settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó ti ẹ̀yà ara kannáà?

Idahun


Nígbà tí Bíbélì sọrọ nípa ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà, kò mẹnubà ní gbangba ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó ti ẹ̀yà ara kannáà. Ó hàn kedere, bí o tilẹ̀ jẹ wípé, Bíbélì bu ẹnu àtẹ lu ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà gẹgẹ bí ẹṣẹ àìmọ àti ohun tó lòdì sí ìwà ẹdá. Lẹfitiku 18:22 ṣe ìdámọ̀ ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà gẹgẹ bí ohun ìríra , ẹṣẹ ìríra. Romu 1:26-27 kéde wípé ìpòhungbẹ ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà bíi ìṣe tí o ti ni lójú, tí ó lòdì sí ìwà ẹdá, ìfẹkúfẹ, àti èyí tí kò bójúmu. Kọríntì kínní 6:9 sọ wípé àwọn tí ó nṣe ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà jẹ àláìṣododo àti wípé wọn kì yóò jogún ìjọba Ọlọrun. Níwọn ìgbà tí ìpòhungbẹ ìbálòpọ láàrín ẹ̀yà ara kannáà àti àwọn ìṣe yìí ni a bẹnu àtẹ lù nínú Bíbélì. Ó hàn kedere wípé "gbígbéyàwó" láàrìn ẹ̀yà ara kannáà kìí ṣe ìfẹ ti Ọlọrun, àti wípé yóò jẹ, ní òtítọ́, ìwà ẹṣẹ.

Nígbàkúgbà ti Bíbélì náà bá mẹnuba ìgbéyàwó, ó jẹ láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Ìgbà àkọkọ ti a mẹnubà ìgbéyàwó, Jẹnẹsísì 2:24 ṣe àpéjúwe rẹ gẹgẹ bí ọkùnrin kan ńfi àwọn òbi rẹ sílẹ tí a sì soópọ̀ pẹ̀lú ìyàwo rẹ. Nínú àwọn àyọkà tí ó ní nínú àwọn ìtọ́ni nípa ìgbéyàwó, bíi 1 Kọríntì 7:2-16 àti Efesu 5: 23-33, Bíbélì ṣe ìdámọ̀ ìgbéyàwó kedere gẹ́gẹ́ bíi láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Sísọrọ nípa ti Bí-bélì, ìgbéyàwó jẹ àsopọ fún gbogbo ìgbà ayé tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan, ní pàtàkì fún èrèdí láti kọ àti pípèsè àyíká tí ó dúróṣinṣin fún ìdílé náà.

Ṣùgbọ́n, a kò ní láti lo Bíbélì níkàn ṣoṣo, láti fi ṣe àpéjùwe òye ti ìgbéyáwò yìí. Ojú ìwòye ìgbéyáwò ti Bíbélì ni ó ti jẹ òye ti àgbáyé nípa ti ìgbéyáwò nínú gbogbo ìtàn ọlàjú ènìyàn ní àgbáyé. Ìtàn ńjiyàn lòdì sí ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin. Ẹ̀kọ́ ìmọ nípa èrò àti ìhùwàsí aláìlẹsìn ìgbàlódé ṣe ìdámọ̀ wípé àwọn ọkunrin àti obìnrin jẹ onírònú àti onímọlára tí a ṣe ètò láti gbé ara ẹni ní ìgbọnwọn. Nípa ti ìdílé, àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìmọ nípa èrò àti ìhùwàsí jà wípé àsopọ tí ó wà láàrín ọkùnrin àti obìnrin kan nínú èyítí ó jẹ wípé àwọn méjèèjì ní yóò ṣe ojúṣe l'ọkùnrin àti l'óbìnrin gẹ́gẹ́ bíi àwọn àwòkọ́ṣe dídára jẹ́ àyíká tí ó dára jùlọ láti tọ́ àwọn ọmọ dáradára dàgbà. Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa èrò àti ìhùwàsí ńjìyàn lòdì sí ìgbeyàwo ọkùnrin sí ọkùnrin. Nínú ìṣẹdá/ti ara, ó hàn kedere, wípé àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ni a ṣẹ̀dá láti ''wà ní ìbámu'' papọ̀ ní ti ìbálòpọ. Pẹ̀lú ète ti ìbálòpọ ní wípé ó wà fún ìbísí ti ''àdáyébá'', ó hàn kedere wípé ìbáṣepọ ti ìbálòpọ láàrín okùnrin kan àti obìnrin kan nìkan ni ó lè mú ète yìí ṣẹ. Ìṣẹdá ńjiyàn lòdì sí ìgbeyàwo ọkùnrin sí ọkùnrin.

Nítorí náà, bí Bíbélì, ìtàn, ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìmọ nípa èrò àti ìhùwàsí, àti ìṣẹdá bá ńjùmọ jiyàn fún ìgbéyàwó wípé kí ó jẹ láàrin okùnrin kan àti obìnrin kan — kílódé tí àrínyànjíyàn kan fi wá wà ní òní? Kí-lódé tí àwọn tì wọn tako ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó ẹlẹ́yà ara kán náà ṣe ńgba ìsàmàmísí gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó kún fún ìkórira, onígbònára, kò níí fi ṣe bí a ṣe gbé àtakò náà kalẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tó? Kílódé tí àjọ tí ó ńjà fún ẹtọ oní bàlópọ ọkùnrin sí ọkùnrin ṣe ńtì síwájú tìbínú tìbínú fún ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó ẹlẹyà ara kan náà nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn, àwọn ẹlẹsìn àti aláìṣẹsìn, ńgbárùkù ti—tàbí ó kéré jùlọ wọn ńtakòó—àwọn tọkọtaya ọkùnrin sí ọkùnrin ńní gbogbo ẹtọ kan náà lábẹ òfin gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya tí ó ti ṣe ìgbéyàwó pẹlú àwọn ohun tí o farajọ ìgbéyàwó tí ó bá ojú mu?

Ìdáhùn, gẹ́gẹ́ bíi ti Bíbélì, ni wípé gbogbo ènìyàn ńti inú mọ wípé ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kan náà jẹ́ àìmọ àti èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹdá, àti wípé ọnà kan ṣoṣo láti tẹ ìmọ àtọrunwá yìí mọlẹ ní nípa ṣíṣe àtúnṣe láti rí ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà bí èyí tí ó dára àti títako èyíkéyì àti gbogbo àtakò síi. Ọnà tí ó dára jùlọ láti ṣe àtúnṣe láti rí ìbálòpọ láàrìn ẹ̀yà ara kannáà bí èyí tí ó dára ni gbígbé ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ ìgbeyàwo oní ẹ̀yà ara kannáà ní ẹgbẹ kẹgbẹ sí ìpele kan náà pẹlú ìgbéyàwó ti ìbílẹ oní ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀tọ̀. Romu 1:18-32 ṣe àpèjúwe èyí. Òtítọ ni ó ti di mí mọ̀ nítori wípé Ọlọ́run ti jẹ kí ó hàn gbang-ba. Òtítọ náà ni a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a sì rọ́pò pẹlú irọ́. Irọ náà ni a gbé lárugẹ àti òtítọ náà ní a tẹ̀ mọ́lẹ̀ tí a sì takò. Ìrunú àti ìbínú tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fihàn sí jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn ìbálòpọ ọkùnrin sí ọkùnrin sí ẹnikẹni tí o bá lòdì sí wọn, ní òtítọ́, jẹ ìtọ́kasí wípé wọ́n mọ̀ wípé ipò wọn kò ṣeé gbèjà. Gbígbìyànjú láti borí ipò tí kò lágbára nípa gbígbóhùn sókè jẹ́ ọgbọ́n àtijọ́ nínú ìwé àrínyànjiyàn. Kò tún wá sí àpèjúwe kankan tí o péye fún titi àgbékalẹ àwọn ẹ̀tọ́ ti ìgbàlódé nípa ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin ju Romu 1:31, wọn jẹ ''aláìlòye, aláìnígbàgbọ, aláìníọkàn, aláìláànú.''

Láti kàán ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó oní ẹ̀yà ara kannáà nípá yóò jẹ láti fí ọwọ́ sí ìgbé-ayé ìbálòpọ ẹlẹyà ara kan náà, èyí tí Bíbélì dálẹbi kedere àti pẹ̀lú ìtẹpẹlẹmọ gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Kristiẹni gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin tako èrò ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó oní ẹ̀yà ara kannáà náà. Síwájú si, àwọn ìjiyàn kan tí o lágbára ati tí ó lọgbọn ńbẹ tako ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó oní ẹ̀yà ara kannáà tí ó dáyàtọ̀ pátápátá sí láti inú Bíbélì. Ènìyàn kò nílò láti jẹ ajíhìnrere Kristiẹni láti ṣe ìdámọ wípé ìgbéyàwó wà láàrin ọkùnrin àti obìnrin kan.

Gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì, ìgbéyàwó ni a yàn nípa Ọlọrun láti jẹ́ láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan (Jẹnẹsisi 2:21-24; Matteu 19:4-6). Ìgbeyàwo ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbeyàwo oní ẹ̀yà ara kannáà jẹ́ ìgbékalẹ ìdibàjẹ́ nípa ìgbéyàwó àti ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun tí ó ṣẹda ìgbéyàwó. Gẹgẹ bíi Kristiẹni, a kò gbọ́dọ̀ fi ààye gbà ẹ̀ṣẹ̀ tàbí fojú paá rẹ́. Dípò, àwa ńláti pín ìfẹ Ọlọ́run àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún gbogbo ènìyàn, àti pẹlú ẹni tí o ńṣe ìbálòpọ pẹlú elẹyà ara kan náà, nípasẹ̀ Jésù Kristi. A gbọ́dọ̀ sọ òtítọ nínú ìfẹ (Efesu 4:15) kí a sì jà fún òtítọ pẹ̀lú ''ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìbọ̀wọ̀'' (1 Peteru 3:15). Gẹgẹ bíi Kristiẹni, nígbà tí a bá dúró fún òtítọ tí èsì rẹ̀ sí jẹ́ àwọn ìtakò sí ara ẹni, àwọn ẹgàn, àti inúnibíni, kí àwa kí ó rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù: "Bí aráyé bá kórira yín, ẹ mọ̀ pe, o ti kórìra mi ṣaju yin. Ibaṣepe eyin iṣe ti ayé, ayé iba fẹ awọn tirẹ̀. Ṣugbọn nitoriti ẹyin kì iṣe tí ayé, ṣùgbọn èmí ti yàn yín kúrò nínú ayé. Nítorí eyi li ayé ṣe kórìra yín '' (Johannu 15:18-19).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó ọkùnrin sí ọkùnrin/ìgbéyàwó ti ẹ̀yà ara kannáà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries