settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àwọn ìgbésẹ̀ sí ìgbàlà?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ńwa "àwọn ìgbésẹ̀ sí ìgbàlà." Àwọn ènìyàn fẹ́ràn èrò ìwé ìtọ́ni pẹ̀lú ìgbésẹ̀ márùn-ún wípé, bí a bá tẹ̀lee, yóò jásí ìgbàlà. Àpẹẹrẹ èyí ni ẹ̀sin Ìmàle pẹ̀lú Òpó Márùn-ún rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀sin Ìmàle, bí a bá tẹ̀lé àwọn Òpó Márùn-ún yìí, ìgbàlà yóò dájú. Nítorí àbá ètò ní ṣìṣẹntẹ̀lé sí ìgbàlà dára, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àwùjọ Kristiẹni ṣe àṣìṣe pípèsè ìgbàlà gẹ́gẹ́ bíi àyọrísí ètò ní ṣìṣẹntẹ̀lé. Ìjọ Kátólíkì ní àwọn ètò ìyàsọ́tọ̀ méje. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà ìjọ Kristiẹni fi ìtẹ̀bọmi, ìjẹ́wọ́ ní gbangba, yíyípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìfèdè fọ̀, abbl., kún un gẹ́gẹ́ bíi ìgbésẹ̀ sí ìgbàlà. Ṣùgbọ́n Bíbélì pèsè ìgbésẹ̀ kan sí ìgbàlà. Nígbàtí asọ́bodè ará Filipi bi Pọ́ọ̀lu léèrè, "Kínni kí èmi kí ó ṣe kí n le là? Pọ́ọ̀lù dáa lóhùn, "Gba Jésù Krístì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là" (Iṣe àwọn Apọsteli 16:30).

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà ni "ìgbésẹ̀" kansoso sí ìgbàlà. Ọ̀rọ̀ Bíbélì hàn kedere gidigidi. Gbogbo wa ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run (Romu 3:23). Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ní ẹ̀tọ́ sí ìyapa ayérayé kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run (Romu 6:23). Nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa (Johannu 3:16), Ọlọ́run gbe àwọ̀ ènìyàn wọ̀ Òun sì kú ní ipò wa, láti gba ìjìyà tí ó tọ́ sí wa (Romu 5:8; 2 Kọrinti 5:21). Ọlọ́run ṣe ìlérí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyè ayérayé ní ọ̀run fún gbogbo àwọn tí ó gba Jésù Krístì gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà, nípa ore-ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (Johannu 1:12; 3:16; 5:24; Iṣe àwọn Apọsteli 16:31).

Ìgbàlà kìí ṣe nípa àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé láti jèrè ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristiẹni gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristiẹni gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà ní gbangba. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristiẹni gbọ́dọ̀ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristiẹni gbọ́dọ̀ fi ara wọn jìn sí ìgbọ̀ràn sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, àwọn wọ̀nyìí kìí ṣe àwọn ìgbésẹ̀ sí ìgbàlà. Wọ́n jẹ́ àwọn àbájáde ti ìgbàlà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, a kò lè j'èrè ìgbàlà. A lè tẹ̀lé ìgbésẹ̀ ẹgbẹ̀rún (1000), kò sì ní tó. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi ní láti kú ní ipò wa. A kò ní agbára rárá láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Ọlọ́run tábi kí á fọ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run nìkan ló lè parí ìgbàlà wa, bẹ́ẹ̀ ni Òun sì ṣe. Ọlọ́run tìkararẹ̀ ti parí "àwọn ìgbésẹ̀" náà ó sì pèsè ìgbàlà fún ẹnikẹ́ni tí yóò bá gbà á lọ́wọ́ Rẹ̀.

Ìgbàlà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ kìí ṣe nípa àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyìí. Ó jẹ́ nípa gbígba Kristi gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà tí ó sì mọ̀ wípé Òun ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà fún wa. Ọlọ́run ńbèèrè ìgbésẹ̀ kan lọ́wọ́ wa—gbigba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí á sì gbẹ́kẹ̀le Òun nìkan pátápátá gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà ìgbàlà. Èyí ni ó mú ìyàtọ̀ bá ìgbàgbọ́ àwọn Kristiẹni àti àwọn ẹ̀sìn àgbáyé yòókù, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tí ó ní àkójọ ìgbésẹ̀ tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé kí á ba lè gba ìgbàlà. Ìgbàgbọ́ àwọn Kristiẹni mọ̀ wípé Ọlọ́run ti parí àwọn ìgbésẹ̀ náà Òun sì ńpe àwọn tí yóò ronúpìwàdà láti gbàá nípa ìgbàgbọ́.

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni àwọn ìgbésẹ̀ sí ìgbàlà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries