settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi?

Idahun


Romu 14:10-12 sọ wípé gbogbo wa ni yóò sáà dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi ...ǹjẹ́ nítorínà olúkúlùkù wa ni yóò sì jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run. Kọrinti kejì 5:10 sọ fún wa, "Nítorí gbogbo wa kò le sàìmá fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, kí olúkúlùkù kí ó le gba ǹkan wọnnì tí ó se nínú ara, gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ti se, ìbáà se rere ìbáà se búburú." Nínú ìwòye yìí, ó hàn kedere wípé àwọn àyọkà ìwé mímọ́ yìí ńtọ́ka sí àwọn onígbàgbọ́, kìí ṣe àwọn aláìgbàgbọ́. Ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi, nítorínáà, nííṣe pẹ̀lú kí àwọn onígbàgbọ́ máa sọ àkọsílẹ̀ ohun ti wọn ṣe fún Kristi. Ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi kò ṣe ìpinnu ìgbàlà; ìrúbọ Kristi ló pinnu ìyẹn fún wa (1 Johannu 2:2) àti ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ (Johannu 3:16). A ti darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, a kò sì ní dá wa l'ẹ́bi mọ́ fún wọn (Romu 8:1). A kò gbọdọ̀ wo ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi gẹ́gẹ́ bíi wípé Ọlọ́run ńdá wa l'ẹ́jọ́, ṣùgbọ́n kí á rí bíi wípé Ọlọ́run ńpín wa l'érè fún ayé wa. Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, àwa yóò jíyìn iṣẹ́ wa. Apákan èyí ńdáhùn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá. Ṣùgbọ́n, ìyẹn kò ní jẹ́ àfojúsùn pàtàkí fún ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi.

Ní Ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, àwọn onígbàgbọ́ ńgba èrè wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sin Kristi l'óòtítọ́ síí (1 Kọrinti 9:4-27; 2 Timoteu 2:5). Àwọn ohun díẹ̀ tí a le dá wa l'ẹ́jọ́ lé lórí ni bí a ṣe gbọ́ràn sí Àṣẹ Ńlá (Matteu 28:18-20), bí a ṣe sẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ sí (Romu 6:1-4), àti bí a ṣe kó ahọ́n wa ní ìjánu síi (Jakọbu 3:1-9). Bíbélì sọ nípa àwọn onígbàgbọ́ tí ńgba adé fún ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí wọ́n ṣe sin Kristi l'óòtítọ́ síí (1 Kọrinti 9:4-27; 2 Timoteu 2:5). Oríṣiríṣi adé ni a ṣe àpèjúwe wọn nínú Timoteu kejì 2:5, Timoteu kejì 4:8, Jakọbu 1;12, Peteru kínní 5:4, àti Ifihan 2:10. Jakọbu 1:12 jẹ́ àkótán dáradára lórí bí ó ti yẹ ká ronú nípa ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì: "Ìbúkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò: nítorí nígbàtí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti se ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ."

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni Ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries