settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni èmi ṣe lè ní ìdánilójú ìgbàlà mi?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-lẹ́hìn Jésù Kristi ni wọn ńwá ìdánilójú ìgbàlà ni ibi tí kò tọ́. A máa ńfẹ́ wá ìdánilójú ìgbàlà nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run ńṣe nínú ayé wa, nínú dídàgbà nínú ẹ̀mí, nínú iṣẹ́ rere àti gbígbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tí ó farahàn nínú ìrìn Kristiẹni wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn nǹkan yìí lè jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà, àwọn kọ́ lo yẹ kí a dá ìdánilójú ìgbàlà wa lé., Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a wá ìdánilójú ìgbàlà wa nínú òtítọ́ ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó yẹ kí a ní ìgbàgbọ́ ìgboyà wípé a gbà wá là lórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti sọ, kìí ṣe nítorí àwọn ìrírí wa.

Báwo ni ìwọ ṣe lè ní ìdánilójú ìgbàlà rẹ? Yẹ 1 Johannu 5:11–13 wò: "Ẹ̀rí náà si li èyí pé: Ọlọ́run fún wa ni ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí si ńbẹ nínú Ọmọ rẹ̀. Ẹnití ó bá ni Ọmọ, ó ní ìyè; ẹnití kò bá sì ní Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè. Nǹkan wọ̀nyìí ni mo kọ̀wé rẹ̀ si yín àní si ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun." Tani ẹni náà tí ó ni Ọmọ? Àwọn náà ni àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ (Johannu 1:12). Bí o bá ní Jésù, o ní ìyè. Kìí ṣe ìyè díẹ̀, ṣùgbọ́n ayérayé.

Ọlọ́run ńfẹ́ kí a ní ìdánilójú ìgbàlà wa. Àwa kò gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé Kristiẹni wa kí ó má yé wa tàbí kí a máa ṣe àní-àní bóyá a ti gbà wá là ní òtítọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀. Ìdí nìyí tí Bíbélì fi fi ètò ìgbàlà hàn kedere tó bẹ́ẹ̀ gẹ́. Gba Jésù Kristi gbọ́ (Johannu 3:16; Iṣe awọn apọsteli 16:31). "Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ Jésù li Olúwa, tí ìwọ si gbàgbọ́ li ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jíi dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ là" (Romu 10:9). Ǹjẹ́ ìwọ ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ? Ǹjẹ́ ìwọ gbàgbọ́ wípé Jésù kú láti san ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí ó si tún jí dìde kúrò nínú òkú (Romu 5:8; 2 Kọrinti 5:21)? Ǹjẹ́ ìwọ gba Òun nìkan gbọ́ fún ìgbàlà? Bi ìdáhùn rẹ bá jẹ́ "bẹ́ẹ̀ni," o ti di ẹni ìgbàlà! Ìdánilójú túmọ̀ sí òmìnira kúrò nínú iyèméjì. Nípa gbígba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọkàn rẹ, ìwọ lè má ní iyèméjì nípa dídájú ìgbàlà ayérayé rẹ.

Jésù tìkalárarẹ̀ múu da àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ lójú: Èmi sí fún wọn ní ìyè aìnípẹ̀kun, wọn kì ó si ṣẹ̀gbé láíláí, kò sì sí ẹnití o lè já wọn kùrò li ọwọ́ mi. Baba mi, ẹnití o fi wọn fún mi, pọ̀jù gbogbo wọn lọ, kò sí ẹnití o lè já wọn kúrò li ọwọ́ Baba mi" (Johannu 10:28–29). Ayérayé ṣáà jẹ́ èyí — ayérayé. Kò sí ẹlòmíràn, kìí ṣe ìwọ fúnrarẹ, tí o lè gba ẹ̀bùn ìgbàlà tí Ọlọ́run fún ni kúrò ní ọwọ́ rẹ.

Ní ayọ̀ nínú ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńsọ fún ọ: dípò iyèméjì, àwa lè gbé pẹ̀lú ìgboyà. Àwa lè ní ìdánilójú láti inú Ọ̀rọ̀ Kristi fúnrarẹ̀ wípé ìgbàlà wa kò ní ní àní-àní. Ìdánilójú ìgbàlà wa dá lórí ìgbàlà pípé àti kíkún èyítí Ọlọ́run ti pèsè fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni èmi ṣe lè ní ìdánilójú ìgbàlà mi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries