settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti wàásù fún ẹnìkan tí ó ńbẹ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí ẹ̀sìn èké?

Idahun


Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a lè ṣe fún àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí ẹ̀sìn èké ní láti gbàdúrà fún wọn. Àwa ní láti gbàdúrà wípé kí Ọlọ́run yí wọn l'ọ́kàn padà kí Òun sì ṣí ojú wọn sí òtítọ́ (2 Kọrinti 4:4). A nílò láti gbàdúrà wípé kí Ọlọ́run baà lè fún wọn ní ìdánilójú tí wọn nílò ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Krísti (Johannu 3:16). Láìsí agbára Ọlọ́run àti ìdánilójú ti Ẹ̀mí Mímọ́, a kò lè ṣe àṣeyọrí láíláí ní fífún ẹnikẹ́ni ní ìdánilójú ti òtítọ́ náà (Johannu 16:7-11).

Àwa tún nílò láti máa gbé ìgbe-ayé ìwà bí Ọlọ́run, nítori bẹ́ẹ̀ àwọn tí ó ti wà nínú àhámọ́ nínú àwọn ẹ̀gbẹ́ òkùnkùn àti àwọn ẹ̀sìn lè rí ìyípadà tí Ọlọ́run ti ṣe nínú ayé wa (1 Peteru 3:1-2). Àwa nílò láti gbàdúrà fún ọgbọ́n ní bí a ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó kún fún agbára (Jakọbu 1:5). Lẹ́hìn àwọn ohun wọ̀nyìí, a gbọ́dọ̀ ní ìgboyà nínú pínpín ìhìnrere àwa gan-an. Àwa gbọ́dọ̀ kéde ìhìnrere ti ìgbàlà náà nípasẹ̀ Jésù Kristi (Romu 10:9-10). Àwa gbọ́dọ̀ máa wà ní ìgbáradì nígbàgbogbo láti dáàbòbò ìgbàgbọ́ wa (1 Peteru 3:15), ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀. Àwa lè kéde ẹ̀kọ́ náà lọ́nà tí ó tọ̀nà, borí ogun ti ọ̀rọ̀, àti síbẹ̀ ṣe okùnfà ìdíwọ́ nípa ìhùwàsí tí ìbínú tí ó ga jùlọ.

Ní ìkẹhìn, a gbọ́dọ̀ fi ìgbàlà àwọn ẹni ti a ti jẹ́ ẹ̀rí fún sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Agbára àti ore-ọ̀fẹ́ ti Ọlọ́run ni o ńgba ènìyàn là, kìí ṣe ipá wa. Nígbà tí ó dára tí ó sì mú ọgbọ́n wa láti wà ní ìgbaradì làti ṣe ìgbèjà tí ó l'ágbára kí a sì ní ìmọ̀ àwọn ìgbàgbọ́ èké, bóyá ti àwọn nǹkàn wọ̀nyìí yóò yọrí sí àyípadà ti àwọn tí ó há gágá sí inú irọ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn náà àti àwọn ẹ̀sìn èké. Èyí tí ó dára jùlọ tí a lè ṣe ní láti gbàdúrà fún wọn, jẹ́rì fún wọn, gbé ìgbé-ayé Kristiẹni ní iwájú wọn, nì ní ìgbẹ́kẹ̀lé wípé Ẹ̀mí Mímọ́ yóò ṣe iṣẹ́ fífà, fífún ní ní ìdánilójú, àti ṣíṣe àyípadà.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti wàásù fún ẹnìkan tí ó ńbẹ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí ẹ̀sìn èké?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries