mu.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Jíjẹ́ kí ìgbeyàwó pẹ́ — kínni kókó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries