settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìhìnrere aásíkí?

Idahun


Ní inú ìhìnrere aásìkí tí a tún mọ̀ sí "'Ìrìn ti Ọ̀rọ̀ Ìgbàgbọ́ (Word of Faith Movement)," onígbàgbọ́ ní a sọ fún láti lo Ọlọ́run, ṣùgbọn ṣá òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí Kristiẹni èyí tí ó bá bíbélì mu jẹ́ ìdàkejì—Ọlọrun ńlo onígbàgbọ́. Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ọlọ́run ti aásìkí ńrí Ẹmí Mímọ gẹ́gẹ́ bíi agbára kan tí a lè múlò fún ohunkóhun tí onígbàgbọ́ bá ńfẹ́. Bíbélì ńkọ́ni wípé Ẹmí Mímọ jẹ́ Ẹnìkan tí ó ńfún onígbàgbọ́ lágbára láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìrìn ìhìnrere aásìkí farajọ ní tìmọ́tímọ́ àwọn ẹgbẹ́ olójúkòkúrò kan tí ó rápálá wọ ìjọ àkọkọ. Pọ́ọ̀lù àti àwọn àpọstélì yòókù kò fààyè gba àwọn olùkọ èké náà tábí ronú pọ pẹlú àwọn tí ó ńfi ẹ̀kọ́ òdì náà lọ́lẹ̀. Wọn dá wọn mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi àwọn olùkọ èké tí ó léwu ti wọn sì rọ àwọn Kristiẹni láti yẹra fún wọn.

Pọ́ọ̀lù kìlọ fún Tímótíù nípa irú àwọn ènìyàn báwọ̀nyìí nínú 1 Timoteu 6:5, 9-11. Àwọn ènìyàn tí "ọkàn ìdíbàjẹ''ńlérò wípé ìwà bí ọlọ́run ti jẹ́ ọ̀nà sí èrè àti àwọn ìfẹ́ wọn fún ọrọ̀ jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi pàkúté tí ó mú wọn wọ ''inú ìparun àti ìdibàjẹ'' (ẹsẹ 9). Lílépa ọrọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó léwu fún àwọn Kristiẹni àti èyí tí Ọlọ́run kìlọ nípa rẹ̀: Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo. Èyí tí àwọn míìrán lépa tí a sì mú wọn ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ, wọn sì fi ìbànújẹ púpọ gún ara wọn ní ọ̀kọ̀'' (ẹsẹ 10). Bí ọrọ̀ bá jẹ́ èrè ìdí ìlépa fún ẹni ìwà bí ọlọ́run, Jésù yóò ti lépa rẹ̀. Ṣùgbọn kò lépa rẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ ó gbà láti má ní ibi tí yóò fi orí Rẹ̀ lé (Matteu 8:20) ti Òun si ńkọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. A tún gbọ́dọ̀ ṣè ìrántí wípé ọmọ ẹ̀hìn kan ṣoṣo tí ọrọ̀ jẹ lógún ni Júdásì.

Pọ́ọ̀lù sọ wípé ojúkòkúrò jẹ ìbọrìṣà (Efesu 5:5) tí ó sì pàṣẹ fún àwọn ará Éfésù láti yẹra fún ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ìròyìn kan ti ìwà àìmọ tàbí ojúkòkúrò wá (Efesu 5:6-7). Ìkọni aásìkí ṣè ìdíwọ fún Ọlọ́run láti ṣe iṣẹ ní Òun tìkalárarẹ̀, èyí tí ó túmọ̀ sí wípé Ọlọ́run kìí ṣe Olúwa ohun gbogbo nítorí Òun kò lè ṣe iṣẹ àfì ìgbà tí a bá jọ̀wọ́ Rẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ, gẹ́gẹ́ bí ẹkọ ọ̀rọ̀ Ìgbàgbọ́, kìí tẹríba sí ìgbẹkẹle nínú Ọlọ́run; ìgbàgbọ́ jẹ́ àgbékalẹ̀ nípa èyí tí a fi ńṣe àyídáyidà àwọn òfin ẹ̀mí èyítí àwọn olúkọ aásíkí gbàgbọ́ wípé ó ńṣakóso àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ náà ''Ọ̀rọ̀ ti Ìgbàgbọ'' èyí túmọ̀ sí, ìrìn yí ńkọ ni wípé ìgbàgbọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ohun tí à ńsọ jù ẹni tí a gbẹ́kẹ̀lé lọ tàbí àwọn òtítọ́ tí a gbà mọ́ra àti èyí tí a jẹ́rìsí ní ọkàn wa.

Ọ̀rọ̀ kan tí àwọn olùkọ aásìkí yàn láàyò jẹ́ ìjẹ́wọ́ dídára.'' Èyí ńtọ́kási ìkọni wípé àwọn ọ̀rọ̀ tìkalára wọn ní agbára ìṣẹdá. Ohun tí o bá sọ, àwọn olùkọ aásìkí jẹ́wọ́, ni ó ńpinnu ohun gbogbo tí yóò ṣẹlẹ sí ọ. Àwọn ìjẹ́wọ́ rẹ, pàápàá jùlọ àwọn ojúrere tí o bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ní ó gbọ́dọ́ là kalẹ̀ ní dídara àti láì yẹsẹ̀. Lẹ́hìn náà Ọlọ́run nílò láti dáhùn (bí ẹni wípé ènìyàn ní ǹǹkan gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run!). Síbẹ̀, agbára Ọlọ́run láti bùkún fún wa kò sopọ̀mọ́ orí ìgbàgbọ́ wa. Jakọbu 4:13-16 tako ẹ̀kọ́ yìí ní kedere: ''Ẹ wá nísisìyí, ẹyín tí ń wípé lónì ni tàbí àwá ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì pé ọdún kan níbẹ, a ó sì ṣòwò, a ó sí jèrè. Nígbà tí ẹyin kò mọ ohun tí ó hù lọla. Kínni ẹmi yín? Ìkùukùu ṣáà ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ, lẹhìn náà a sì túká lọ." Jìnà sí sísọ àwọn ohun sí ìwásáyé ní ọjọ́ iwájú, àwa kò tilẹ̀ mọ ohun tí ọjọ́ ọla yóò mú wá tàbí bóyá àwa yóò tilẹ̀ wà láàyè.

Dípo ṣíṣe ìdàmú lóri pàtàkì ọrọ̀, Bíbélì kìlọ nípa lílépa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́, ní pàtàkì jùlọ àwọn aládarí ní inú ìjọ (1 Timoteu 3:3), ní láti bọ́ lọ́wọ́ ìfẹ́ owó (Heberu 13:5). Ìfẹ́ ti owó ńyọrí sí onírúurú búburú gbogbo (1 Timoteu 6:10). Jésù kìlọ̀, ''Ó sì wí fún wọn pé, Kíyèsára, kí ẹ sì má a ṣọra nítorí ojú kòkòro, nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kìí dúró nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní'' (Luku 12:15). Ní ìdàkejì gédégbé sí ìhìnrere aásìkí èyítí ńtẹnumọ níní owó àti àwọn ohun ìní nínú ayé, Jésù sọ wípé, ''Ẹ má ṣe to ìṣura yín jọ fún ara yín, níbití kòkòrò àti ìpáàrá ìbá jẹ, àti níbití àwọn olè ìrunlẹ tí wọn sí ń jalè'' (Matteu 6:19). Àìlèṣe ìbálàjà àwọn àtakò láàrín ìkọni aásìkí àti ti Jésù Kristi Olúwa wa ni a lè ṣe àròpọ rẹ̀ ní èyí tí ó dára jùlọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ní Matteu 6:24, ''Ìwọ kò lè sin Olúwa pẹlú Mámónì."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìhìnrere aásíkí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries