settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ ikú àwọn àpọ́stélì? Báwo ni àwọn àpọ́stélì kọ̀ọ̀kan ṣe kú?

Idahun


Àpọ́stélì kan soso tí Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ ikú rẹ̀ ni Jakọbu (Iṣe àwọn Apọsteli 12:2). Ọba Hẹrọdu "fi idà paá," Jakọbu èyí tí o ńtọ́kasí bíbẹ́lórí. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yí àwọn ikú àwọn àpọ́stélì tí ó kù ni a mọ̀ nípasẹ̀ ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ìjọ, nítorí náà àwa kò gbọ́dọ̀ gbé ara lé èyíkéyì àwọn àkọsílẹ̀ míìrán. Èyí tí ó wọ́pọ̀ jùlọ tí a gbà nípa ikú àpọ́stélì Peteru ni wípé a kàn-án mọ́ àgbélèbú ní ìdoríkodò ni ori àgbélèbú tí ó dàbí àmì x ní Romu ní ìbámu pẹ̀lú àsọtélẹ̀ Jésù (Johannu 21:18). Ìwọ̀nyìí ni àwọn "ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́" tí ó wọ́pọ̀ jùlọ nípa ikú àwọn àpọ́stélì tí ó kù:

A pa Matteu, láti ọwọ́ ọgbẹ́ nípasẹ̀ idà, fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ ní Etiopia. Johannu kojú ikú fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbàtí a sèé nínú agbada ńlá tí ó kún fún òróró gbígbóná ní ìgbà inúnibíni ni Romu. Ṣùgbọ́n, a gbàá lọ́wọ́ ikú ní ọ̀nà ìyanu. Lẹ́yìn náà a lée lọ sí ẹ̀wọ̀n maini ní èrékùsù Patmosi. Òun kọ ìwé Ìfihàn ti àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní Patmọsi. Nígbà tí o yá, a dá Johannu àpọ́stélì sílẹ̀ tí òun si padá sí ibi ti a mọ̀ sí Tọ́kìí ní òde-òní. Òun kú gẹ́gẹ́ bíi àgbàlagbà arúgbó, àpọ́stélì kan soso tí ó kù ní àláàfíà.

Jakọbu, arákùnrin Jésù (òun kìí ṣe àpọ́stélì kan tí a fọwọ́ sí), ni aládarí ìjọ ní Jerusalẹmu. A ju òun láti ibi sóńsó tẹmpili ti gúsù mọ́ ilà oorùn (èyí tí ó ju ìwọn ọgọ́rùún sílẹ̀ lọ) nígbà tí òun kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Kristi. Nígbàtí wọn ṣe àwárí wípé òun ye ṣiṣubú náà, àwọn ọ̀tá rẹ̀ lùú pa pẹ̀lú kùmọ̀ kan. Èyí ni a rò wípé ó jẹ́ ibi sóńsó kannàá tí èṣù gbé Jésù lọ ní ìgbà ìdanwò rẹ̀.

Batilomiu, tí a tún mọ̀ bíi Nataniẹli, jẹ́ ajíǹrere sí Aṣia. Òun jẹ́rìí ní ibi tí ó jẹ́ Tọ́kìí ní òde-òní tí a sì paá fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún wíwàasù ní Amenia, nípa nínàá dójú ikú pẹ̀lú kòbókò. A kan Andérù mọ àgbélèbú tí ó dà bi àmì x ní Girisi. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ-ogun méje nàá, wọn dèé mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú okùn láti jẹ́ kí ìrora rẹ pọ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ jábọ̀ wípé nígbàtí wọn ńdarí rẹ̀ lọ sí àgbélèbú náà, Andérù bẹ́rí fún-un pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí: "Èmi ti ńpòngbe típẹ́ tí mo sì ńretí wákàtí ìdùnú yìí. A ti ya àgbélèbú sọ́tọ̀ nípasẹ́ ara Jésù tí a gbékọ́ sórí rẹ́." Òun tẹ̀síwájú láti máa wàásù fún àwọn apọ́nilójú rẹ̀ fún ọjọ́ méjì títí tí òun fi kú. Àpọ́stélì Tọmasi ni a gún pẹ̀lú ọkọ̀ ní India ní àkókò ìrìn-àjò rẹ̀ láti fi ìjọ lọ́lẹ̀ níbẹ̀. Matayasi, àpọ́stélì tí a yàn láti dípò Judasi Iskariọti tí ó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, ni a sọ l'ókùta tí a sì bẹ́ẹ lórí. Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù ni a dá lóró tí a sì bẹ́ lórí láti ọwọ́ Ọba Nero burúkú ní Romu ni ọdún 67 lẹ́yìn ikú Kristi. Àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ nípa àwọn àpọ́stélì tí ó kù náà wà ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyì tí ó ní ìtàn tàbí àtìlẹhìn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó ṣeé gbáralé.

Kò ṣe pàtàkì bí àwọn àpọ́stélì ṣe kù. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni wípé gbogbo wọn ni wọn ṣetán láti kú fún ìgbàgbọ́ wọn. Bí Jésù kò bá jí dìde, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kò bá mọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ènìyàn kò ní kú fún ohun tí wọn mọ̀ wípé irọ́ ni. Òtítọ́ wípé gbogbo wọn setán láti kú ikú gbígbóná, tí wọn kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn nínú Kristi, jẹ́ ẹ̀rí wípé wọn jẹ́rìsí àjíǹde Jésù Kristi ní òtítọ́.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ ikú àwọn àpọ́stélì? Báwo ni àwọn àpọ́stélì kọ̀ọ̀kan ṣe kú?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries