settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìtumọ̀ ẹ̀ṣẹ̀?

Idahun


A ṣe àpéjùwe ẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bíi rírú òfin Ọlọ́run (1 Johannu 3:4) àti ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run (Deutarọnọmi 9:7, Joṣua 1:18). Ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu Lusiferi, bóyá áńgẹ́lì tí ó l'ẹ́wà tí ó sì l'ágbára jùlọ. Ipò rẹ̀ kò tẹ l'ọ́rùn, ó wùú láti gaju Ọlọ́run lọ, èyi sì ni ìṣubú rẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ (Isaiah 14:12-15). Orúkọ àtúnpè Satani, ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wàá fún ìran ènìyàn nínú ọgbà Edẹni, níbití ó ti dán Adamu àti Efa wò pẹ̀lú ìtànjẹ kanńàá, "ẹ̀yin ó dàbí Ọlọ́run." Jẹnẹsisi 3 ṣe àpéjùwe ìṣọ̀tẹ̀ ti Adamu àti Efa lòdì sí Ọlọrun ati lòdì sí aṣẹ Rẹ̀. Láti ìgbànáà, ẹ̀ṣẹ̀ ti sàn wálẹ̀ sí gbogbo ìran ọmọ ènìyàn àti wípé àwa, ìran Adamu, ti j'ogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Romu 5:12 sọ fún wa wípé ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa ọ̀dọ̀ Adamu wọ ayé, bẹ́ẹ̀ni ikú sí kọjá s'órí ènìyàn gbogbo nítorí wípé "ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀" (Romu 6:23).

Nípasẹ̀ Adamu, ìtẹríba fún ẹ̀ṣẹ̀ wọ inú ìran ènìyàn, àwọn ọmọ ènìyàn síì di ẹlẹ́sẹ̀ nípa ara. Nígbàtí Adamu d'ẹ́sẹ̀, àbùdá inú rẹ̀ yípadà nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìsọ̀tẹ̀, èyítí òun mú ikú ẹ̀mí àti ìdibàjẹ́ wá fún-un tí yóò sì pín fún gbogbo àwọn tí wọ́n wá lẹ́yìn rẹ̀. A jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kìí se nítorí wípé a d'ẹ́ṣẹ̀; bíkòse wípé, a d'ẹ́ṣẹ̀ nítorípé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. Ìdibàjẹ́ tí ó pín yìí ni a mọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jogún àbùdá ara láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa, a jogún àwọn àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ wa láti ọ̀dọ̀ Adamu. Dafidi Ọba kẹ́dùn ipò ìṣubú àbùdá ènìyàn yìí nínú Orin Dafidi 51:5: "Kíyèsi i, nínú àìsedéédé ni a gbé bí mí, àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi síì l'óyún mi."

Oríṣi ẹ̀ṣẹ̀ míìrán ni a mọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ìkàsíni l'ọ́rùn. Èyítí a ńlò nínú àwọn ètò ìṣúná àti òfin, ọ̀rọ̀ Gíríkì tí a túmọ̀ "ìkàsíni l'ọ́rùn" túmọ̀ sí "kí á fi ohun tí ó tọ́ sí ẹnìkan fún ẹlòmìíràn." Kí òfin Mose tó dé, a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn, bíótilẹ̀jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogún bá. Lẹ́yìn tí a fi Òfin fún wa, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá l'òdì sí Òfin ni a kà sí wọn l'ọ́rùn (Romu 5:13). Kódà kí á tó ka òfin rírú sí àwọn ènìyàn l'ọ́rùn, èrè ẹ̀ṣẹ̀ ńlá (ikú) tí ńjọba (Romu 5:14). Gbogbo ènìyàn, láti Adamu sí Mose, di ẹrú ikú, kìíse nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn lòdì sí Òfin Mose (èyítí wọn kò ní), sùgbọ́n nítorí àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ àjogún bá wọn. Lẹ́yìn Mose, àwọn ènìyàn di ẹrú iku nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogún bá láti ọ̀dọ Adamu àti ẹ̀ṣẹ̀ ìkàsíni l'ọ́rùn nípa ìtàpá sí àwọn òfin Ọlọ́run.

Ọlọ́run lo ìlànà ìkàsíni l'ọ́rùn láti fi ṣe àǹfààní fún ọmọ ènìyàn nígbàtí Óún ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ sí Jésù Kristi l'ọ́rùn, enití ó san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀-ikú-l'órí igi àgbélèbú. Kíka ẹ̀ṣẹ̀ wa sí Jésù l'ọ́rùn, Ọlọ́run wò Ó bíi wípé Ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Òun kò d'ẹ́ṣẹ̀, Ó sì mú kí Òun kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé (1 Johannu 2:2). Ó ṣe pàtàkì láti l'òye wípé a ka ẹ̀ṣẹ̀ sí I l'ọ́rùn, ṣùgbọ́n Òun kò jogún rẹ̀ láti ọ̀dọ Adamu. Ó san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣùgbọ́n Òun kò di ẹlẹ́ṣẹ̀. Àbùdá mímọ́ àti pípé Rẹ̀ kò l'àbàwọ́n nípa ẹ̀ṣẹ̀. A wòó bíí wípé Ó jẹ̀bi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ìran ọmọ ènìyàn ti dá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Òun kò d'ẹ́ṣẹ̀ kankan. Ní pàṣíìpààrọ̀, Ọlọ́run fi òdodo Jesu kún inú àwọn onígbàgbọ́ ó sì fi òdodo Rẹ̀ kún wa, gẹ́gẹ́ bí Òun ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ wa sí I l'ọ́rùn (2 Kọrinti 5:21).

Oríṣi ẹ̀ṣẹ̀ míìrán ni ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni, èyítí gbogbo ènìyàn ńdá ní ojoojúmọ́. Nítorí wípé a ti jogún àbùdá ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Adamu, à ńd'ẹ́ṣẹ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan, ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni, ohun gbogbo láti àìsòdodo kékéèké sí ìpànìyàn. Àwọn tí kò tíì fi ìgbàgbọ́ wọn sínú Jésù Kristi gbọdọ̀ san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn, pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ati ẹ̀ṣẹ̀ ìkàsíni l'ọ́rùn. Ṣùgbọ́n, àwọn onígbàgbọ́ ti bọ́ lọ́wọ́ ìparun ẹ̀ṣẹ̀ ayérayé-ọ̀run àpáàdì àti ikú ẹ̀mí-ṣùgbọ́n nísisìnyí a ní agbára pẹ̀lú láti d'ojúkọ dídá ẹ̀ṣẹ̀. Ní bàyí a le yàn bóyá a fẹ́ tàbí a kò fẹ́ dá ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni nítorí a ní agbára láti d'ojúkọ ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ẹnití Ó ngbé inú wa, Óun yà wá sí mímọ́ Òun sì ńdá wa l'ẹ́bìi ẹ̀ṣẹ̀ nígbàtí a bá dá wọn (Romu 8:9-11). Níwọ̀n tí a bá ti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni fún Ọlọ́run tí a síì bèèrè ìdáríjìn fún wọn, a ti mú wa bọ̀ sípò sí ìdàpọ̀ àti ìbásepọ̀ tí ó dán mọ́rán pẹ̀lú Rẹ̀. "Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtọ́ọ́ àti olódodo li Òun láti dárí ẹ́ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo" (1 Johannu 1:9).

A dá gbogbo wa l'ẹ́ẹ̀bi l'ọ́nà mẹ́ta nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, ẹ̀ṣẹ̀ ìkàsíni l'ọ́rùn, ati ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni. Ìjìyà kan fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ikú (Romu 6:23), kìí ṣe ikú ti ara nìkan bíkòṣe ikú ayérayé (Ifihan 20:11-15). Pẹ̀lú ọkàn ọpẹ́, a ti kan gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, ẹ̀ṣẹ̀ ìkàsíni l'ọ́rùn, àti ẹ̀ṣẹ̀ ara-ẹni mọ́ àgbélèbú Jésù, nísisìnyí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà "àwa ní ìràpadà nípa ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ore-òfẹ́ Rẹ̀" (Efesu 1:7).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìtumọ̀ ẹ̀ṣẹ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries