settings icon
share icon
Ibeere

Ìgbà wo ni ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpọ́njú náà?

Idahun


Àkókò ìgbàsókè ní ìbámu pẹ̀lú ìpọ́njú jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn nínú ìjọ lóòní. Àfojúsùn mẹ́ta tí ó ṣe kókó ni wípé ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìpọ́njú, ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tàbí láàrin ìpọ́njú àti ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú. Àfojúsùn kẹrin, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńpè ní ìgbàsókè tí yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìbínú, ó jẹ́ àyípadà bíntí lórí ti ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ láàrin ìpọ́njú.

Àkọ́kọ́, ó ṣe pàtàkì láti mọ èrèdí ìpọ́njú náà. Gẹ́gẹ́ bíi àkọsílẹ̀ ìwé Daniẹli 9:27, ọdún méje kan ńbọ̀ (ọdún méje) èyítí kò tìí dé. Gbogbo àṣọtẹ́lẹ̀ Daniẹli nípa àádọ́rin ó lé méje (Daniẹli 9:20-27) ńsọ nípa orílẹ́-èdè Isrẹli. Ó jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run tẹjú mọ́ Ísráẹ́lì lọ́kúnkúndùn. Àádọ́rin àti méje, ìpọ́njú náà, gbọ́dọ̀ jẹ́ ìgbà tí Ọlọ́run ńbá Isrẹli da òwò pọ̀. Nígbàtí èyí kò tọ́kasi wípé ìjọ ò ní sí níbẹ̀ ní dandan, ó yẹ kí á máa bèèrè ìdí tí ìjọ ṣe gbọ́dọ̀ wà ní ayé ní àkókò náà.

Àyọkà tí ó ṣe àlàyé ìgbàsókè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wà nínú 1 Tẹssaloníka 4:13-18. Ó sọ wípé gbogbo onígbàgbọ́ tí ó wà láàyè pẹ̀lú àwọn òkú nínú Olúwa yóò lọ pẹ̀lú Jésù Olúwa ní òfuurufú, wọn ó sì wà pẹ̀lú Rẹ̀ títí láíláí. Ìgbàsókè jẹ́ ìyọkúrò àwọn ènìyàn Ọlọ́run kúrò láyé. Ẹsẹ díẹ̀ nitẹsiwájú nínú Tẹssalonika kínní 5:9, Pọ́ọ̀lù sọ wípé, "Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi". Ìwé Ifihan, tí ó sọ ní pàtó nípa àwọn àkókò ìpọ́njú náà jẹ́ ìwàásù àṣọtẹ́lẹ̀ bí Ọlọ́run yóò ṣe tú ìbínú rẹ̀ jáde sí ayé ní àkókò ìpọ́njú náà. Kò jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé fún Ọlọ́run láti ṣe ìlérí fún àwọn onígbàgbọ́ wípé wọn kò ní jìyà, kí Òun sì fi wọ́n sílẹ̀ sáyé láti jẹ ìyà ìpọ́njú náà. Òdodo ni wípé Ọlọ́run ṣe ìlérí láti gba àwọn Kristiẹni lọ́wọ́ ìbínú ní àkókò díẹ̀ lẹ́hìn tí ó ṣe ìlérí láti yọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ kúrò láyé, jọ wípé Òun so àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèjì yìí papọ̀.

Àyọkà míìrán tí ó ṣe kókó lórí àkókò ìgbàsókè ni ìwé Ìifihan 3:10, nínú èyí tí Kristi ṣe ìlérí láti gba àwọn onígbàgbọ́ ni "àkókò ìdánwò" tí ńbọ̀ wá bá ayé. Èyí lè ní ìtumọ̀ sí nǹkan méjì. Bóyá kí Kristi pa àwọn onígbàgbọ́ mọ́ nígbà ìdánwò tàbí kí Òun gba àwọn onígbàgbọ́ kúrò nínú ìdánwò náà. Méjèèjì yìí jẹ́ ojúlówó ìtumọ̀ sí "kúrò" nínú èdè Gíríkì. Ṣùgbọ́n, ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn nńkan tí a ṣe ìlérí láti pa onígbàgbọ́ mọ́ kúrò. Kìí ṣe ìdánwò nìkan, ṣùgbọ́n "wákàtí" ìdánwò. Kristi ṣe ìlérí láti pa onígbàgbọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdánwò náà, tí à ńpè ní, ìpọ́njú náà. Ète ìpọ́njú náà, ète ìgbàsókè náà, ìtumọ̀ ìwé Tẹssalonika kínní 5:9 àti ìtumọ̀ ìwé Ifihan 3:10, ṣe àtìlẹhìn tí ó hàn kedere fún ipò ìgbàsókè wípé yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìpọ́njú wọlé. Bí a bá túmọ̀ Bíbélì ní àkọsílẹ̀ ṣísẹ̀ntẹ̀lé, gbígbà wípé ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìpọ́njú ni ó jẹ́ ìtumọ̀ tí ó faramọ̀ Bíbélì jùlọ.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ìgbà wo ni ìgbàsókè yóò ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpọ́njú náà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries