settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Ìtẹ́ Ìdájọ́ Funfun ńlá?

Idahun


Àpèjúwe ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá wà ní Ifihan 20:11-15 òhun sì ni ìdájọ́ ìkẹyìn ṣáájú kí a tó sọ àwọn tí ó pàdánù sínú adágún iná. A mọ̀ láti Ifihan 20:7-15 wípé ìdájọ́ yìí yóò wáyé lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún àti lẹ́yìn tí a ti sọ Satani, ẹranko búburú nìì, àti wòólì èké sínú adágún iná (Ifihan 20:7-10). Àwọn ìwé tí a ṣí sílẹ̀ (Ifihan 20:12) ní àkọsílẹ̀ ìṣe gbogbo ènìyàn, bóyà rere tàbí ibi ni, nítorí Ọlọ́run mọ ohun gbogbo tí a ti sọ, ṣe, tàbí rò, yóò sí gbósùbà tàbí fi ìyà jẹ olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ (Orin Dafidi 28:4; Romu 2:6; Ifihan 2:23; 18:6; 22:12).

Bákànnáà ni àkókò yìí, a ṣí ìwé míìrán sílẹ̀, tí a pè ní "ìwé ìyè" (Ifihan 21:12). Ìwé yìí ló ńsọ bóyá ènìyàn yóò jogún ìyè ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí gba ìjìyà àìnípẹ̀kun nínú adágún iná. Bí ó tilẹ̀ jẹ wípé a mú àwọn onígbàgbọ́ fún àwọn ìṣe wọn, a dáríjìn wọ́n nínú Kristi a sì ti kọ orúkọ wọn sínú "ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá" (Ifihan 17:8). A mọ̀ bákannáà láti inú Ìwé Mímọ́ wípé ní ìdájọ́ yìí ni àwọn òkú yóò ti gba "ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn" (Ifihan 20:12) àti wípé "orúkọ ẹnikẹ́ni" tí kò bá "sí nínú ìwé ìyè" ni a ó "sọ sínú adágún iná" (Ifihan 20:15).

Òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ó ṣe ìdájọ́ ìkẹyìn fún gbogbo ènìyàn, àwọn onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́, ló f'ìdí múlẹ̀ kedere nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Gbogbo ènìyàn ni yóò dúró níwájú Kristi tí yóò sì gba ìdájọ́ fún ìṣe rẹ l'ọ́jọ́ kan. Bí ó ti hàn kedere wípé ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá ni ìdájọ́ ìkẹyìn, àwọn onígbàgbọ́ lòdì sí bí ó ti jẹ mọ́ àwọn ìdájọ́ mìíràn tí a mẹ́nu bà nínú Bíbélì, pàápàá jùlọ, ẹnití a ó dá l'ẹ́jọ́ ní ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá.

Àwọn onígbàgbọ́ kan gbàgbọ́ wípé Ìwé Mímọ́ ṣe àfihàn ìdájọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ńbọ̀. Àkọ́kọ́ ni ìdájọ́ àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ tàbí ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè (Matteu 25:31-36). Èyí wáyé lẹ́yìn àkókò ìpọ́njú ṣùgbọ́n ṣáájú ẹgbẹ̀rún ọdún; ète rẹ̀ ni láti mọ ẹnití yóò wọ ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún. Ẹ̀kejì ni ìdájọ́ iṣẹ́ àwọn onígbàgbọ́, tí à ńpè ní "ìjókòó ìdájọ́ [bema] Krístì" ní ìgbà mìíràn (2 Kọrinti 5:10). Ní ìdájọ́ yìí, àwọn onígbàgbọ́ yóò gba àwọn ìpele èrè fún iṣẹ́ àti ìṣe wọn sí Ọlọ́run. Ẹ̀kẹta ni ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún (Ifihan 20:11-15). Èyí ni ìdájọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ nínú èyítí wọn yóò gba ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn a ó sì sọ wọ́n sí ìjìyà àìnípẹ̀kun nínú adágún iná.

Àwọn onígbàgbọ́ míìrán gbàgbọ́ wípé gbogbo ìdájọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí ńsọ nípa ìdájọ́ ìkẹyìn kannáà, kìí sì ṣe nípa ìdájọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ní ọ̀rọ̀ míìrán, ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá nínú Ifihan 20:11-15 ni yóò jẹ́ ìgbà tí ó ṣeéṣe kí á ṣe ìdájọ́ àwọn onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́. Àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè yóò gba ìdájọ́ fún ìṣe wọn láti le mọ èrè tí wọn yóò gbà tàbí pàdánù. Àwọn tí orúkọ wọn kò sí nínú ìwé ìyè yóò gba ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn láti mọ̀ bí ìjìyà tí wọn yóò gbà yóò ṣe pọ̀ tó nínú adágún iná. Àwọn tí wọ́n ní ìwòye yìí gbàgbọ́ wípé Matteu 25:31-46 ni àpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ míìrán ní ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá. Wọ́n tọ́ka síi wípé àyọrísí ìdájọ́ yìí papọ̀ mọ́ ohun tí a rí lẹ́yìn ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá nínú Ifihan 20:11-15. Àwọn àgùtàn (onígbàgbọ́) wọ inú ìyè ayérayé, nígbàtí a sọ àwọn ewúrẹ́ (aláìgbàgbọ́) sínú "ìjìyà ayérayé" (Matteu 25:46).

Ìwòye èyíkèyí tí ènìyàn bá dìmú nípa ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá, ó ṣe pàtàkì láti má pàdánù òdodo ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tí ó ńbọ̀. Àkọ́kọ́, Jésù Kristi ni yóò jẹ́ onìdájọ́, Kristi ni yóò dá gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ l'ẹ́jọ́, wọn ó sì gba ìjìyà wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Bíbélì hàn kedere wípé àwọn aláìgbàgbọ́ ńfi ìbínú ṣúra fún ara wọn (Romu 2:5) àti wípé Ọlọ́run yóò "san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀" (Romu 2:6). Kristi ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn onigbàgbọ́ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí òdodo Kristi ti hàn sí wa tí a sì ti kọ orúkọ wa sínú ìwé ìyè, àwa yóò gba èrè, kìí sì ṣe ìjìyà, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa. Romu 14:10-12 sọ wípé gbogbo wa ni yóò sáà dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì olúkúlùkù wa ni yóò sì jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Ìtẹ́ Ìdájọ́ Funfun ńlá?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries