settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìṣiyèméjì?

Idahun


Ìṣiyèméjì jẹ́ ojú ìwòye wípé ìwàláàyè Ọlọ́run náà kò ṣeé ṣe láti mọ̀ tàbí fihàn. Ọ̀rọ̀ náà "aláìfóye" ní pàtàkì jùlọ túmọ̀ sí "àìlóye". Ìṣiyèméjì tún jẹ́ irú òtítọ́ tí ó lọ́gbọ́n nínú nípa àìgbà wípé Ọlọ́run wà. Ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí gbà wípé Ọlọ́run kò sí—ipò tí kò lójú. Ìṣiyèméjì jiyàn wípé a kò lè fi wíwà láàyè Ọlọ́run hàn tàbí kò ṣèé fihàn, wípé kò ṣeé ṣe láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. Nínú eléyìí, ìṣiyèméjì jẹ́ èyí tí ó tọ́. Ìwàláàyè Ọlọ́run ni a kò lè fihàn tàbì àìfihàn nípa ṣí ṣe ìwádì àti àṣìṣe.

Bíbélì sọ fún wa wípé a gbọ́dọ̀ gbà nípa ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà. Heberu 11:6 sọ wípé láì sí ìgbàgbọ́ "kò ṣé e ṣe láti wu Ọlọ́run, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ǹ wá sí ọ̀dọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ wípé ó wà láàyè àti wípé òun ni òlùṣẹ̀san fún àwọn tí o ń fi ìtara wá a." Ẹ̀mí ni Ọlọ́run (Johannu 4:24) nítorí náà a kò lè rí Òun tàbí fi ọwọ́ kàn-án. Àyààfi bí Ọlọ́run bá yàn láti fi ara Rẹ̀ hàn, Òun jẹ̀ ẹni tí a kò lè rí pẹ̀lú àwọn ẹ̀ya ara wa (Romu 1:20). Bíbélì náà kéde wípé ìwàláàyè Ọ̀lọ́run lè di rírí kedere nínú àgbáyé yìí (Orin Dafidi 19:1-4), tí a lè ní ìmọ̀lára nínú ti ayé (Romu 1:18-22), tí a sì lè jẹ́rìsí nínú àwọn ọkan wa (Oniwaasu 3:11).

Àwọn ìṣiyèméjì jẹ́ aláìfẹ́ láti ṣe ìpinnu kan bóyá fún wíwà Ọlọ́run tàbí lòdì síi. Ó jẹ́ ti ipò "rínrìn ní ẹ̀gbẹ odi" ni ìkẹhìn. Àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà. Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run wípé Ọlọ́run kò sí. Àwọn oníyèméjì gbàgbọ́ wípé a kò gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ tàbí má gbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọ́run, nítorí wípé kò ṣeé ṣe láti mọ̀ ní ọ̀nà yóòwù.

Nítorí ti àríyànjiyàn, ẹ jẹ́ ká gbàgbé nipa àwọn ẹ̀rí tí kò hàn kedere àti èyí tí a kò lè kọ̀ ni ti ìwàálààyè t'Ọlọ́run. Bí a ba mú àwọn ipò ti àìgbàpé Ọlọ́run wáà àti ìṣiyèméjì ní ori ipele kannáà, ewo ni ó "mọ́'gbọ́n wá" jùlọ láti gbàgbọ́ nipa ọro ṣí ṣe é ṣe ti ayé lẹ́hìn ikú? Bí Ọlọ́run kò bá sí, àìgbàpé Ọlọ́run wà àti àwọn oníyèméjì bákannáà gbogbo ní kò ní wà láàyè nígbàtí wọ́n bá kú. Bí Ọlọ́run bá wà, àwọn méèjèjì àìgbàpé Ọlọ́run wáà àti àwọn oníyèmèéjì yóò ní ẹnìkan láti dáhùn sí nígbàtí wọn bá kú. Láti ojú ìwòye yìí, dájúdájú ó ní "ìtumọ̀" ju, láti jẹ́ aìgbàpé Ọlọ́run wáà ju oní iyèméèjì náà lọ. Bí kò bá si ọkankan ninú méjèji ti ó ni ẹ̀ri tabi ti kò ni ẹ̀ri, ó jẹ́ ohun ọlọgbọ́n láti sa gbogbo ipá làti ṣe àyẹ̀wò fínífíní ipò náà tí o lè ti ní àìlópin àti ayérayé sí àbájáde ìkẹhìn tí à ń fẹ́ jùlọ.

Ó ṣe déédé láti ní àwọn ìyeméjì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni ó n bẹ nínú ayé yìí tí kò yé wa. Nígbàgbogbo, àwọn ènìyàn ńṣiyèméjì ìwàláàyè t'Ọlọ́run, nítorí òye kò yé wọn, tàbí kí wọn gbà fún àwọn òhun tí ó ń ṣe àti ohun tí ó gbà láàyè. Síbẹ̀sìbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti ó ní ìparí a kò gbọ́dọ̀ retí à ti má a ní òye Ọlọ̀run àìlópin náà. Ìwé Romu 11:33 polongo wípé, "Ah! ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!

Àwámáridìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì ju àwárí lọ! 'Nítorí talí ó mọ inú Olúwa? Tàbí taní íṣe ìgbìmọ rẹ̀?"" Àwa gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀nà Rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́. Ọlọ́run ti ṣetán àti pé ó sì ń fẹ́ láti fi ara rẹ̀ hàn ní àwọn ọ̀nà tí ó yà lárà ọ̀tọ̀ sí àwọn tí yíọ́ gbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Ìwé Deutarọnọmi 4:29 wípé, "Níbẹ̀ ni ẹ ó ti wá Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ ó sì ríi, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí yín."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìṣiyèméjì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries