settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìwò wípé kò sí Ọlọ́run?

Idahun


Ìwò wípé kò sí Ọlọ́run jẹ́ ìwò wípé Ọlọ́run kò sí. Ìwò wípé kò sí Ọlọ́run kìí ṣe ohun titun Orin Dafidi 14:1, tí a kọ láti ọwọ́ Dáfídì ní àkókò ẹgbẹ̀rún (1000) ọdún kan kí a tó bí Kristi mẹ́nuba ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí: "Aṣiwerè wí lí ọkàn rẹ̀ pé, 'Ọlọ́run kò sí.'" Ìwádìí ìṣirò tí ó wáyé láìpẹ́ fihàn wípé iye àwọn ènìyàn tí ó ńpọ̀si gbà wípé àwọn jẹ́ ẹni tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà, títí dé ìdá mẹ́ẹ̀wá nínú ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn lágbàáyé. Nítorí náà kílódé tí àwọn ènìyàn ṣe ńdi ẹni tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà? Ǹjẹ́ ìwò wípé kò sí Ọlọ́run jẹ́ ipò òtítọ́ tí ó mú ọgbọ́n dání bí àwọn tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà ṣe ńjẹ́wọ́?

Kínní ìdí tí ìwò wípé kò sí Ọlọ́run pàápàá ṣe wà? Kínni ìdí tí Ọlọ́run kò ṣe kúkú fi ara Rẹ̀ han àwọn ènìyàn, ní fí fi wíwà Òun hàn? Nítòótọ́ bí Ọlọ́run bá kan farahàn, ìrònú náà ni wípé, gbogbo ènìyàn ni yóò gbàgbọ́ nínú Rẹ̀! Ìṣòro níbíyìí ní wípé kìí ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti mu dánilójú wípé Òún wà. Ó jẹ́ ìfẹ́ ti Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ (2 Peteru 3:9) kí wọn sì gbà ẹ̀bùn ìgbàlà Rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ (Johannu 3:16). Ọlọ́run ṣe àfihàn wíwà Rẹ̀ kedere lọ́pọ̀ ìgbà nínú Májẹ̀mú Láíláí (Jẹnẹsisi 6-9; Ẹksodu 14:21-22; 1 Àwọn Ọba 18: 19-31). Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn náà gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà? Bẹ́ẹ̀ni. Ǹjẹ́ wọn yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà ibi wọn tí wọn sì gbọ́ràn sí Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀kọ́. Bí ẹnìkan kò bá ńfẹ́ láti gba wíwà ti Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́, nígbà náà òun l'ọ́kùnrin/l'óbìnrin ni tí kò tíì ṣetán dájúdájú láti gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà nípa ìgbàgbọ́ (Efesu 2:8-9). Ìfẹ́ Ólọ́run jẹ́ fún àwọn ènìyàn láti di Kristiẹni, kìí kàn ṣe ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà (àwọn tí ó gbàgbọ́ wípé Ọlọ̀run wà).

Bíbélì sọ fún wa wípé àwa gbọ́dọ̀ gba wíwà Ọlọ́run gbọ́ nípa ìgbàgbọ́. Heberu 11:6 sọ wípé "láì sìí ìgbàgbọ́ kò ṣé e ṣe láti wu Ọlọ́run, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá nwá sí ọ̀dọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ wípé ò wà láàyè àti wípé òun ni òlùṣẹ̀san fún àwọn tí o ń fi ìtara wá a." Bíbélì rán wa létí wípé àwa jẹ́ alábùkún fún nígbàtí a bá gbàgbọ́ tí a sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́: "Lẹ́hìn náà Jésù wí fun pé, 'Nítorí wípé ìwọ́ ti rí mi, ìwọ́ ti gbàgbọ́ alábùkún ní fún àwọn tí kò ì tí rí mi síbẹ̀ wọ́n gbàgbọ́"' (Johannu 20:29).

Wíwà Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gba nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n èyì kò túmọ̀ sí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run jẹ́ àìní ìrònú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àrínyànjiyàn tí ó dára fún wíwà Ọlọ́run ni ó wà. Bíbélì kọ́ wípé wíwà Ọlọ́run ni a rí kedere nínú àgbáyé yìí (Orin Dafidi 19:1-4), nínú àwọn ohun àdáyébá (Romu 1:18-22), àti nínú àwọn ọkan wa (Oniwaasu 3:11). Pẹ̀lú gbogbo èyí tí a ti sọ yìí, wíwà Ọlọ́run kò ṣeé jẹ́rìsí sí; ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà nípa ìgbàgbọ́.

Ní àkókò kan náà, ó ńgba ìgbàgbọ́ púpọ̀ bakan náà láti gbàgbọ́ nínú wípé Ọlọ̀run kò sí. Láti mú kí gbólóhùn pọ́nbélé náà "Ọlọ́run kò sí" jẹ́ láti gbà ní ìmọ̀ ohun gbogbo l'ápapọ̀ èyí tí ó wà látì mọ̀ nípa ohun gbogbo àti ti ní ní wíwà níbi gbogbo nínú àgbáyé àti níní ìjẹ́rìí ohun gbogbo èyí tí ó ńbẹ láti rí. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí yóò jẹ́rìsí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ìyẹ́n jẹ́ pàtàkì ohún tí wọ́n ńgbà nígbàtí wọ́n bá sọ wípé Ọlọ́run kò sí pátápátá. Àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ọlọ́run kò sí, fún àpẹ̀ẹrẹ, ńgbé láàrín gbùngbùn òòrùn, tàbí lábẹ́ àwọn sáńmọ̀ ti Júpítérì, tàbí ní àwọn kùrukùru jí jìnjìnnà. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ibi wọ̀nyìí ti ju àwọn agbára wa láti ṣe àkíyèsi lọ, kò ṣeé fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ọlórun kò sí. Ó gba ìgbàgbọ́ púpọ̀ látí jẹ́ ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run látí jẹ́ ẹnìkan tí ó gbàgbọ̀ wípé Ọlọ́run wà.

Ìwò wípé kò sí Ọlọ́run jẹ́ èyí tí a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀, àwa gbọ́dọ̀ gba wíwà Ólọ́run gbọ́ nípa ìgbàgbọ́. Ó hàn gbangba, wípé àwọn Kristiẹni gbàgbọ́ gan an wípé Ọlọ̀run wà, àti wípé wọn gbà wípé wíwà Ọlọ́run jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́. Ní àkókò kan náà, àwa kọ èrò wípé ìgbàgbọ̀ nínú Ọlọ́run jẹ́ èyì tí kò mú ọpọlọ dání mu. Àwá gbàgbọ́ wípé wíwà Ọlọ́run jẹ́ èyí tí a lè rí kedere, tì a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dé ibi tí ó pọndandan nípa ọ̀nà ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́nsì. "Àwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run, àti òfurufú ńfi iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ hàn." Ọjọ́ dé ọjọ́ ńfọhùn, àti òru dé òru ń fi ìmọ̀ hàn. Kò sí ohùn kan tàbí èdè kan, níbití a kò gbọ́ ìró wọn. Ìró wón la ayé já, àti ọ̀rọ wọn dé òpin ayé" (Orin Dafidi 19:1-4).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìwò wípé kò sí Ọlọ́run?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries