Ibeere
Kínni Ìpọ́njú náà? Báwo ni a ṣe lè mọ̀ wípé Ìpọ́njú náà yóò wà fún ọdún méje?
Idahun
Ìpọ́njú náà jẹ́ àkókò ọdún méje ní ọjọ́ iwájú nigbà tí Ọlọ́run yóò parí ìbáwí Rẹ̀ lórí Isrẹli tí yóò sì pinnu ìdájọ́ Rẹ̀ lórí ayé aláìgbàgbọ́. Ìjọ, tíí ṣe àkójọpọ̀ gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ẹni àti iṣẹ́ Jésù Olúwa láti gbà wọ́n lọ́wọ́ ìjìyà ẹ́ṣẹ́, kò ní sí ní ayé nígbà ìpọ́njú náà. A ó mú ìjọ kúrò láyé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí à ńpè ní ìgbàsókè (1 Tẹssalonika 4:13-18; 1 Kọrinti 15:51-53). A ó gba ìjọ kúro nínú ìbínú tí ó ńbọ̀ (1 Tẹssalonika 5:9). Nínú gbogbo Ìwé Mímọ́, a pe ìpọ́njú náà ní àwọn orúkọ míìrán bíi ọjọ́ Olúwa (Isaiah 2:12; 13:6-9; Joẹli 1:15; 2:1-31; 3:14; 1 Tẹssalonika 5:2); ìdàmú tàbí ìpọ́njú náà (Deutarọnọmi 4: 30, Sẹfaniah 1:1); ìpọ́njú ńlá náà, tí ó túmọ̀ sí ìdajì ọdún méje náà tí ó le koko (Matteu 24:21); àkókò tàbí ọjọ́ ìyọnu (Daniẹli 12:1, Sẹfaniah 1:15); àkókò ìpọ́njú ilé Jákọ́bù (Jẹrimiah 30:7).
Òye nípa ìwé Daniẹli 9:24-27 ni a nílò láti ní òye ète àti àkókò ìpọ́njú náà. Àyọkà yí sọ nípa àádọ́rin (70) ọ̀sẹ̀ tí a ti sọ lòdì sí " àwọn ènìyàn rẹ." Àwọn Júù, orílẹ̀-èdè Isrẹli jẹ́ àwọn ènìyàn Daniẹli, ìwé Daniẹli 9:24 sọ nípa àkókò tí Ọlọ́run ti fi sílẹ̀ "láti fi òpin sí àiṣedédé, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣe ètùtù fún ìwà ìkà, láti mú òdodo àínìpẹkun wá, fi èdìdí sí ìran àti àsọtẹ́lẹ́, àti láti fi òróró ya ilé Mímọ́ júlọ sọ́tọ̀." Ọlọ́run pàṣẹ wípé, "àádọ̀rin méje" yóò mú gbogbo nǹkan wọ̀nyìí ṣe. Èyí ni àádọ̀rin méje ọdún, tàbí irinwó lé ní àádọ̀run (490) ọdún. (Àwọn ìtúmọ̀ kan pèé níí àádọ̀rin ọ̀sẹ̀ ọdún.) A fi ìdí èyí múlẹ̀ nínú ìpín míìrán nínú àyọkà yìí nínú ìwé Daniẹli. Ní ẹsẹ̀ kẹẹ̀dọọ́gbọ̀n (25) àti kẹrindinlọ́gbọ̀n (26), a sọ fún Daniẹli wípé wọn ó ké Mesiah kúrò lẹ́yìn "méje lọ́ná méje àti méjìlélọ́gọ́ta lọ́ná méje" (ọ̀kàndínláàádọ̀rin (69) láapapọ̀), láti ìbẹ̀rẹ̀ àṣẹ láti tún Jerúsálẹ̀mù kọ́. Ní ọ̀nà míràn, ọ̀kàndínláàádọ̀rin (69) ọdún lọ́ná méje (ọdún 483) lẹ́yìn àṣẹ láti tún Jerúsálẹ̀mù kọ́, ni wọn yóò ké Mesiah kúrò. Àwọn onítàn Bíbélì fìdí rẹ̀ mulẹ̀ pe ọdún 483 kọjá lọ láti ìgba tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerúsálẹ̀mù kọ́, sí ìgbà tí wọn kan Jésù mọ́ àgbélèbú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Onímọ̀ Kristiẹni, ní òye nípa ẹ̀kọ́ àádọ̀rin lọ́nà méje nípa àádọ́rin (70) méje ti Daniẹli yé, láì ka àfojúsùn wọn sí nípa ẹ̀kọ́ òpin ayé (nǹkan/ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú).
Pẹ̀lú ọdún 483 tí ó ti kọjá lọ láti ìgba tí àṣẹ ti jáde lọ láti tún Jerúsálẹ̀mù kọ́, sí ìgbà tí wọ́n ké Mesiah kúrò, èyí fi sáà ọdún méje kan sílẹ̀ láti mú ìwé Daniẹli 9:24 ṣẹ: "láti fi òpin sí àiṣedédé, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣe ètùtù fún ìwà burúkú mú òdodo àínìpẹkun ṣẹ, fi èdìdí di ìran àti àsọtẹ́lẹ́, fi òróró ya ilé Mímọ́ júlọ sọ́tọ̀." Ìgbà ọdún méje tó gbẹ̀yìn ni à ńpè ní àkókò ìpọ́njú—tíí ṣe àkókò tí Ọlọ́run yóò fi òpin sí ìdájọ́ Isrẹli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Ìwé Daniẹli 9:27 tọ́ka sí àkókò ìpọ́njú ọdún méje: "On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ niwọn ọ̀sẹ̀ kan: Ati laarin ọ̀sẹ̀ na ni yóò mu ki a dẹ́kun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, Irira iṣọdahoro yóò si duro lori ibi-mímọ́ titi idajọ ti a pinnu yóò túdà sori asọnidahoro." Ẹni tí ẹsẹ yìí ńsọ nípa rẹ̀ ni ẹni tí Jésù pè ní"ìríra tí ń fa ìsọdahoro" (Matteu 24:15). Tí à ń pè ní "ẹranko náà" nínú ìwé Ifihan 13. Ìwé Dáníẹ́lì 9:27 sọ wípé ẹranko náà yóò dá májẹ̀mú fún ọdún méje, ṣùgbọ́n láàrin ọ̀sẹ̀ yìí (ọdún mẹ́ta ààbọ̀ nínú ìpọ́njú náà), yóò ba májẹ̀mú náà jẹ́, yóò fi ópin sí ẹbọ rírú. Ìwé Ifihan 13 ṣàlàyé wípé ẹranko náà yóo gbé ohun àwòrán ara rẹ̀ ka tẹ́mpílì wípé kí ayé máa sìn òun. Ìwé Ifihan 13:5 sọ wípé yóò máa lọ báyìí fún oṣù méjìlélógójì, tíí ṣe ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Nígbàtí ìwé Daniẹli 9:27 ti sọ wípé èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní ààrin ọ̀sẹ̀, tí ìwé Ifihan 13:5 sọ wípé ẹranko yìí yóò ṣe èyí fún oṣù 42 ( méjìlélógójì), ó rọrùn láti sọ wípé àkójọpọ̀ àkókò náà jẹ́ osù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) tàbí ọdún méje. Tún wo ìwé Daniẹli 9:25, níbití "àkókò, àkókò náà, àti ìdajì àkókò náà" (àkókò=jẹ́ ọdún kan; àkókò náà jẹ́ ọdún méjì; ìdajì àkókò náà jẹ́ ọdún mẹ́ta ààbọ̀) tí a ńpè ní "ìpọ́njú ńlá", ìdajì ọdún méje tí ó kẹ́hìn tí ó jẹ́ àkókò ìpọ́njú tí ẹranko náà yóò fi wà ní ìjọba.
Fún àwọn atọ́ka síwájú si nípa ìpọ́njú náà, wo ìwé Ifihan 11:2-3, tí ó sọ nípa ọjọ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ́fà (1260) àti oṣù méjìlélógójì àti ìwé Daniẹli 12:11-12, tí ó sọ nípa èédégbèje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1290) àti èédégbèje ọjọ́ ó lé ọjọ́ márùndínlógójì(1335). Àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí tọ́ka sí ààrin gbùngbùn ìpọ́njú náà. Àwọn ọjọ́ tí ó ṣẹ́kù ní Daniẹli 12 lè jẹ́ àkókò òpin tí ó wà fún ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè (Matteu 25:31-46) àti àkókò ìgbékalẹ̀ ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún Kristi (Ifihan 20:4-6).
English
Kínni Ìpọ́njú náà? Báwo ni a ṣe lè mọ̀ wípé Ìpọ́njú náà yóò wà fún ọdún méje?