settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Ìjọba Ẹgbẹ̀rún ọdún, ṣé ó yẹ kí á gbàá bẹ́ẹ̀?

Idahun


Ìjọba Ẹgbẹ̀rún ọdún náà jẹ́ àkórí tí a fún ẹgbẹ̀rún ọdun tí Jésù Kristi yóò ṣe àkóso ayé. Àwọn kan túmọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdun ní ọ̀nà àpejúwe. Àwọn kan rí ẹgbẹ̀rún ọdun bíi àkànlò-èdè lásán ni wípé "àkókò ìgbà pípẹ́", tí kìí kàn ṣe pé ó rí bẹ́ẹ̀, tí kíì ṣe ìgbà tí Jésù yóò darí ayé nínú ara. Ṣùgbọ́n, ọ̀nà mẹ́fà nínú Ìwé Ìfihàn 20:2-7 ni a ti ri wípé, Ìjọba Ẹgbẹ̀rún ọdún náà ní pàtó jẹ́ àsìkò ẹgbẹ̀rún ọdún. Bí Ọlọ́run bá fẹ́ ṣọ nípa "àkókò ìgbà pípẹ́", Òun yóò kúkú ti ṣọ ní pàtó láì ṣe àwítúnwí asán nípa gbèdéke àsìkò náà.

Bíbélì náà ṣọ fún wa pé nígbà tí Kristi bá padà sí ayé, Òun yóò fi ara Rẹ̀ jẹ Ọba ní Jèrúsálẹ́mù, yóò jókó lórí ìtẹ́ Dáfídì (Luku 1:32-33). Májẹ̀mu aláìlódiwọ̀n náà pè fún Ìpadàbọ̀ Kristi nínú ara láti fìdí Ìjọba náà múlẹ̀. Májẹ̀mu ti Ábúráhàmù náà ṣ'èlérí ilẹ̀, ọmọ ati aláṣẹ, àti ìbùkún ẹ̀mí fún Isrẹli (Jẹnẹsisi 12:1-3). Májẹ̀mu ti Palẹ́sítínìì náà ṣ'èlérí ìmúpadàbọ̀sípò ilẹ̀ àti gbígbé ilẹ̀ náà fún Isrẹli (Deutarọnọmì 30:1-10). Májẹ̀mu ti Dáfídì náà ṣ'èlérí ìdáríjìn fún Isrẹli—ọ̀nà tí a ó fi bùkún orílẹ́-èdè náà (Jeremiah 31:31-34).

Nígbà ìpadàbọ̀ kejì náà, àwọn májẹ̀mu yìí yóò wàá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ó ti tún Isrẹli kójọpọ̀ láti àwọn orílẹ́-èdè náà (Matteu 24:31), yí wọn padà (Sẹkariah 12:10-14), tí a ó si mú wọn padà bọ̀ sí ilẹ̀ náà lábẹ́ ìsàkóso Jésù Kristi, Mesiah náà. Bíbélì náà sọ nípa ìlànà láàrin ẹgbẹ̀rún ọdun náà gẹ́gẹ́ bí agbègbè tí ó pé ní ẹ̀mí ati lára. Yóò jẹ́ àkókò àlàáfía (Mika 4:2-4; Isaiah 32:17-18), ayọ̀ Isaiah 61:7, 10), ìtùnú (Isaiah 40:1-2), ìṣẹ́ àti àìsàn kò ní sí (Amọsi 9:13-15; Joẹli 2:28-29). Bíbélì tún sọ fún wa wípé àwọn onígbàgbọ́ nìkan ni yóò wọ ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún náà. Nítorí èyí, yóò jẹ́ àkókò òdodo pátápátá (Matteu 25:37; Orin Dafidi 24:3-4), Ìgbọràn (Jeremiah 31:33), ìwà mímọ́ (Isaiah 35:8), òtítọ́ (Isaiah 65:16), àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí mímọ́ (Joẹli 2:28-29). Kristi yóò ṣe àkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba (Isaiah 9:3-7; 11:1-10), pẹ̀lú Dáfídì gẹ́gẹ́ bí atọ́ni (Jeremiah 33:15-21; Amọsi 9:11). Àwọn Ìjòyè àti ọlọ́lá náà yóò ṣe àkóso (Isaiah 32:1; Matteu 19:28), Jèrúsálẹ́mù ni yóò sì jẹ́ Olú-ìlú gbogbo ayé (Sẹkariah 8:3).

Ìwé Ìfihàn 20:2-7 sọ ní pàtó ìgbà tí Ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò jẹ́ Yàtọ̀ sí àwọn àyọkà wọ̀nyìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àyọkà míìrán náà tọ́ka síi wípé Mesiah yóò jọba lórí ilé ayé nítòótọ́. Ìmúṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlérí Ọlọ́run nííṣe pẹ̀lú ìjọba ọjọ́ iwájú nínú ara. Kò sí ìdí gbòógì kan láti sọ wípé ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún náà kò rí bẹ̀ àbí kí á sọ wípé kò ní jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún kan.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Ìjọba Ẹgbẹ̀rún ọdún, ṣé ó yẹ kí á gbàá bẹ́ẹ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries