Ibeere
Kínni ìpadàbọ̀ Jésù Kristi kejì?
Idahun
Ìpadàbọ̀ Jésù Kristi kejì jẹ́ ìrètí onígbàgbọ́ pé ohun gbogbo wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì jẹ́ olótítọ́ sí àwọn ìlérí àti àwọn àṣọtẹ́lẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Nígbà tí ó wá ní àkọ́kọ́, Jésù Kristi wá sí ayé bí ọmọ kékeré nínú ibùjẹ ẹran ní Bẹ́tílẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣọ tẹ́lẹ̀. Jésù mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣọtẹ́lẹ̀ ṣẹ nípa Mesiah nipa ìbí, ìgbé-ayé, iṣẹ́ ìránsẹ́, ikú àti àjíhìnde Rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó ní àwọn àṣọtẹ́lẹ̀ kan tí Jésù kò tí mú ṣẹ nípa Mesiah. Wíwá Kristi lẹ́kèejì máa jẹ́ ìpadàbọ̀ láti mú àwọn ìyókù àṣọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Nígbà tí Òun wá ní àkọ́kọ́, Jésù jẹ́ Ẹrú tó jìyà. Ní ìpadàbọ̀ kejì Rẹ̀, yóò jẹ́ Ọba tí ó ńṣẹ́gun. Ní àkọ́kọ́ wá Rẹ̀, Jésù wá ní ipò tí ó rẹlẹ̀ jù. Ní wíwá Rẹ̀ lẹ́kèejì, Jésù yóò dé pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀.
Àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láíláí kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrin wíwá méjèèjì. A lè rí èyí nínú ìwé Isaiah 7:14; 9:6-7 àti ìwé Sẹkariah 14:14. Nítorí bí àṣọtẹ́lẹ̀ yí ṣe jọ wípé ó ńsọ nípa ènìyàn méjì, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ Júù gbàgbọ́ wípé Mesiah èyí tó jìyà àti èyí tó ṣẹ́gun ni yóò wà. Ohun tí wọ́n kùnà láti mọ̀ ni wípé Mesiah kan náà ni ó wà, tí Òun yóò sì mú ipa méjèèjì ṣẹ. Jésù mú ipa ẹrú tó jìyà ṣẹ (Isaiah orí 53) ní wíwá àkọ́kọ́ Rẹ̀. Jésù yóò mú ipa olùgbàlà àti ọba Isrẹli ṣẹ ni ìpadàbọ̀ lẹ́kèejì Rẹ̀. Sẹkariah 12:10 àti Ifihan 1:7, ńṣe àpèjuwè ìpadàbọ̀ lẹ́kèejì, ní ìrántí bí a ṣe ńgún Jésù lọ́kọ̀. Ísrẹli àti gbogbo ayé yóò ṣọ̀fọ̀ bí wọn kò ṣe gba Mesiah nígbà àkọ́kọ́ tí Òun wá.
Lẹ́yìn tí Jésù gòkè lọ sí ọ̀run, àwọn áńgẹ́lì wí fún àwọn àpọ́sítélì wípé, "Wọ́n ní," ẹ̀yin ará Gálílì, èése tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ńwo ojú ọrun? Jésù náà yìí, tí a gba soke ọ̀run kuro lọwọ yin, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹgẹ bi ẹ ti ri tí ó ńlọ sí ọ̀run" (Iṣe àwọn Apọsteli 1 :11). Sẹkariah 14:14 tọ́kasí wípé Orí-òkè Ólífì ni ibi ìpadàbọ̀ lẹ́kèejì. Matteu 24:30 fihàn wípé,"nigbana li àmì Ọmọ-èniyàn yóo si fi ara hàn li ọ̀run, nigbana li gbogbo ẹya ayé yóò káànú. Wọn o si ri Ọmọ-ènìyàn ti yóò ma ti oju ọ̀run bọ̀ ti on ti agbara ati ogo ńlá." Ìwé Títù 2:13 ṣàlàyé ìpadàbọ̀ lẹ́kèejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí "ìfarahàn ògo".
A sọ̀rọ̀ ìpadàbọ̀ lẹ́kèejì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ìwé Ìfihàn 19:11-16, "Mo si rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, si woo, ẹsin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a ńpe ni Olódodo àti Olóòótọ́, Ninu ododo li o si ńṣe ìdájọ́, tí ó sì ńjagun. Ojú Rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, ati li ori rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; O si ni orúkọ kan ti a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. A si wọ̀ọ́ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ̀: a si npe orúkọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ogun ti mbẹ li ọ̀run ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwe, funfun ati mímọ́, si ńtọ̀ọ́ lẹhin lori ẹsin funfun. Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti njáde lọ, ki o le máa fi iṣá awọn orilẹ-èdè: on o si máa fi ọ̀pá irin' ṣe akoso wọn: O si ntẹ ìfúntí irunu ati ibinu Ọlọ́run Olódùmarè. O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orúkọ kan ti a kọ: "ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI OLÚWA ÀWỌN OLÚWA"
English
Kínni ìpadàbọ̀ Jésù Kristi kejì?